"Kìí ṣe gbogbo èèyàn ló lè gbá bọ́ọ̀lù jẹun, eré ìdárayá 'squash' ló gbémi dé ibi gíga"

Àkọlé fídíò,
"Kìí ṣe gbogbo èèyàn ló lè gbá bọ́ọ̀lù jẹun, eré ìdárayá 'squash' ló gbémi dé ibi gíga"

Emmanuel Oyeniyi Oyewumi to jẹ ogbontarigi ninu ere idaraya 'squash' ti rọ ijọba lati gbaruku ti ere idaraya 'squash' ki o ba le gbooro si.

Oyewumi ni nibi ere idaraya 'squash' gbigba loun fi di eeyan laye.

O ṣalaye wi pe oun ṣoju ipinlẹ Bornu ri ninu idije 'squash' fawọn ọmọkunrin ti ọjọ ori wọn ko ju ọdọ mẹrindinlogun lọ nigba ewe oun.

Oyewumi fikun ọrọ rẹ pe 'squash' yii naa loun gba ti oun fi di aṣiwaju lẹka awọn ọdọkunrin ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandinlogun lọ ni Naijiria.

Oyewumi naa si ni ẹni akọkọ ti yoo soju orilẹede Naijiria ninu idije agbaye squash lọdun 1991.

Idi niyii ti o fi ko awọn ọjẹwẹwẹ jọ lati maa kọ wọn ni ere idaraya 'squash.'

Oniruuru ipele ni o wa fawọn ọmọde ninu idije ti Oyewumi ṣe agbekalẹ rẹ fawọn ọmọde.

Koda, o ṣalaye pe awọn kan ti wọ ipele ti wọn fi le pegede lati kopa ninu idije Olympics ọdun 2028 bayii.

"Kii ṣe gbogbo eeyan lo maa gba bọọlu jẹun, ere idaraya squash naa le sọ eeyan di nla"

"Ere bọọlu alafẹsẹgba l'awọn gomina maa nawo le lori julọ.

O ni kii ṣe gbogbo ọmọ ni ẹ gbọdọ mu ni tipa pe o gbọdọ gba bọọlu tori pe awọn ere idaraya mii naa wa.

"Ere idaraya 'squash' yii wulo pupọ, ohun lo gbemi de ibi ti mo de lonii.

A nilo iranlọwọ lori ere idaraya 'squash', ti wọn ba na owo lori 'squash', awọn eeyan yoo mọ nipa ere idaraya naa, yoo si ṣe wọn ni anfani.

Kii ṣe gbogbo naa lo maa di nla nipa ere bọọlu afẹsẹgba," Oyewumi ṣalaye.

O ni fun bii ọdun mẹta loun ṣe fi owo ounjẹ oun wọ ọkọ lọ sibi ti wọn ti n gba squash.

Ṣugbọn lonii oun ti jẹ eeyan nipa gbigba 'squash', eyi to si jẹ nnkan idunnu fawọn obi oun.

Oyewumi wa rọ awọn obi lati fawọn ọmọ wọn lanfaani lati kopa ninu ere idaraya 'squash' ati awọn ere idaraya mii yatọ si ere bọọlu afẹṣẹgba.