Ètò ìsìnkú Aduke Gold bẹ̀rẹ̀ lónìí, bí yóò ṣe lọ rèé

Adukẹ Gold

Oríṣun àwòrán, Adukegold1/instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Oni, Ọjọru ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni ayẹyẹ eto isinku gbajugbaja akọrin ẹmi, Adukẹ Ajayi, ti ọpọ mọ si Adukẹ Gold yoo bẹrẹ.

Adukẹ Gold jade laye ni ọjọ kejila oṣu kẹjọ ẹyin ti itọju aisan jẹjẹrẹ oju ara obinrin ran an lọsọrun ni ile iwosan nla UCH nilu Ibadan.

Gẹgẹ bi ilana eto isinku ti ẹbi rẹ fi sita, oni Ọjọru ni wọn yoo ṣe eto idagbere titan abẹla, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni, ‘Candle Night’.

Eto abẹla titan naa yoo waye lagbegbe ile ẹkọ alakọbẹrẹ Ayanlẹyẹ Primary School lagbegbe Idiagbọn Bust stop, College road Ifakọ - Ijaiye lagbegbe Ọgba ni ilu Eko.

Ọjọ Ẹti ni wọn yoo gbe oku Adukẹ Gold wọ kaa ilẹ lọ,

Báyìí ni ètò ìsìnkú Aduke Gold, akọni nínú orin ẹ̀mí yóò ṣe lọ.....
Aworan atẹjade to n kede isinku Oloogbe Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, @Ajayi's family

Àkọlé àwòrán, Aworan atẹjade to n kede isinku Oloogbe Aduke Gold

BBC kan si ẹni to ku ni baba fun Aduke Ajayi, onkọrin ẹ̀mí ti gbogbo aye n ṣọfọ ré lówó nipa eto isinku rẹ.

Pasitọ Ajayi sọ pe ẹbi Ajayi ti ṣepade pẹlu ẹgbẹ awọn akọrin ẹmi, Gospel Musicians' Association of Nigeria (GOMAN), pẹlu awọn mi-in ti ọrọ naa kan.

Atẹjade to n kede eto isinku naa ṣalaye, pe titan abẹla (candlelight procession) ni yọo kọkọ waye l’Ọjọru, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ 2024, ni ileẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ ti orukọ rẹ n jẹ Ayanleye Primary School, ibudokọ Idi-agbọn, College Road, Ifakọ-Ijaye nipinlẹ Eko.

Aago mẹfa irọlẹ ni eto naa yoo bẹrẹ .

Oloogbe Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold@ Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Aduke Gold

Bi iroyin oriṣiiriṣii ṣe n waye nipa iku Oloogbe Aduke Ajayi (Aduke Gold), bẹẹ ni ọlọkan-o-jọkan ahesọ n tẹle e pẹlu, loju opo ayelujara.

Ṣugbọn ẹni to ba mọ oju ogun ni i pa obi nire, ko si sẹni to le tan imọlẹ si ọrọ yii bii awọn ẹbi oloogbe.

Eyi lo jẹ ki BBC ba ẹni to ku ni baba fun Oloogbe Aduke Gold sọrọ, iyẹn Pasitọ Ajayi Aderounmu.

Baba naa si ṣalaye idi iku Aduke, igbesi aye to gbe, aisan to pa a yii ati eto isinku rẹ, bayii ni Olori ẹbi Aduke Ajayi wi.

‘Àrùn jẹjẹrẹ ojú ara (Cervical cancer) ló pa Aduke Gold’

’’ Orukọ mi ni Pastor Ajayi Aderounmu, mo jẹ ẹgbọn Aduke, baba kan naa lo bi emi ati ẹ.

Ọdun 1993 ti baba wa ku ni Iya Aduke naa ku, nigba yẹn lo ti di ọmọ orukan, latigba naa lo dẹ ti n gbe lọdọ mi. Emi ni mo kù ni baba fun un.

‘’ Badagry ni wọn bi i si, emi n gbe ni Ifakọ, iku awọn Obi wa lo jẹ ko maa wa gbe lọdọ mi.

