D'Tigress gbìyànjú àmọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ òsì júwe ilé fún wọn ní ìdíje Olympics

Aworan awọn D'Tigress

Oríṣun àwòrán, dtigressofficial/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Irinajo ìkọ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, D'Tigress dopin lalẹ Ọjọru lẹyin ti akẹgbẹ wọn lati orilẹede Amẹrika fagba han wọn pẹlu ami ayo 88-74 ninu ere bọọlu ipele komẹsẹ-o-yọ ti wọn n pe ni 'quarter finals' ninu idije Olympics to n lọ lọwọ niluu Paris lorilẹede France.

Lati abala kini ere bọọlu ọhun ni awọn ọmọbinrin Amerika ti bẹrẹ si jẹwọ ara wọn pe ọga l'awọn jẹ lagbo ere bọọlu alapẹrẹ lagbaaye.

A'Ja Wilson to ti gbami ẹyẹ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin to pegede julọ nigba meji ọtọọtọ ninu idije WNBA l'Amerika gba ogun ami ayo wọle, nigba ti o si tun ṣeranwọ fun ami ayo mọkanla.

Jackie Young naa gba ami ayo mẹẹdogun wọle fun Amerika ninu ere bọọlu ọhun.

Breanna Stewart naa o gbẹyin, ami ayo mẹtala loun ri gba sinu apẹrẹ fun Amerika.

Ni ọjọ Ẹti ni ikọ agbabọọlu alapẹrẹ Amerika yoo maa koju Australia ninu ere bọọlu alapẹrẹ to kangun si aṣekagba.

Ẹwẹ, Ezinne Kalu tun fakọyọ ninu ere bọọlu alẹ Ọjọru, bo tilẹ jẹ pe Naijiria fidirẹmi.

Ikọ agbabọọlu alapẹrẹ D'Tigress ni ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ lati ilẹ Afirika ti yoo de ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ tawọn oloyinbo n pe ni 'quarter finals.'

D'Tigress di ajitanna wo ninu idije Olympics 2024 lẹyin ti wọn fagba han Australia to jẹ ẹgbẹ agbabọọlu to lorukọ juwọn lọ.

Lẹyin eyi ni wọn tun lu Canada eyi ti wọn fi pegede fun ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ.

D'Tigress Nàìjíríà gbìyànjú àmọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ Amẹ́ríkà fọwọ́ òsì júwe ilé fún wọn ní ìdíje Olympics 2024

Ǹjẹ́ ikọ̀ D'Tigress Nàìjíríà tó gbangba sùn lọ́yẹ́ láti borí ikọ̀ Amẹ́ríkà lónìí ní ìdíje Olympics?

Aworan agbabọọlu Alapẹrẹ D'Tigress

Oríṣun àwòrán, x.com/DtigressNG

Eyi ni ibeere ti ọpọ n bere, ti igbagbọ si wa pe ikọ D’Tigress ti orilẹede Naijiria yoo pese idahun lonii nigba ti wọn ba koju ikọ USA ni ipele Quarterfinal ti idije Olympic ti alapẹrẹ ti awọn obinrin to n lọ lọwọ lorilẹede France.

Bo tilẹ jẹ ikọ D’Tigress ti jẹ ki inu ọpọ dun nigba ti wọn seto iya fun awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Austraila, ọpọ si ni igbagbọ pe wọn tun le fakọyọ nigba ti wọn ba koju USA.

Akọnimọgba ikọ D’Tigress, Rena Wakama, pẹlu bi ikọ se ti gbo ewuro si oju ọpọ awọn akẹgbẹ wọn, o ni awọn ko ti mu inu ọpọ dun, ti awọn ko ba gba ami ẹyẹ goolu ti awọn wa wa si idije naa.

Ifẹsẹwọnsẹ laarin orilẹede Naijiria ati France ni ọpọ ṣapejuwe gẹgẹ aṣekagba saaju aṣekagba, to si dun ọpọ pe ọkan ninu wọn yoo pada si ile lonii.

Orilẹede Naijiria ni anfani lati se ohun ti ọpọ ko le se ti wọn ba fidi USA janlẹ ninu ifẹswọnsẹ yii, bo ti lẹ jẹ pe wọn ti fitan balẹ pe awọn ni ikọ adulawọ akọkọ ti yoo ipele quarterfinal.

Bawo ni wọn se ipo ti wọn wa bayii?

Orilẹede bi Australia ati Canada wa lati awọn orilẹede ti D’Tigress se iya fun ninu idije yii.

Ikọ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin Naijiria, D’Tigress ti bẹrẹ ikopa wọn ni idije Olympics Paris 2024 lọwọ ẹrọ pẹlu gbigbo ewuro si ẹnu awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Australia.

Australia lo wa ni ipo kẹta pepele igbelewọn awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin lagbaye.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn to waye lọjọ Aje ni ilu Lille ikọ D’Tigress fi ajulọ han Australia pẹlu apẹrẹ marundinlọgọrin si mejilelọgọta.

Ta ni ọpọ gbe ọkan le fun orilẹede mejeeji

D’Tigress gbe ọkan le Ezinne Kalu, ẹni ti ko ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ kankan lati idije Tokyo 2020 sugbọn kete to pada sinu ikọ naa, ọpọ nnkan lo ti yi pada.

Ikọ orilẹede USA n reti pe Chelsea Gray yoo tun pitu bi o ṣe ma pitu lasiko ti wọn ba koju ikọ D’Tigress.

Ọpọ igba ni awọn orilẹede mejeeji ti koju arawọọn.

Ninu oṣu keji ọdun yii, wọn pada ara wọn ti ikọ USA si bori pẹlu 100-46

Bakan naa ninu idije Olympic Tokyo ọdun 2020, ikọ mejeeji koju ara wọn, ti USA si tun bori pẹlu 81-72