Báyìí ni ìwọ́de #Endbadgovernance ṣe wáyé ní Eko, Ibadan, Osogbo, Ilorin

Níṣe ni gbogbo àdúgbò dá páropáro ní ìpínlẹ̀ Eko bí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀bù, àwọn ilé ìfowópamọ́ ṣe wà ní títìpa.
Àmọ́ pẹ̀lẹ́ kùtù ni ètò ìwọ́de láti fi pé fùn ìfòpinsí ìjọba tí kò dára ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn olùwọ́de, tí wọ́n gbé onírúurú àkọlé, tí wọ́n sì ń pariwo kí ìjọba tí kò dára dópin ní Nàìjíríà, kó ara wọn jọ sí Ikeja kí wọ́n tó mórílé Freedom Park, ọ̀kan lára àwọn ààyè tí ilé ẹjọ́ fún wọn láṣẹ láti lò fún ìwọ́de náà.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tẹ̀lé àwọn olùwọ́de náà ní iwájú àti lẹ́yìn.
Bákan náà ni àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò dúró wámúwámú káàkiri àwọn àdúgbò ní ìpínlẹ̀ Eko tó fi mọ́ Freedom Park láti ri pé wàhálà kò bẹ́ sílẹ̀ níbi ìwọ́de náà.
Àwọn olùwọ́de náà sọ pé ìwọ́de oní àláfíà ni àwọn fẹ́ ṣe, tí àwọn kò sì ní fi ààyè gba jàgídíjàgan rárá.
Wọ́n ní ohun tí àwọn ń fẹ́ ni kí ìjọba dá ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù padà, pèsè ètò ààbò àti láti ṣe àwọn àtúntò tí yóò mú ìrọrùn bá àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè yìí.
Ọjọ́ mẹ́wàá ni àwọn olùwọ́de ní àwọn máa fi ṣe ìwọ́de títí tí ìjọba fi máa tẹ́tí sáwọn ìbéèrè àwọn.
Kò wù mí láti máa ṣiṣẹ́ ọkada rárá ìjọba orile-ede Naijiria lo sọ mí dí Ọlọkada

Iwọde ebi ń pa wa to n waye kaakiri orilẹ ede Naijiria naa gberasọ ni nnkan bii agogo mẹsan-an owurọni Freedom park ni ilu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Osun.
Oniruuru akọle ni awọn ọdọ to n ṣewọde naa gbe dani lati fi ẹhonu wọn han si ijọba lori iṣẹ ati oṣi tawọn eeyan n koju.
Lara awọn akọle ti wọn gbe dani pe “ẹgbẹrun lọna aadọrin naira gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ ko si ni ibamu pẹlu ọwọn gogo to wa Naijiria.”
Awọn miiran ni ki ijọba da owo epo bẹntiroolu pada si iye to wa tẹlẹ ki Tinubu to gba ijọba pada loṣu Karun-un ọdun 2023.
Lara awọn oluwọde naa ni Oluwasegun Obaloluwa to n ṣiṣẹ ọkada.

Obaloluwa ni aisiṣẹ lo gbe oun de idi iṣẹ ọkada nitori oun kẹkọọ gboye ni ile ẹkọ giga Fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ilorin toun si kẹkọọ gboye lọdun 2009.
“Lẹyin ti mo jade ni Fasiti naa ti ko si iṣẹ ni mo tun pada lọ si School of Health to wa ni ilu Offa ni Ipinlẹ Kwara ṣugbọn gbogbo iwe ti mo ka lo ja si asan patapata nitori mi o ri iṣẹ fi ṣe.”
O ni eyi lo jẹ ki oun pinnu lati maa ṣe iṣẹ ọkada ki oun le maa ri ounjẹ nigba ti oun ko riṣẹ toun pẹlu iwe ti oun ka.
Ranti Oluwasegun to jẹ ọkan lara awọn akanda sọ pe ìjọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ko naani awọn akanda eeyan ati pe gbogbo eto rẹ ti ko inira ba awọn.
Oluwasegun rọ Aarẹ Bola lati boju aanu wo inira ti awọn ọmọ orilẹ-ede yii n doju kọ ni akoko yii ki wọn wa ojutuu si gbogbo nnkan to n ba awọn finra.
Adetunji Ajala, ẹni to jẹ adari fun awọn oluwọde naa rọ gbogbo awọn to fara han fun iwọde lati ma ṣe ba ohunkohun jẹ rara, nitori iwọde alaafia ni awọn fẹ ṣe.
Ajala tun fi kun pe ọjọ mẹwaa gbako ni awọn maa fi ṣe iwọde naa.

Perete ni awọn to jade ni Kwara

Ni Ilorin, ipinlẹ Kwara ẹwẹ, paroparo ni papa iṣere Metropolitan Square, ibi ti ile ẹjọ fun awọn olufẹhonuhan laṣẹ lati lo fun iwọde wọn, ni gbogbo ibẹ da.
Awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo miiran wa nibẹ lati mojuto awọn oluwọde amọ awọn oluwọde ko to nnkan nibẹ rara.
Awọn ọlọpaa fẹ ẹ pọ ju awọn olufẹhonuhan lọ nitori awọn eeyan ko tu sita boya nitori ibẹrubojo atawọn gbedeke ti ti ile ẹjọ gbe kalẹ lori iwọde naa.
Amọ bi awọn olufẹhonuhan naa ṣe kere niye to, wọn ni awọn ko ni boju wẹyin afi ki awọn ṣe ifẹhonuhan.