‘’Ileẹ̀kọ́ alakọọbẹrẹ lo wa nigba yẹn, mo pada fi i sileẹ̀kọ́ Sanmori Comprehensive High School, Ifako, nigba ti asiko to.

Awọn ẹlẹyinju aanu ni wọn ran an lọ si yunifasiti, LASU lo lọ.

Awọn Ọnarebu Onimọle ati Opeyemi Bamidele, awọn to jẹ baba ẹ gan-an nibi inawo ẹkọ giga niyẹn.

‘’Nipa iku to pa Aduke, Cervical cancer lo pa a loootọ, nitori o han ninu iwe ẹri iku rẹ bẹẹ.

Oloogbe Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold@Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Aduke Gold

"Aduke kì í sọ̀rọ̀ ara rẹ̀ fún èèyàn, ọjọ́ tó kú ni mo tóó gbọ́ pé ó ní àìsàn jẹjẹrẹ’’

Nigba to n sọrọ nipa iru eeyan ti Oloogbe Aduke Gold jẹ, Pasitọ Ajayi Aderounmu sọ pe, ‘’Aduke jẹ eeyan kan ti ki i sọ ọrọ ara rẹ fun eeyan.

‘’ Igba ti ko ti gbe lọdọ mi mọ, mi o gbọ nnkan kan nipa rẹ mọ.

Emi gan-an o mọ pe arun yii n ṣe e, afi lọjọ Mọnde to ku yii.

‘’Ninu oṣu kọkanla, ọdun 2023, o wa si ṣọọṣi mi lasiko ajọdun, o di mọ mi, o si kọrin pẹlu.

Ko jọ ẹni ti nnkan kan n ṣe nigba naa, ko si apẹẹrẹ pe nnkan kan n ṣe e rara.

‘’Koda, o ṣi pe mi ni bii ọsẹ mẹta sẹyin lorii foonu, to ki mi fun iku iyawo ọrẹ mi.

Ko si apẹẹrẹ pe nnkan kan n ṣe e nigba naa, ko dẹ sọ fun mi pe aarẹ naa n ṣe oun.

Àlàyé rèé lórí irú ikú tó pa ọmọ wa Aduke Gold àti bí ìlànà ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ - Olórí ẹbí Ajayi ṣàlàyé

O tun salaye fun BBC pe: ‘’Aduke gbagbọ ninu ara rẹ gan-an, o gbagbọ pe oun le da koju ohunkohun, gbogbo bo ṣe n gba itọju ni yunifasiti Olabisi Onabanjo ni Sagamu, emi o mọ.

Gbogbo bo ṣe ṣe aarẹ yẹn, ko fi to mi leti rara.

‘’ Ọjọ Mọnde to ku yẹn ni wọn pe mi, pe o wa ni Danger list (ẹṣe kan aye, ẹsẹ kan ọrun),ni UCH.

Kinni yẹn ba mi lojiji, emi dẹ ni mo sun mọ ọ ju ninu ẹbi, emi ni baba ẹ, baba ni mo jẹ fun un.

‘’Emi gbagbọ pe o yẹ ko le sọ fun mi, ṣugbọn ko sọ, mo dẹ mọ pe nnkan ti ko ṣe sọ ni pe o ti gbagbọ pe oun maa wa ok.’’

‘Àbúrò rẹ tí wọ́n bí tẹle e lo pe mi lati UCH ti mo fi gbọ’

Gẹgẹ bi Pasitọ Aderounmu ṣe wi, o ni aburo Aduke to jẹ ọkunrin lo pe oun ni ọjọ Mọnde ti akọrin ẹmi naa ku.

‘’O tiẹ ni ki ọmọ yẹn gan-an ma sọ fun mi, iyẹn lo ni ṣe bi gbogbo eeyan ko ba tiẹ gbọ, ṣe bii ti Pastor Ajayi ni.

‘’Ọmọkunrin naa pe mi, o ni Aduke sọ pe koun ma sọ fun mi, ṣugbọn oun gbọdọ jẹ ki n gbọ, iyẹn dẹ jẹ ọjọ Mọnde to ku yii naa.

