Aráàlú ká orí èèyàn mọ́ ọkùnrin kan lọ́wọ́ n‘Ibadan, ariwo sọ, Ọlọ́pàá lahùn

Ọdaran to wa ni ahamọ

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọn ni ọjọ gbogbo ni ti ole sugbọn ọjọ kan ti ọwọ palaba rẹ yoo sẹgi.

Eyi ni ohun to waye si ọkunrin ti ọrukọ rẹ n jẹ Musa nigba ti awọn eeyan kan ni agbegbe Amuloko niluu kan ori eeyan tutu mọ lọwọ.

Oṣojumikoro ni ori eeyan naa lo jẹ ti obinrin kan ti awọn ko da mọ.

Awọn oṣojumikoro ni awọn kẹẹfin Musa bi o ṣe n rin kiri ni adugbo naa, ti irin rẹ si mu ifura dani, ti wọn si lọ bi pe ki lo gbe lọwọ.

Musa, ẹni to gbe apo kan dani, ni wọn ni ko tun apo naa, to si jẹ pe ori eeyan ni wọn ba nibẹ.

Ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara, Musa ni oun jẹ ọmọ ikọ ẹgbẹ kan to n se karakata ẹya ara eeyan.

Ẹwẹ, wọn ti fa Musa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun iwadii.

Ọwọ wa ti tẹ eeyan meji lori ẹsun tita ẹya ara eeyan - Ọlọpaa Oyo

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adewale Osifeso nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe ọwọ ti tẹ eeyan meji bayii, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo.

“Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii, ti ọwọ si ti tẹ eeyan meji to lọwọ ninu isẹlẹ

“A o ma fi to eyi leti bi iwadii wa se n lọ.”

Bẹẹ gbagbe nibi oṣu diẹ ni ọwọ tẹ mẹta kan niluu Ibadan kana pẹlu ori eeyan.

Adugbo Moniya nilu Ibadan ni wọn sọ pe awọn afurasi yii ti ge ori ọkunrin ọhun, to jẹ osisẹ wọnlẹ-wọnlẹ, ti a mọ si Surveyor

iyalẹnu lo jẹ fun awọn eeyan nigba ti ina nla kan ṣẹyọ ni ile afurasi kan ti wọn ba ẹya ara lọwọ wọn.

Taofeeq Olalekan, ẹni to wa ni ahamọ awon agbofinro ipinlẹ Oyo pẹlu awọn afurasi meji miiran fẹsun pe wọn ba ori eeyan lọwọ wọn.