Akòròyìn Kenya, Rukia Bulle, gba àmì ẹ̀yẹ BBC Komla Dumor 2024

Aworan akọroyin, Rukia Bulle
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Akọroyin ọmọ orilẹede Kenya, Rukia Bulle ti gba ami ẹyẹ BBC News Komla Dumor ti ọdun 2024.

Ẹni ọgbọn ọdun jẹ eeyan kẹsan an ti yoo gba ami ẹyẹ yii, to si n sisẹ fun ileeṣẹ iroyin Kenya Nation Media, to n se iroyin nipa ohun ti awọn eeyan nifẹ si.

Bulle tun ti se ọpọlọpọ aṣeyọri lori ayelujara Tiktok nitori bi o ṣe n gbe awọn iroyin sita lori igbesi aye akọroyin.

Ami ẹyẹ yii ni wọn sẹda lati fi bu ọla fun Dumor, akọroyin orilẹede Ghana, to jẹ sọrọsọrọ fun BBC World News, ẹni to ku lojiji ni ẹni ọdun mọkanlelogoji ni ọdun 2014.

Dumor sisẹ karakara lati fi gbe ohun to n waye ni ilẹ Afrika sita fun gbogbo araaye lati mọ nipa.

Awọn adajọ ami ẹyẹ yii ni inu wọn si iwa akikanju Bulle lati koju awọn iroyin ti wọn gbe si niwaju, bi o se gbajumọ ati bi o se gbe iroyin naa sita lori afẹfẹ.

“Gbigba ami ẹyẹ yii tumọ ohun nla fun mi. Gẹgẹ bii akọroyin, o ni lati saa gbogbo agbara rẹ lati se ohun to dara, lia ro ibi ti mo ti wa, fun idi eyi, pe wọn lẹwọgba gba lagbaye latara ami ẹyẹ Komla Dumor jẹ ohun iwuri.” Bulle, ẹni to wa ọgọrun un eeyan to jẹ musulumi to ni okiki ni orilẹede Kenya lọdun to kọja.

“Mo lero pe ami ẹyẹ yii yoo jẹ ohun iwuri fun ọpọ awọn ọdọmọbinrin bi temi, to n wọ Hijab, ti wọn si wa lati ilu kekere pe ni igbagbọ pe wọn yoo de ibi ti wọn fẹ de laye.”

Akọroyin Kenya naa yoo lo oṣu mẹta lati ba BBC News sisẹ lori tẹlifisan, redio ati ori ayelujara niluu London.

Bakan naa ni yoo tun gba idanilẹkọ lati ọwọ agba akọroyin ni BBC.

Komla Dumor

Tarik Kafala to je adari agba fun BBC World Service sọ pe inu oun dun pe ami ẹyẹ Komla Dumor ti ṣe ọpọ anfani fun awọn akọroyin kaakiri agbaye.

"Awọn akọroyin ti o gba ami-ẹyẹ yii ṣaaju ti ko awọn ipa pataki si iṣẹ iroyin siṣe fun agbegbe wọn nitori naa inu wa dun lati ki Rukia Bulle kaabọ gẹgẹ bi olubori ti ọdun yii," o sọ.

Gẹgẹ bí a se ma n se, Bulle yoo rin irìn ajo lọ si orilẹ-ede kan ni ilẹ Afírika lati lọ se iroyin ti wọn yoo gbe sori afẹfẹ fun gbogbo ileeṣẹ BBC kaakiri agbaye.

Awọn ti o gba ami-ẹyẹ naa ṣaaju ni Paa Kwesi Asare, Dingindaba Jonah Buyoya, Victoria Rubadiri, Solomon Serwanjja, Waihiga Mwaura, Amina Yuguda, Didi Akinyelure ati Nancy Kacungira, olubori akọkọ.

Ni ọdun to kọja, Asare rin irin-ajo lọ si Kenya lati lọ jabọ lori iroyin kan.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images/BBC