Ètò ìsìnkú Aduke Gold

Pasitọ Ajayi tun ṣalaye pe:

Alẹ awọn oṣere (Artists night), yoo waye l’Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹjọ 2024, ni aaye kan naa ti titan abẹla ti waye.

Aago mẹfa irọlẹ ni eto naa yoo bẹrẹ, yoo si pari si aago mẹfa idaji ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹjọ 2024 ti i ṣe ọjọ ti wọn yoo sin Oloogbe Aduke Gold.

Lagos Afreican Church Grammar School ni titẹ oku ati isinku yoo ti waye, eyi to wa ni College Bus stop, College Road, Ogba niluu Eko.

Ta a ni Aduke Gold?

Aduke Ajayi, (Aduke Gold) ni ọmọbinrin naa ti wọn bi ni ọdun 1988, ni ilu Badagry, ṣugbọn ọmọ Ilesa, ni ipinlẹ Ọsun ni.

Ọdun 1993 ti baba rẹ ku ni iya rẹ naa jade laye, Aduke ko si ti i ju ọmọde lọ nigba naa.

O tiraka lo ẹbun orin to ni, ogo rẹ si pada buyọ.

O kawe, o si kọ awọn ẹkọ nipa iṣẹ ọwọ ati itọju ọmọde.

Aduke pẹnkẹlẹ ni Oloogbe n jẹ nigba to bẹrẹ orin, ko too yọ penkele kuro to si ni Aduke Gold ni oun yoo maa jẹ, iyẹn lọdun 2008.

Aduke Ajayi jade laye lọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ ọdun 2024, lẹyin aisan jẹjẹrẹ oju ara.

Ọ̀pọ̀ àṣírí nípa ìtàn ayé, ìdílé àti ọkọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí Aduke Gold tú síta kó tó kú rè

Lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Aduke Ajayi Morounkola, ti ọpọ eeyan mọ si Aduke Gold se ifọrọwanilẹnuwo kan, eyi to jade loju opo ayelujara You tube.

Nibi ifọrọwanilẹnuwo ọhun ni Oloogbe Aduke Gold ti sọ awọn ọrọ kan to jẹ aṣiri nipa rẹ.

Aworan Oloogbe Aduke Ajayi, ẹni ti ọpọ mọ si Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Facebook/AdukeGold

Àkọlé àwòrán, Aworan Aduke Ajayi, ẹni ti ọpọ mọ si Aduke Gold

Bo ṣe jẹ pe idile olorogun lo ti wa, bi baba rẹ ṣe bi to ọmọ mejidinlogun, ti iya tirẹ ko si bi ju meji pere lọ, Aduke ati aburo rẹ ọkunrin nikan.

O ṣalaye nipa ọkunrin to yẹ ko fẹ ti ko pada fẹ mọ, aini Obi lati kekere, bo ṣe jiya fun ọdun mẹwaa lọdọ ẹni kan to n ba a gbe orin rẹ jade lai mu nnkan kan bọ.

Oloogbe Aduke Gold tun ṣalaye nipa bo ṣe tu ẹgbẹ orin rẹ ka nitori aṣemaṣe ọkunrin to ni oun n fẹ naa.

"Idi ree ti mo se tu ẹgbẹ akọrin mi ka tori asemase ọkọ afẹsọna mi"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Aduke Gold salaye pe ọkunrin to yẹ ki oun fẹ, n ba awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin oun lo pọ, ti oun si tu ẹgbẹ akọrin naa ka, ti oun ko si fẹ ọkunrin naa mọ.

‘’Ile onigbagbọ ni mo ti wa, bi n ko tilẹ ni itọju obi nitori awọn obi mi ku lọdun kan naa nigba ti mo wa ni kekere.

Ṣugbọn mo kọ ẹkọ nipa Ọlọrun lati ipasẹ Profẹẹti I. A Oluyemi, pasitọ mi to kọ mi pẹlu ọna to le, ti mo fi mọ pe ko daa ki eeyan ni ibalopọ ṣiwaju igbeyawo.

‘’Ọmọ Ẹfanjẹliisi ni ọkunrin to yẹ ki n fẹ, o maa n lu duuru, ṣọọṣi ni a ti pade, mo si fẹran ọkunrin to ba n lu duuru gan-an.

