Kí ló fa ìdẹ́yẹsí ọmọ Naijiria tó ń díje fún àmì ẹ̀yẹ Miss South Africa yìí?

Chidimma Adetshina

Oríṣun àwòrán, Miss South Africa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigba ti Chidimma Adetshina to jẹ akẹkọọ imọ ofin ni South Africa wọ ipele to kẹyin ninu idije omidan to rẹwa julọ nilẹ naa, lawọn eeyan orilẹede ọhun bẹrẹ si n sọrọ kobakungbe si.

Bo tilẹ jẹ pe ẹni ọdun mẹtalelogun naa ko fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ, awọn eeyan ṣewadii rẹ titi ti wọn fi ṣawari pe ọmọ Naijiria ni baba rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ South Africa ni oun funra rẹ ti iya rẹ si wa lati Mozambique, ti ko fi bẹẹ jina si South Africa.

Lara awọn to n sọrọ kobakungbe si Chidimma loju opo X sọ pe “lorukọ awa ọmọ South Africa, a ko da a mọ, bẹẹ ni a ko mọ orukọ rẹ, yoo dara ko gbe ẹru rẹ ko si pada sibi to ti wa.”

Amọ nibo ni Chidimma Adetshina ti wa? Ọmọ South Africa ni gẹgẹ bi awọn to ṣagbatẹru idije naa ṣe fidi rẹ mulẹ ninu iwadii wọn.

O sọ ninu oniruru ifọrọwerọ pe ilu Soweto ni wọn bi oun si, eyii ti ko jina siluu Johannesburg, o si dagba niluu Cape Town.

Amọ awọn to n sọrọ kobakungbe si ko fẹ ko yege ninu idije naa latari pe ọmọ Naijiria ni baba rẹ, koda ẹgbẹrun mẹrinla awọn eeyan lo tọwọ bọwe lori ayelujara pe ki wọn yọ ọ bii jiga ninu idije ọhun.

Awọn kan ninu awọn eeyan naa sọ loju po X pe “a ko le gba ki ọmọ Naijiria dije gẹgẹ bii omidan to rẹwa julọ ni South Africa.”

Amọ ọrọ naa ti bi ọpọ eeyan ninu kaakiri ilẹ adulawọ.

Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati ba BBC sọrọ, Chidimma ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin abẹle kan ni South Africa pe idẹyẹsi ti oun n dojukọ lori ayelujara ti mu ki oun tun ero oun pa lori idije ọhun.

O ṣalaye pe ọrọ naa ṣafihan ikorira to wa laarin eeyan dudu si alawọ dudu ẹgbẹ rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni kii ṣe oun nikan ni baba rẹ wa lati orilẹede mii ninu idije ọhun amọ oun nikan ni wọn gbogun ti julọ.

Ki ni awọn to ṣagbatẹru eto naa sọ?

Chidimma Adetshina

Oríṣun àwòrán, Chichi Vanessa/ Instagram

Nigba ti BBC kan si awọn to ṣagbatẹru idije naa lati sọrọ lori idẹyẹ ti Chidimma Adetshina n doju kọ, agbẹnusọ wọn kọ lati sọrọ taara lori iṣẹlẹ ọhun amọ o ni ọdọbinrin naa yege lati dije.

Awọn to ṣagbatẹru idije naa ni awọn ko ni ọrọ miran lati sọ lori iṣẹlẹ naa yatọ si eyii ti wọn ti sọ ṣaaju lori awọn amuyẹ ti eeyan gbọdọ ni ko to le kopa ninu dije omidan to rẹwa julọ ọhun.

Wọn sọ siwaju si pe Chidimma ti ọrọ ọhun kan ko ni sọrọ kankan lori iṣẹlẹ naa mọ.

Ninu ohun ti wọn sọ, gbogbo awọn iwe ati ẹri to gbe kalẹ lati kopa ninu idije naa lawọn yẹwọ, ọdọbinrin ọhun si kunju oṣuwọn lati kopa ninu rẹ.

Mo fẹ fi ọrọ mi ṣe iwuri fun awọn ẹlomiran

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ile iwosan Chris Hani Baragwanath Academic Hospital, to wa niluu Soweto ni wọn bi Chidimma si, ọmọ Naijiria ni baba rẹ, ti iya rẹ si jẹ ọmọ Mozambique amọ Soweto ni Chidimma dagba si.

Nigba to n ba ileeṣẹ iroyin Sowetan Smag sọrọ, o ni oun ti ni oniruru iriri lati oriṣiṣi orilẹede latari pe idile ti wọn bi oun si jẹ eyii ti wọn wa lati oniruru orilẹede.

O fi kun pe inu oun dun lati kopa ninu idije naa amọ oun ko lero pe awọn eeyan yoo dẹyẹ si oun latari idije ọhun.

Lẹyin to wọ ipele komẹsẹ-ọ-yọ ni awọn eeyan kan ni south Africa bẹrẹ si n binu latari ibi ti baba rẹ ti wa.

O ni “awọn eeyan n bere loju opo X eredi ti mo fi n dije nigba ti mi o ki n ṣe ọmọ ilẹ South Africa, wọn ko faramọ ibi ti emi atawọn obi mi ti wa.

“Lakọkọ, ko kọkọ jọ mi loju, ṣugbọn bi mo ṣe n tẹsiwaji ninu idije naa ni idẹyẹsi naa bẹrẹ si n pọ si titi ti mo fi bi ara mi lere pe njẹ o yẹ ki n maa ṣoju orilẹede ti awọn eeyan rẹ ko fẹran mi?

Ninu fidio to fi wọ idije naa, o ni oun fẹ fi itan aye oun ṣe iwuri fun awọn ẹlomiran.

Kii ṣe Chidimma ni ẹni akọkọ ti wọn yoo wu irufẹ iwa yii si ni South Africa.

Wọn wu iwa kan naa si Melissa Nayimuli to kopa ninu idije ọhun lọdun to kọja latari pe Uganda ni orisun rẹ.