Mo lọ fásitì, àìríṣẹ́ sọ mí di ọlọ́kadà, wọ́n tú ń fi àdá lémi kiri – Olùwọ́de kan sọ ẹ̀dùn rẹ̀

Àkọlé fídíò, Mo lọ fásitì, àìríṣẹ́ sọ mí di ọlọ́kadà, wọ́n tú ń fi àdá lémi kiri – Olùwọ́de
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Akẹkọọjade fasiti kan ti ke si ijọba apapọ lati wa ojutu si iṣoro airiṣẹṣe ni Naijiria.

Okunrin ọhun, Oluwasegun Obaloluwa sọ pe ọdun 2009 ni oun pari ni Fasiti ilu Ilorin amọ oun ko riṣẹ kankan.

Latari airiṣẹṣe naa, o tun pada sile ẹkọ iṣegun, School of Health Technology niluu Offa lati kawe si nipa ẹkọ imọ nọọsi amọ pabo naa ṣi ni.

O ni “mo pari ni Health Tech Offa ni 2011, lẹyin naa mi o riṣẹ”

“Mo tun n dako ni Odo Otin, mo dako eeka mẹta maalu jẹ nigba mẹta, mi o ri nnkankan mu ninu oko naa, ohun lo jẹ ki n pada sibi ọkada mi, ọkada na ni a n ṣe titi di isinyii.

“Bi a tun ṣe n gun ọkada naa, awọn kọlọrọsi tun n le wa kaakiir igboro, wọn n gba ọkada lọwọ wa…. Igba meji ni wọn ti ṣa mi ladaa.”

Obaloluwa parọwa si ijọba Bola Tinubu ko tun Naijiria ṣe ki ara le rọ gbogbo mutumuwa.

Obaloluwa sọ fun BBC News Yoruba wi pe, oun naa ka iwe jade ni Fasiti ti ijọba apapọ to wa niluu Ilorin ni ọdun 2009.

Aworan Ọbaloluwa lori ọkada rẹ

Lẹhin igba ti mo jade ni Fasiti naa ti ko si isẹ, mo tun pada lọ si School of Health to wa ni iluu Offa ni Ipinlẹ Kwara. Sugbọn gbogbo iwe ti wo ka lo ja si asan patapata.

Obaloluwa sọ wi pe, oun wa isẹ kakiri sugbọn ko si isẹ nigbati oun ko mọ ẹnikankan ti o le ran oun lọwọ lati le ri isẹ ìjọba tabi omiran.

Ranti Oluwasegun to jẹ ọkan lara awọn akanda nipinlẹ Ọsun ti salaye bi ìjọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu se mu ìnira ba awọn akanda.

Ranti tun tesiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe, iya to pọ lo n jẹ awọn eeyan ti ki se akanda. O ni ki ni awọn akanda ti ko ni oju tabi ẹsẹ fẹ ṣe ni akoko inira to wa ni orile-ede Naijiria lọwọ lọwọ.

O wa rọ Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati boju wo inira ti awọn ọmọ orile-ede yii doju kọ ni akoko yii.

Adetunji Ajala ẹni to jẹ adari fun awọn oluwọde naa, lo ti rọ gbogbo awọn to fara han ki wọn maa se ba ohunkóhun jẹ rara, nitori iwọde alaafia ni awọn fẹ ṣe.

Ajala tun fi kun wi pe, iwọde naa tesiwaju fun ọjọ mẹwaa gbako.