Kí ló dé tí oúnjẹ kò wálẹ̀ lẹ́yìn tí àdínkù bá ọ̀wọ́ngógó ọjà ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ajọ kan to n ṣe iṣiro afikun ati ẹdinwo ọja lorilẹede Naijiria, National Bureau of Statistics (NBS), kede ninu atẹjade wọn l’Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, pe adinku diẹ ti ba bi awọn ọja ṣe wọn gogo lorilẹede yii.
Ida 34.19 % ni ọwọngogo wa loṣu kẹfa ọdun 2024 yii, ṣugbọn nigba ti yoo fi di oṣu keje, o dinku si 33. 40% bi ajọ NBS ṣe kede.
Bakan naa, wọn ni ọwọngogo ounjẹ dinku diẹ pẹlu ida 0.08 %, kuro ni 2.55% to wa laarin oṣu kẹfa is ikeje 2024.
Gẹgẹ bi NBS ṣe wi, owo ounjẹ dinku diẹ loṣu keje ọdun yii, nitori adinku iye ti wọn n ta awọn ọja bii miliiki alagolo, wara oniyẹfun awọn ọmọde, ẹja tutu, igbin, eso Dabinu, Watermelon, Gaari, Akpu, ẹran tolotolo ti a mọ siTurkey, ẹran ẹlẹdẹ ti wọn ti lọ̀ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti n kọminu si abajade ajọ NBS yii, wọn ni awọn ko ri adinku kankan ninu owo ọja, paapaa awọn ohun jijẹ.
Ọpọ lo n beere pe bawo ni iṣiro ati igbelewọn yoo ṣe fi han pe ọwọngogo dinku, ti owo ọja si n fi ojoojumọ wọn si i.
Koda, ẹnikan to pe orukọ rẹ ni @efe_wills, loju opo X, da awọn NBS lohun pe ṣe awọn onka yin yii ni igboro n sọ ṣaa?
Ṣugbọn awọn onimọ nipa ọrọ aje to ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ṣalaye idi ti ọwọngogo fi dinku ṣugbọn ti araalu ko ṣe mọ ọ lara.
‘Àdínkù tó bá ọ̀wọ́ngógó náà kéré’
Tope Fasua, Oludamọran pataki fun Aarẹ Tinubu lori ọrọ aje,fidi ẹ mulẹ pe awọn ounjẹ kan dinwo lọja, koda bi ko tiẹ pọ, ẹdinwo diẹ ba wọn.
Fasua sọ pe, asiko ikore la wa, awọn ounjẹ kan ṣẹṣe jade ni. Awọn bii iṣu ati tomato.O ni owo wọn si ti dinku lọja bayii ju ti tẹlẹ lọ, paapaa julo, iṣu tuntun to ṣẹṣẹ jade.
‘’Tẹlẹ, iṣu kan ṣoṣo le jẹ ẹgbẹrun mẹrin, (4,000), ṣugbọn nisinyi, e le ri iṣu tuntun kan ra ni ẹgbẹrun meji aabọ (2,500) tabi ẹgbẹrun meji.
Ẹgbẹrun lọna aadoje (150,000) ni wọn n ta apẹẹrẹ tomato tẹlẹ, ṣugbọn nisinyi, o ti walẹ daadaa si ilaji iye yẹn."
Bakan naa ni Oludamọran Aarẹ nipa ọrọ aje yii sọ pe bi awọn eeyan ba ṣe le na ọja si naa tun ṣe pataki, nitori iyẹn ni yoo jẹ ki wọn le ra ọja ni ẹdinwo tabi ọwọngogo.
Akọṣẹmọṣẹ miran lẹka ọrọ aje, Ọmọwe Okey Okere, sọ ni tiẹ pe awọn eeyan yoo ri iyatọ ẹdinwo yii, bi owo ọja ba tẹsiwaju lati maa wa silẹ, ti nnkan ko wọn gogo mọ.
O ni to ba le ri bẹẹ laarin oṣu mẹta si mẹrin,iyatọ naa yoo han kedere.
" Ẹdinwo ti ko ju ida kan lọ ko le tete fi ara han lọja, ṣugbọn òye foju han pe o n dinku, to ba le tẹ siwaju bẹẹ, dandan ni ko han, ki araalu si ri i.’’
Ọmọwe Okey Okere lo sọ bẹẹ.
Ni ti Rotus Odiri, akọroyin to tun jẹ oniṣowo ni Naijiria, o ni, " owo ọja ṣi n gbẹnu soke, ẹdinwo kekere yii ko tumọ si pe owo ọja n walẹ.
‘’Ni Naijiria, ti owo ọja ba lọ soke, o maa lọ réré bii igba ti wọn ju ado oloro ni, ṣugbọn to ba maa walẹ, bii ẹni ju ìyẹ́ lasan silẹ ni, ko ni i lapa gidi’’
Kì ni NBS sọ?

Oríṣun àwòrán, NBS
Ajọ to n ri si akọsilẹ ẹdinwo ati ẹkunwo ọja naa sọ pe awọn gbe iṣiro awọn le ori ọja ati iṣẹ ẹẹdẹgbẹrin ati ogoji (740) ti awọn eeyan saba maa n ra, ti wọn si n ṣe deede.
NBS sọ pe ki i ṣe owo ounjẹ ati owo ọkọ nikan lo n sọ nipa ọwọngogo, wọn ni gbogbo ohun ti awọn eeyan n lo ni.
Awọn nnkan eelo ile to n lo ina, aṣọ, iwe, bata, itọju ilera ẹni, awọn ko-ṣee-ma-lo ọlọkan-ojọkan ninu ile ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wọn ni bi nnkan ṣe dinwo diẹ nigboro naa lo ri ni awọn igberiko.














