Ìjìyà tó wà lábẹ́ òfin fáwọn èèyàn tó ń gbé àsìá Russia sókè ní Nàìjíríà rèé

Oríṣun àwòrán, Social media
Ọga ologun lorilẹede Naijiria, Ọgagun Christopher Mustapha ti se ikilọ fun awọn eeyan to n gbe asia orilẹede Russia soke lasiko iwọde pe ẹsun nla lo jẹ, to si lodi si ofin.
Mustapha ni ohun ti awọn eeyan yii n se lo jẹ ẹsun iditẹmọjọba, ti ko si jẹ itẹwọgba lorilẹede Naijiria.
Ọwọ ti tẹ awọn eeyan kan bayii, paapa ransọransọ to ran asia naa fun lilo awọn olufẹhonuhan ati awọn afurasi mii.
Ninu atẹjade kan to jade lọjọ Aje, ileeṣẹ Ọtẹlẹmuyẹ DSS ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan.
Ki lo sẹlẹ saaju?

Ọpọlọpọ awọn oluwọde lo tu si oju popo lawọn ipinlẹ Kano lẹkun ariwa orilẹede Naijiria bi ọjọ karun un iwọde ṣe n tẹsiwaju.
Lara awọn oluwọde naa kan ni Zamfara ati Kaduna jade pẹlu aṣia orilẹede Russia lọwọ wọn.
Awọn fidio kan n kaakiri lori ayelujara to n ṣe afihan awọn oluwọde kan bi wọn ṣe n gbe aṣia orilẹede Russia kaakiri ti wọn si n kọminu lori eto ọrọ abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Ko si ẹni mọ idi ti wọn fi n ju aṣia Russia kiri, ṣugbọn ọpọ lo ti n woye pe o ṣeeṣe ko ni itum miran.
Nigba ti BBC ba Saadu Musa Abdullahi sọrọ lori idi to n gbe asia Russia soke dipo ti orilẹede Naijiria lasiko iwọde EndBadGovernance, o ni “A ko ri ibi ti a n gbe gẹgẹ bii ara orilẹede Naijiria. A ko ro pe a jẹ ọmọ Naijiria. Idi ti a fe na asia Russia soke niyẹn.
O tẹsiwaju, “ko si ijọba ibilẹ kankan to ni alaafia ni agbegbe wa. Eyi ti wa saaju ki ijọba yii to bọ si ipo, ko si nnkan to yipada.
“Idi ti a fi na asia Russia soke ni lati pe akiyesi wọn iṣoro wa, lati jẹ ki wọn da si.
“A ti ri nnkan ti wọn se ni Mali, ti inu awọn araalu si n dun. Awọn araalu wọn n gbadun ju orilẹede ti awọn ara oke okun se tilẹyin lọ.”
Ki ni ijiya fun awọn eeyan to n gbe asia Russia ni Naijiria?

Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Abubakar Mohammad Usman ni ilana ofin ti orilẹede Naijiria fi aye gba awọn eeyan lati se ifẹhonuhan sugbọn gbigbe asia orilẹede mi soke lo jẹ.
O ṣapejuwe iwa yii gẹgẹ bii iditẹmọjọba, to si se koko ki awọn olufẹhonuhan mọ ohun ti ofin sọ nipa iwa yii.
“Ti ọwọ ba tẹ awọn eeyan, ti wọn gbe wọn lọ si ile ẹjọ, agbẹjọrọ wọn le sọrọ pe wọn lẹtọ lati se ifẹhonuhan sugbọn ofin ko sọ pe wọn ẹtọ lati gbe asia orilẹede mii soke.
Ki ni a n pe ni iditẹmọjọba?
Iditẹmọjọba, gẹgẹ bii ofin se gbe kalẹ, Agbẹjọro Umar Bala ni ẹnikẹni to ba to sẹyin tabi ransẹ si eeyan kan pe ko wa gba ijọba tabi se ikọlu si Aarẹ ni a n pe iditẹmọjọba.
O ni ijiya iku lo wa fun ẹsun yii labẹ ofin.
“Ẹnikẹni to gbe ogun ti ijọba, tabvi gbero lati gba ijọba, agbegbe jẹbi ẹsun iditẹmọjọba, to si jẹbi ijiya iku.
“Ẹnikẹni to ba lẹdi apupọ mọ eeyan mi lati ditẹmọijọba lorilẹede Naijiria tabi ni ita naa jẹbi ẹsun iditẹmọjọba, ti iku si le jẹ ijiya ẹsun naa.”