‘Emi duro lori ofin Ọlọrun pe a ko ni i ba ara wa jẹ ṣiwaju igbeyawo, ko ni i si ibalopọ, afi bi mo ṣe ri i pe ọkunrin yii n ba awọn ọmọ ẹgbẹ mi obinrin lo pọ.

Ki i ṣe ẹyọkan, ki i ṣe meji to n ba ṣe’’

‘’ Bi mo ṣe ri eyi ni, mo ni mi o ṣe mọ, mo si tu ẹgbẹ orin mi naa ka, mo ni ki onikaluku wọn maa lọ sile rẹ.

Ọlọrun ti sọ fun mi tẹlẹ pe ajọṣepọ naa ko le bọ si i, mo kuna nibẹ gan-an ni.’’

"Ọdún mẹ́wàá ni ẹni to n ba mi gbe awo orin sita fi lo mi lai fun mi lowo, o fi orukọ mi gbowo kiri nitori mo jẹ ọmọ orukan, o tun ṣepe fun mi nigba ti mo ni mi o ṣe mọ"

Aduke salaye ninu ifọrọwerọ naa pe ẹni to n ba oun gbe awo orin oun jade, lo oun fun ọdun mẹwaa yii, amọ ko darukọ ẹni to n ba a gbe awo rẹ jade.

‘’Nitori mo fẹ ni orukọ ati okiki, ti mo fẹ ki aye mọ mi, mo tọwọ bọ iwe adehun ọdun mẹwaa pẹlu ileeṣẹ to ni oun n maneeji mi naa.

‘’Ọkunrin naa maa n mu mi kiri lọ sọdọ awọn alaanu, a sọ fun wọn pe mo ni talẹnti, ṣugbọn ọmọ orukan ni mi.

‘’Bi wọn ba fun mi lowo, mi o ni ri nnkan kan gba lọwọ rẹ.

O le mọ ọkunrin naa debi pe oun ati iyawo rẹ n fi orukọ mi gba owo ati ẹbun kiri.

Mo ṣe show, mi o rowo kankan gba lọwọ rẹ.

‘’Ọdun 2008 ni mo ni mi o ṣe mọ, mo ni mo maa lọ tu aṣiri ẹ fun awọn eeyan to n fi mi gba owo lọwọ wọn.

O ṣepe fun mi nigba naa pe toun ba ṣi n mi loke eepẹ, mi o ni lu aluyọ.

‘Mi o sepe fun un pada ni temi, mo kan sọ fun un pe afi to ba jẹ oun lo fun mi lẹbun orin ni epe rẹ yoo ṣẹ.

Mo fi owo mi silẹ fun ati awọn irinṣẹ ti mo ni, mo yọnda gbogbo ẹ fun.

Mo si pada foriji i, nitori emi kọ ni mo n ṣe gbogbo ẹ, Ọlọrun ni.

‘’Ọdún 2008 yẹn ni mo pàdé Tope Alabi, òun lọ yọ pẹnkẹlẹ kúrò nínú orúkọ mi’’

‘’Nibi ere ita gbangba kan ni mo ti pade Tope Alabi, wọn si sọ fun mi pe awọn ti n wa mi tẹlẹ.

‘’Tope Alabi sọ pe ki n yọ pẹnkẹlẹ to wa ninu orukọ mi kuro, wọn ni orukọ naa n dena kadara mi.

Wọn ni Aduke Gold ni ma a maa jẹ, latigba naa ni mo ti n jẹ Aduke Gold.

Mo le sọ ọ nibikibi pe Tope Alabi lo fun mi lorukọ yẹn, bii mama ni wọn jẹ si mi.’’

Àì ní òbí jẹ́ ki n maa da ipinnu ṣe lati kekere, mo si ṣe awọn aṣiṣe nitori eyi

Oloogbe Aduke Gold nigba to wa ni kekere

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold @Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Aduke Gold nigba to wa ni kekere

Nigba to n dahun si awọn iya to jẹ ẹ ni kekere, Adukẹ Gold sọ pe oun ko ri obi ti oun yoo fi ọrọ oun lọ, eyi si jẹ ki oun maa da ipinnu ṣe.

