Wo ìṣepàtàkì ẹgbẹ́ Emere láwùjọ gẹ́gẹ́ bí olórí Emere ṣe ṣàlàyé

Aworan awọn Emere
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọdun ẹgbẹ Emere Onitesiwaju ti ọdun 2024 waye ni ọjọ Keje osu Kẹjọ ọdun yii ni ile olori ẹgbẹ Emere to wa ni agbegbe orita Sabo niluu Osogbo nipinle Osun larinrin.

Nigba ti o n sọ iṣepataki ẹgbẹ Emere lawujọ, Oyelola Elebuibon to jẹ olori ẹgbẹ Emere sọ pe ẹgbẹ naa lagbara o si jẹ ẹgbẹ to maa n fi eeyan lọkan balẹ laarin àwùjọ.

Elebuibon ni ''ọmọ ẹgbẹ Emere ki ba wọn bu ìjọba, bẹẹ si ni ọmọ ẹgbẹ Emere ki i se ohun ti ko tọ tabi ohun ibajẹ rara.''

Oyelola fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ Emere ma n ran ara wọn lọwọ lati le bori ipenija tabi ogun to ba doju kọ ọmọ ẹgbẹ emere.

Olori ẹgbẹ Emere tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe, bi ẹni to ba ni ẹmi Emere ko ba ti jẹ nkan ewọ ko le ku ni kekere.

Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan ti wọn maa n sọ pe awọn ọmọ Emere maa n ku ni rewerewe.

Oyelola tun fi kun ọrọ rẹ pe ''awa ti a jẹ ọmọ ẹgbẹ Emere, Ọlọrun maa n gbọ adura awọn gidigidi ni gbogbo igba ti awọn ba ti gbadura si Ọlọrun.''

O wa gba gbogbo eeyan nimoran wi pe, ki wọn ni ifẹ ọmọ ẹnikeji wọn daada, ki wọn le bori isoro to n doju kọ ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ati eyi to doju kọ orile-ede Naijiria lọwọ yii.

Ẹgbẹbunmi Ifawuyi to jẹ akowe fun ẹgbẹ Emere naa sọ wi pe, ko si ẹni ti ko ni ẹgbẹ sugbọn o le yàtọ̀ sira wọn ni.

Ẹgbẹbunmi ni, akọsilẹ ti wa fun olukaluku lati ode ọrun wa, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ Emere ti oun mọ, wọn dagba wọn si di ogbo ki wọn to pa ipo da.

''Bi ọmọ ẹgbẹ Emere ba tọju ẹgbẹ daadaa yoo pẹ laye gidigidi a si tun ni owo lọwọ, tori ẹgbẹ Emere jẹ ẹgbẹ to ni alubarika lọpọlọpọ.

Nigba ti mo darapọ mọ ẹgbẹ Emere ni aye mi dara,'' Egbebunmi lo sọ bẹẹ.

O tun fi ku ọrọ rẹ wi pe ẹni to ba tọju ẹgbẹ Emere yoo pẹ laye nitori ẹgbẹ yoo mọ fi ọdun kun ọjọ ori rẹ.

Ọpọlọpọ awọn aláwọ̀ funfun lo peju pesẹ si bi ajọdun ẹgbẹ Emere ti ọdun yii.