''Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti máwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń ṣàtìlẹyìn fáwọn tó ń na àsìá Russia sókè níbí ìwọ́de''

Oríṣun àwòrán, Ṣocial media
Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, IGP Kayode Egbetokun ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti mawọn eeyan ti wọn n ṣe agbatẹru awọn oluwọde to n na asia orilẹede soke lapa ariwa Naijiria.
Awọn olufẹhonuhan ọhun lo u asia Russia dani lati fi beere fun ijọba tuntun.
Ọgagba ọlọpaa sọ pe ilu oyinbo lawọn to n ṣagbatẹru mimu asia Russia dani nibi iwọde n gbe.
Egbetokun ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe iwadii lori gbogbo awọn to n ṣe atilẹyin fawọn to n na asia Russia soke yii ti awọn si ti ṣawari wọn.
O ni gbogbo akaunti wọn ni ijọba ti gbe tipa bayii ki wọn le ma baa ri owo na mọ.
Bakan naa tun ni ọga ọlọpaa sọ kii ṣe awọn agbofinro lo yinbọn pa oluwọde to ku ni Kubwa l’Abuja.
O ni ko si ọlọpaa to tii yinbọn sawọn oluwọde lati igba ti iwọde naa ti bẹrẹ.
Orílẹ́èdè Russia sọ̀rọ̀ lórí àwọn olùwọ́de tó ń na àsìá ilẹ̀ náà sókè ní Kano

Ijọba Russia lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko mọ nnkan kan nipa awọn eeyan to gbe asia orilẹede naa kiri lati fẹhonuhan ni Naijiria.
Lọjọ Aje, ọjọ karun-un oṣu keje ọdun 2024, ni ajọ to n ṣoju Russia ni Naijiria, fi atẹjade kan sita pe awọn ko lọwọ ninu iwọde ti wọn ti gbe asia Russia kiri lorilẹede yii.
Gẹgẹ bi awọn aṣoju Russia ni Naijiria ṣe wi, “ Ijọba apapọ Russia ati awọn aṣoju wọn ko lọwọ ninu igbesẹ yii, awa si kọ ni adari rẹ.
“ Gẹgẹ bi ìṣe wa, a n tẹnumọ ọ bayii, pe Russia ki i koju bọ ọrọ abẹnu awọn orilẹede ilẹ okeere, Naijiria naa si jẹ ọkan lara wọn.”
“ Awọn ti wọn fi asia Russia wọde ni Naijiria ṣe bẹẹ lati ọwọ ara wọn ni, ko si tumọ si pe ijọba orilẹede Russia mọ nipa rẹ. ”
Ilẹ Russia sọ pe oun bọwọ fun ijọba awarawa ti Naijiria n lo, ati pe ẹtọ ni fun awọn eeyan lati fi ẹhonu wọn han lọna alaafia.
Wọn ni bi ifẹhonuhan ṣe wa di rogbodiyan yii ko dun mọ awọn ninu.
Russia sọ pe bi iwọde yii ba tun ṣe bẹẹ to di rogbodiyan, awọn ko faramọ iru ẹ ni tawọn.
Ọjọbọ, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ ọdun 2024 ni iwọde ‘ẹ fopin si ijọba buruku’ bẹrẹ ni Naijiria, laarin rẹ ni rogbodiyan ti bẹ silẹ lapa Oke-Ọya.
Ninu iwọde ọhun ni awọn eeyan kan si ti gbe asia Russia kiri lapa Ariwa Naijiria kan naa.
Ìjọba Nàìjíríà sọ ohun tí yóò ṣe fún àwọn olùwọ́de tó ń gbé àṣíá ilẹ̀ òkèèrè kiri lásìkò ìwọ́d

Oríṣun àwòrán, sadu labin gusau
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ṣalaye pe oun ko ni kawọ gbera maa woran ki awọn kọlọransi kan maa gbe aṣia ilẹ okeere kiri tabi tabuku ba aṣia orilẹede Naijiria lasiko iwọde.
Ọga agba ileeṣẹ ọmọogun alaabo lorilẹede Naijiria, Ọgagunagba Chris Musa ni ẹsun to sọ rọ mọ iditẹgbajọba ni iwa bẹẹ, oju ti ileeṣẹ ọmọogun yoo si wi wo o ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ niyi.
Ọgagun agba Musa ṣalaye ọrọ fawọn akọroyin lẹyin ipade awọn olori ileeṣẹ ọmọogun pẹlu aarẹ Tinubu lọjọ Aje nilu Abuja.
Lori ọrọ ipe fun iditẹgbajọba, Ọagun agba Musa ni orilẹede olominira to da duro ni Naijiria jẹ, awọn ileeṣẹ alaabo gbogbo nibẹ ni yoo si ja fitafita lati rii pe eera kan ko rin eto iṣejọba tiwantiwa nibẹ.
“A ko ni gba ki ẹnikẹni maa gbe igbesẹ tabi pe fun ayipada ijọba labẹ eredi biotiwulẹo mọ.”
O ni lootọ gbogbo awọn to n gbe aṣia yii kiri leeyan le ri pe ọmọde niwọn eleyi to fihan pe awọn kan lo n ran wọn ni iṣẹ naa. O ni awọn yoo ṣawari gbogbo awọn to n dana labẹ aṣọ fun wọn.
Ki lo de ti awọn oluwọde kan fi n ṣe iwọde pẹlu aṣia orilẹede Russia?

Ọpọlọpọ awọn oluwọde lo tu si oju popo lawọn ipinlẹ Kan lẹkun ariwa orilẹede Naijiria bi ọjọ karun un iwọde ṣe n tẹsiwaju.
Lara awọn oluwọde naa kan ni Zamfara ati Kaduna jade pẹlu aṣia orilẹede Russia lọwọ wọn.
Awọn fidio kan n kaakiri lori ayelujara to n ṣe afihan awọn oluwọde kan bi wọn ṣe n gbe aṣia orilẹede Russia kaakiri ti wọn si n kọminu lori eto ọrọ abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Ko si ẹni mọ idi ti wọn fi n ju aṣia Russia kiri, ṣugbọn ọpọ lo ti n woye pe o ṣeeṣe ko ni itum miran.