O ni bi oun ba gbe awọn igbesẹ mi-in, yoo kuna nitori oun ko ri ẹni sọrọ oun fun. Awọn aṣiṣe ti ko ba ma waye ka ni oun ni obi ni, gbogbo ẹ lo ni oun ṣe.

Aduke ṣalaye bo ṣe koju iwa biba ọmọde ṣe oun ti ko tọ,nitori ai ni obi rẹ.

‘’Loootọ, mo maa n gbe awọn igbesẹ mi-in ti yoo daa o, bii apẹẹrẹ, nigba ti mo n kẹkọọ nipa itọju awọn ọmọde, owo nla ni mo n san. UK ni ileewe naa wa ṣugbọn wọn ni ẹka rẹ ni Eko.

‘’Mo kọ ara mi pe mi o ni i ra mekọọpu, mi o ni i ra kiriimu, mi o si ni i ra aṣọ. Mo maa n ṣi gbogbo ẹ letoleto ni, owo ile, owo ounjẹ, owo awọn to n ba mi ṣiṣẹ nigba yẹn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‘’Nigba ti owo ileewe yẹn pọ, mo sọ fun awọn oyinbo pe mi o le sanwo bii awọn akẹkọọ yooku, nitori emi ni mo n ran ara mi nileewe.

‘’Oyinbo sọ pe ṣebi mo kọ ‘Adani-ma-gbagbe’ sinu iwe gẹgẹ bii onigbọwọ mi (sponsor) ti yoo maa sanwo ileewe naa. Mo yaa sọ fun oyinbo naa pe ko le ye e, ko ṣaa maa wo ni tiẹ.

Ṣugbọn awọn igbesẹ ti mo gbe lọna aitọ naa pọ,nigba ti ko sẹni to maa beere lọwọ mi.’’

Bí ẹ̀bùn orin mi ṣe jáde

Ẹnikan to pe ni Pastor Ajayi, ni Aduke sọ pe o ṣawari ẹbun oun ni ṣọọṣi.

‘’Wọn kọ mi lati maa gba aawẹ biribiri, aawẹ ti awọn ọmọ to ni obi ko le gba. Bi mo ba gba aawẹ naa tan, omiran fun ọjọ mẹrinla, ẹja yiyan ati gaari ni mo maa fi ṣinu. Ko kuku si ohun ti ma a jẹ tẹlẹ naa bi mi o ba gbaawẹ.

‘’Bi mo ṣe n fi ara ṣiṣẹ f’Oluwa niyẹn ti mo si n kọrin. Bi mo ba gbọ orin kan, ma a sare kọ ọ jade ki n ma baa gbagbe. Mo si maa n kawe daadaa, mo maa n ṣe iwadii iha ti ọrọ Ọlọrun kọ si orin ti mo fẹẹ gbe jade.

Àwo orin Nítorí ògo ni

‘’Ọmọ kan lo fọ loju wa lati inu iya rẹ, nigba ti wọn bi i, ko riran.

‘’Eyi ṣe awọn eeyan ni kayeefi, wọn n beere pe ṣe iya ọmọ lo ṣe ni abi ọmọde jojolo. Ṣugbọn si iyalẹnu wọn, esi ti wọn gba ni pe nitori ogo Ọlọrun ni.

‘’Eyi ni mo ro papọ, mo si sọ ọ di orin bayii pe, ‘’Nitori ogo ni, ohun ti oju ologo ba ri laye, nitori ogo ni. Aṣe Ọlọrun mọ si i, aṣe Ọlọrun da mi mọ, ohun ti oju ologo ba ri laye, nitori ogo ni.’’

Mo wọ studio, mo kọ ọ lorin, ẹni to n ba mi rikọọdu rẹ si bẹrẹ si i ke nigba to gbọ orin naa.

‘’Mo mu un lọ si Redio Lagos atu Faaji FM, mi o kuku ni marketer mọ, o si di itẹwọgba.

Mo le ma pa owo nibẹ loootọ, ṣugbọn orin to n fi ibukun si aye awọn eeyan ni, o n la ipa rere’’

Bẹẹ ni Oloogbe Aduke Ajayi Morounkola wi.