Ìjọba gbe ṣọ́ọ̀ṣì 4,000 tìpa, ìdí abájọ rèé

Aworan agbelebu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O le ni ṣọọṣi ẹgbẹrun mẹrin ti ijọba orilẹede Rwanda ti gbe tipa laarin oṣu kan bayii lori wi pe wọn kuna lati tẹle alakalẹ ilana ijọba lori ọrọ ilera ati abo to fi mọ k'awọn ile ijọsin ma maa pariwo si araalu leti mọ.

Ọrọ yii lo ti kan awọn ṣọọṣi kekeke at'awọn mọsalaaṣi diẹ julọ eyi ti ọpọ wọn wa ni eti odo.

Minisita to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ ni Rwanda, Jean Claude Musabyimana, ṣalaye pe ijọba ko gbe igbesẹ yii lati ma le jẹ k'awọn eeyan lọ maa gbadura ṣugbọn lati ri pe awọn olujọsin wa lai lewu ati ni idakẹjẹ.

Igba akọkọ ree ti ijọba yoo gbe awọn ile ijọsin to pọ to bayii tipa lati igba to ti ṣofin ti yoo maa mojuto bi awọn ile ijọsin ṣe n pọ kaakiri orilẹede Rwanda.

Ki lo wa ninu ofin ijoba lori awọn ile ijọsin?

Ofin ti ijọba Rwanda gbe kalẹ ni bii ọdun marun un sẹyin lori awọn ile ijọsin sọ pe wọn ko gbọdọ maa lo gbohun-gbohun ti yoo maa pariwo di awọn ara adugbo lọwọ.

Bakan naa ni ofin yii tun sọ pe awọn ile ijọsin gbọdọ maa ṣe nnkan wọn leto leto, ki wọn si tun ri pe ko si ewu ni ayika ile ijọsin wọn.

Ofin ijọba yii tun sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ da ṣọọṣi silẹ gbọdọ lọ sile ẹkọ oniwaasu ki wọn to le ṣe bẹẹ.

Ẹẹdẹgbẹrin ṣọọṣi ni ijọba kọkọ tipa lọdun 2018 nigba ti ofin naa bẹrẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba naa ni Aarẹ Paul Kagame sọ pe orilẹede Rwanda ko nilo ile ijọsin to pọ to bayẹn tori eto ọrọ aje orilẹede naa ko gbe e.

Ijọba ni oun gbe igbesẹ yii tori oun ti fawọn ile ijọsin lọdun marun un lati tẹ le ofin ti ijọba ṣe.

Awọn alaṣẹ agbegbe ati igbimo RGB to n ṣoju ijọba Rwanda lo n ṣagbatẹru gbigbe awọn ile ijọsin tipa yii.

Adari igbimọ RGB, Usta Kayitesi sọ fun ileeṣẹ iroyin ori ayelujara, New Times news wi pe "ijọba ti fi ero rẹ han lori bi ile ijọsin ṣe n pọ kaakiri orilẹede Rwanda.

Bẹẹ ni a si tun n ri ọpọ ile ijọsin to ti di ẹgẹrẹ miti, nigba t'awọn mii si dọti."

Musabyimana ṣalaye pe ọpọ awọn ile ijọsin ti ijọba tipa lo n jọsin labẹ atibaba eyi to lewu fawọn olujọsin.

Ni bayii, ile ijọsin 4,223 ni o ti di titi pa.

Ọpọ awọn eeyan orilẹede Rwanda lo jẹ ẹlẹsin Kristẹni, nigba t'awọn mii naa tun jẹ ẹlẹsin ibilẹ.

Ọpọ awọn ṣọọṣi igbalode lo wa ni Rwanda t'awọn alufaa wọn maa n sọ pe awọn lagbara lati ṣiṣẹ iyanu.

Ọpọ iru awọn ṣọọṣi yii lo ni ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ijọ ti wọn n jọsin lọjọ Aiku, nigba t'awọn mii n lo ile ijọsin kekeke ti ko duro nilẹ daadaa.