Ìdí rèé tí ọmọ ẹgbẹ́ Emèrè ṣe ń yè tàbí kú - Ẹgbẹ́ Emere ṣàlàyé
Ni ilẹ Yoruba laye atijọ, ohun ajeji ni ki awọn elére ọmọ foju han sita fun araye ri.
Ọpọ ọmọ to ba jẹ Emere, ni kii jẹ ki aye mọ, yoo maa fi oju pamọ amọ awọn iwa to ba hu nigba mii, lo maa n jẹ kawọn obi tabi awujọ fura pe ọmọ naa ni ẹgbẹ lọrun.
Amọ ohun iyalẹnu lo n jẹ fun ọpọ eeyan laye ode oni lati maa ri awọn Emere ti wọn n foju han fun araye ri.
Koda, kii se pe awọn Emere yii n foju han sita nikan, se ni wọn tun ko ara wọn jọ sinu ẹgbẹ, ti wọn si maa n se ajọdun ẹgbẹ Awọn Emere.
Ilu Osogbo, tii se Olu ilu ipinlẹ Osun si sọkutu wọwọ lasiko ajọdun awọn Emere fun tọdun yii, eyi ti BBC Yoruba peju si.
Nibẹ si la ti ba awọn eekan ẹgbẹ Emere sọrọ nipa awọn ohun to nii se pẹlu ẹgbẹ naa, ero ọpọ eeyan nipa iku awọn Emere ati awọn anfaani ti wọn n ri jẹ ninu ẹgbẹ naa.

Bawo ni eeyan se n mọ Emere ọmọ?
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti ẹgbẹ Emere duro fun, Olori ẹgbẹ Emere naa, Oyinlola Ẹlẹbuibọn salaye pe ko si ẹni ti ko ni ẹgbẹ, gbogbo ẹni to ba ti ni ori, o ti ni ẹgbẹ.
"Amọ ẹ́gbẹ yii ju ara wọn lọ, bi aye wa se ri naa ni.
Asiri owo nini ju ara wọn lọ, ko sẹni ti ko ni owo lọwọ ọla ni ko kari.
Ẹlomii n gbọ ohun ajeji, ti ẹlomiran ko le gbọ, ẹlomii n ri ohun ti ẹlomiran ko le ri, ibi ti a ti mọ pe Emere rẹ lagbara niyẹn.
Bi eeyan se maa n mọ Elere ọmọ niyẹn, ẹni to ba ni awọn anfaani yii, yoo maa kiyesi ara rẹ.
Bi ọmọ ẹgbẹ Emere ba n ku, to n lọ, to n pada lọpọ igba, lo di abiku
Ohun ti awọn eeyan bẹru ju gan ree, ti wọn fi ro pe Emere maa ku ni.
Ẹgbẹ to ba mọ ohun ti oun ko gbọdọ jẹ, to si n tọju awn ẹgbẹ rẹ deedee, yoo mọ bi oun yoo se maa ti i."

Ki lo n mu ẹmi awọn Emere gun tabi kuru?
Bakan naa ni arabinrin Osunbukola Bukunmi kin Elebuibon lẹyin pe pataki ẹgbẹ Emere ni pe ẹni ti ko ba ni ẹgbẹ nile aye, ko le ni lọrun.
"Ẹni to ba lẹgbẹ, yoo mọ pe oun ni ẹgbẹ, gbẹ eeyan si maa n ro fun eeyan.
Onitọun lee sun, ko maa la ala, ko maa ri awọn ẹgbẹ rẹ pe ko se bayi, bayi."
Ẹgbẹbunmi Ifawuyi naa salaye nipa awọn ohun to n mu ki ẹmi awọn Emere gun tabi kuru nile aye.
"Ti a ba sọ pe awọn Emere kii pẹ laye, irọ ni o nitori akọsilẹ ti wa fun onikaluku.
Awọn ẹlẹgbẹ wa, ti awa mọ, maa n dagba, wọn maa n dogbo.
Bi wọn ko ba tọju ẹgbẹ lo maa n jẹ ki Emere tete ku tori ẹlomiran ko ni tọju ẹgbẹ rẹ.
Nigba ti mo fi idi ẹgbẹ lelẹ ni aye mi gun, ni aye mi ko.
Ẹlomiran ti ko tọju ẹgbẹ rẹ, akọsilẹ ti duro, ẹlomiran ti ko tọju ẹgbẹ gan n saisi, ka ma sẹsẹ sọ ti ẹni ti ko tọju ẹgbẹ rẹ.
Ti eeyan ba n tọju ẹgbẹ rẹ loorekoore, wọn yoo maa fi ọdun kun ọdun rẹ ni."







