“Ọdún méjìlá gbáko ló gbà wá kí àjọ UNESCO tó fòntẹ̀ lu ọdún Sango àgbáyé”

Ayẹyẹ aṣekagba ọdun Sango agbaye ọdun 2024 ti waye ninu gbagede aafin Alafin ti ilu Oyo.
Ajọdun naa low aye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2024.
Ayẹyẹ naa ni yoo jẹ ayẹyẹ ọdun Sango agbaye kẹta to waye lẹyin ti Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi Olayiwola kẹta waja.

Ninu ọrọ ikinni kaabo rẹ, Paula Gomez, ẹni to jẹ aṣoju aṣa aafin Oyo fi idunu rẹ han si bi ajọ agbaye, UNESCO ṣe fi ajọdun ọjọ Sango agbaye si ọkan ninu awọn ajọdun aṣa kaakiri agbaye.
Gomez ni laisi iṣe takuntakun ti Alaafin Oyo ana, Ọba Lamidi Adeyemi Olayiwola ṣe, o ṣeṣe ki ajọ agbaye ma ṣe idamọ ọdun naa rara.

Otesiwaju pe, o gba ohun ni ọdun mejila gbako pẹlu iranlowo ajọ to n ri si aṣa ati afẹ ijọba apapọ ati ti Ipinlẹ Oyo ki wọn to fi ontẹ lu ayajọ ọhun gẹgẹ bii ọkan gbogi lagbaye.
O rọ awọn iran Yoruba lati gbe aṣa wọn larugẹ.
Hanatu Musa, to jẹ minisita fun aṣa ati igbafẹ Naijiria nínú ọrọ ikinni kaabọ rẹ ni ijọba apapọ yoo fọwọ sowọpo pẹlu awọn ori ade ati awọn ti igbelarugẹ aṣa jẹ logun lati mu ki ẹka aṣa ati igbafẹ dagba si bii ti ilẹ okeere.

Oni pẹlu bii awọn eeyan ipinlẹ Oyo ṣe gbaruku ti ajọdun Sango agbaye ọdun yii, idaniloju wa pe ti ọdun to n bọ yoo tun lokiki ju ti ọdun eyi lọ.
Igbakeji gomina ipinle Oyo, Bayo Lawal ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Oyo yoo mu igbelarugẹ ba aṣa ati isẹ ipinlẹ ọhun, pẹlu bi o ti kede ogunjọ oṣu Kẹjọ gẹgẹ bii ọjọ igbelarugẹ fun awọn aṣa ati isẹ ilẹ Yoruba.
Lawal ni pẹlu bii ajọ UNESCO ti bu ọwọ lu ṣiṣe ajọdun ọdun Sango agbaye, ijọba ipinlẹ Oyo ko ni tẹti lati mu idagbasoke ba awọn ẹka to niṣẹ pẹlu aṣa ati igbafẹ ipinlẹ Oyo.

O dupẹ lọwọ aṣoju orilẹede Portuga si Naijiria Paulo Santos, kọmiṣọna fun aṣa ati eto igbafẹ Naijiria, Hannatu Musa atawọn to wa lati ilẹ okeere, o si ṣeleri lati mu idagbasoke ba ayajọ ọdun Sango agbaye.
Lara awọn to wa sibi ọdun Sango agbaye ọdun yii nii aṣoju orilẹede Portugal ni Naijiria, Paulo Sancho, ọmọ ọba Akeem Adeyemi, awọn aṣoju ẹka to n ri si aṣa ati igbafẹ, to fi mọ awọn oyinbo miran lati orile-ede Brasil, Portugal ati Cuba.















