Wo ohun tí Tinubu àti àwọn gómìnà sọ lórí ìwọde #EndBadGovernance tó wáyé

Oríṣun àwòrán, @Presidency, Kano and Lagos state government
Aarẹ Bọla Tinubu ati awọn gomina kan ti fi ero ọkan wọn han lori iwọde ebi n pa wa to n lọ lọwọ ni Naijiria.
Ọkan ninu awọn agbẹnusọ Aarẹ, Malam Abdul'aziz Abdul'ziz, ṣalaye fun BBC pe Aarẹ Bola Tinubu koro oju si bi awọn eeyan kan ṣe sọ iwọde di rogbodiyan ni awọn ipinlẹ kan lorilẹede yii.
‘’Tita ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, ole jija, didana sun dukia ati awọn iwa aitọ to waye nibi iwọde to ṣẹṣẹ bẹrẹ yii ko dun mọ Aarẹ Bola Tinubu ninu.
‘’Ijọba mọ pe ẹtọ araalu ni lati fi ẹhonu han, ṣugbọn ko si ijọba to faramọ jagidijagan bii eyi’’
Malam Abdul'aziz Abdul'ziz tẹsiwaju pe ijọba Naijiria ko tiẹ mọ awọn to gbe iwọde yii kalẹ.
O ni o ṣee ṣe ki wọn jẹ ajeji ti ẹnikẹni ko le tọka si ibi ti wọn ti wa.
Eyi lo ni o fi ṣoro fun ijọba lati ba wọn sọrọ.
‘’ A o ri ẹnikan kan, afi awọn ti wọn wa lojuu popo. Nigba ti a o si le ri ẹnikẹni tọka si pe o wa nidi iṣẹlẹ yii, bawo la ṣe fẹẹ ba a sọ ohunkohun.‘’
Bẹẹ ni agbẹnusọ Aarẹ wi.
O fi kun un pe iṣakoso Bọla Tinubu ko jokoo lasan, o ni gbogbo ọna ti nnkan yoo fi dẹrun fun araalu nijọba naa n wa. Ṣugbọn o ba ni lọkan jẹ pe awọn kan ti sọ iwọde di ija igboro ati ole jija.
Mà á jíṣẹ́ yín fún Ààrẹ Tinubu- Obaseki

Oríṣun àwòrán, @Godwin Obaseki Facebook
Gomina ipinlẹ Edo,Godwin Obaseki, ti ni oun yoo jiṣẹ awọn olufẹhonuhan naa fun Aarẹ Bola Tinubu.
Obaseki sọrọ yii lasiko to n ba awọn oluwọde sọrọ lagbegbe Ring Road, niluu Benin, l’Ọjọbọ,ọjọ akọkọ ninu oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.
Gomina Edo sọ pe oun mọ pe iya n jẹ awọn eeyan ipinlẹ naa ati awọn ọmọ Naijiria lapapọ.
‘’Gẹgẹ bii gomina yin, mo mọ pe inu yin o dun, ebi n pa yin. Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe mo maa gbe ohun tẹ ẹ wi lọ s’Abuja.
‘’Ẹ ni ki Aarẹ din owo epo ku, mo maa jiṣẹ fun wọn. Ẹ ni awọn olori ẹgbẹ n mu ki ounjẹ wọn gogo, ẹ jẹ ki n mọ awọn to n daamu yin ninu wọn, ijọba maa gbe wọn. A maa ri i daju pe ounjẹ walẹ.
‘’A maa tu awọn agbero ka. Ẹ ni ka tun ọna ijọba apapọ ṣe, ka si din owo ina ku, mo maa lọọ sọ iyẹn fun wọn l’Abuja ni.
‘’Mo maa din owo ileewe ku nipinlẹ Edo, mi o nilo ijọba apapọ lati ṣeyẹn’’
Ṣugbọn bo ti wu ko ri, Obaseki ni oun yoo fi ẹdun ọkan awọn eeyan to n wọde naa lọ Aarẹ Naijiria to n darii gbogbo ọrọ orilẹede yii.
O ni ki wọn ma jẹ ki awọn ọmọ ganfe gba iwọde naa mọ wọn lọwọ, ki wọn si ma dana sun dukia ijọba.
Gomina Kano
Ṣaaju iwọde to pada di wahala nipinlẹ Kano, Gomina Abba Yusuf, pe ipade awọn alẹnulọrọ, nibi to ti kilọ nipa iwọde ọhun.
Gomina Yusuf ṣalaye pe oun faramọ iwọde alaafia ti araalu yoo ti sọ ẹdun ọkan wọn lori ounjẹ, owo ina to wọn gogo, ọna ti ko daa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
O ni ṣugbọn awọn wo lo fẹẹ ṣe iwọde ọhun, ko ma baa di ohun ti awọn janduku yoo tẹwọ gba.
Nigba ti ọrọ pada bẹyin yọ ni Kano,ti iwọde di rogbodiyan ati ole jija, Gomina Abba Yusuf sọ pe, ‘ọpọlọpọ ṣọọbu, ọkọ bọọsi, ibudo ijọba ni wọn ti bajẹ, wọn si tun ṣe ọpọ araalu leṣe’’
Gomina yii kede konile-o-gbele fun wakati mẹrinlelogun lẹyin rogbodiyan naa.
Gomina Eko
Ọjọru ni Gomina Eko,Babajide Sanwo-Olu, ti kọkọ kilọ ṣiwaju iwọde.
O ni kawọn ara Eko ma jẹ ki oun to ṣẹlẹ lasiko EndSARS tun waye mọ lasiko yii.
Ọrọ yii ni ọpọ eeyan gbagbọ pe o mu iwọde Eko lọ wọọrọwọ lọjọ akọkọ ti iwọde waye.
Gomina Sanwo-Olu sọ pe oun gbagbọ pe ifẹhonuhan kọ ni yoo yanju iṣoro bayii, yoo wulẹ tun ko ba daadaa to wa nilẹ ni.
Gomina Eko naa sọ pe iwọde ọjọ mẹwaa ko le tun ọrọ aje ṣe lọna ti imọ nipa ọrọ aje funra rẹ yoo gba tun nnkan ṣe.
Bakan naa ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademola Adeleke, ti rọ awọn eeyan ipinlẹ naa ṣaaju lati ma ṣe da wahala silẹ lasiko rogbodiyan.
Adeleke kilọ pe oun ko ni i fi aaye gba rogbodiyan kankan nitori iwọde.
Bakan naa ni awọn gomina Yobe ati Borno, kede konile-o-gbele latari iwọde to di rogbodiyan ati itajẹsilẹ lọdọ wọn.