Àwọn oríkò tó yẹ kí àwọn olùwọ́de ebi- ń-pa-ilu ti pàdé dá paroparo l'Ondo
Awọn oriko mejeeji ti o yẹ kawọn oluwọde ti pade n'ilu Akure, olu ilu Ipinlẹ Ondo lo da paroparo bi awọn ọdọ to ti n gbaradi fun iwọde ebi-n-panu naa ṣe kọ lati kopa l'Ondo.
Ileeṣẹ BBC Yoruba lọ si A Division ati Cathedral to jẹ oriko mejeeji to yẹ ki awọn oluwọde ti pade, awọn oriko yi da paroparo to si jẹ pe awọn Ọlọpaa ni wọn wa ni awọn oriko naa.
Awọn Agbofinro lo wa ni gbogbo aarin igboro Akure eyi ti awọn ara ilu fi sọ pe ifarahan awọn agbofinro lo fa ibẹrubojo eyi ti ko jẹ ki awọn ọdọ naa jade lati se iwọde.
Lasiko ti ileeṣẹ BBC Yoruba ṣabewo si ọja ọba, gbogbo ile itaja lo wa ni titi pa latari ibẹru ohun to le waye lasiko iwọde naa.
Ṣugbọn awọn eniyan ni ireti pe awọn ọdọ Ipinlẹ Ondo si le darapọ mọ awọn ojugba wọn Jakejado orileede yii ni ọjọ keji ifẹhonuhan naa lati lati se iwọde.
Èyí ni bí ìwọ́de 'Endbadgovernance' ṣe ń lọ láwọn ìpínlẹ̀ Naijiria

Kaakiri ilẹ Naijiria lonii, ọjọ akọkọ ninu oṣu kẹjọ ọdun 2024, o fẹrẹ ma si ibi kan ti awọn agbofinro ko ti duro wamu lati kapa rogbodiyan to ba fẹẹ bẹ silẹ latari ifẹhonuhan ti awọn kan kede rẹ lati ṣe.
Awọn ipinlẹ bii Ogun, Ondo, Ekiti, Eko titi to fi de olu ilu Naijiria ti i ṣe Abuja ni awọn agbofinro ti duro wamu laarọ kutu, bi eṣinṣin ba kọja lọna aitọ, wọn yoo wọn ọn danu ni.
Ṣugbọn lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ohun ti awọn akọroyin BBC jakejado awọn ipinle yii jabọ ni pe awọn oluwọde naa ko jade ni awọn ipinlẹ kan.
Ipinlẹ Osun ni tiẹ ti n gbaradi lati bẹrẹ iwọde nigba ti BBC debẹ, Freedom Park l’Osogbo ni wọn ti fẹẹ gbera .
Bakan naa lo ri n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.Awọn oluwọde kan bẹrẹ tiwọn ni agbegbe Iwo Road, nigba ti awọn kan bere lati Yunifasiti Ibadan, U.I.
Wọn de awọn agbegbe bii Agodi-Gate, o si ṣee ṣe ki wọn morile ọfiisi gomina pẹlu.

BBC fidi ẹ mulẹ pe paroparo ni ibudokọ Ọjọta niluu Eko da, awọn agbofinro nikan ni wọn wa niduuro wamu, oluwọde kan ko jade .
Bakan naa lọmọ ṣori nipinlẹ Ogun, nibi ti kootu ti ni wọn ko gbọdọ wọde kiri ilu, bi ko ṣe ki wọn lo papa iṣere MKO Abiola, Abeokuta, Papa iṣere Dipo Dina n’Ijebu-Ode, Ansarudeen Grammar Sch ati Remo Divisional High Sch to wa ni Sagamu.
Awọn oluwọde ko si ni papa iṣere MKO Abiola to wa ni Kuto, l’Abeokuta, awọn ọlọpaa, awọn NSCDC ti i ṣe aabo ara ẹni laabo ilu ni wọn wa nibẹ bamu.
Gẹgẹ bi ohun ti a ri l’Abeokuta, ibẹrubojo wa lọkan awọn araalu naa, ọpọ wọn ko jade, bẹẹ ni awọn oniṣọọbu ko ṣi i, ṣugbọn awọn mi-in ti n fi ọkan akin mura ibi iṣẹ wọn lẹyin ti wọn ko ri oluwọde kankan ko jade.
Niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo, awọn olutaja ko ṣilẹkun, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọja mi-in wa niwaju ṣọọbu wọn, ṣugbon won ko ṣi i.
Bẹẹ naa lo ri nipinlẹ Kwara. Awọn eeyan ko jade lọ sibi iṣẹ nitori ibẹru ohun to le ṣẹlẹ, ṣugbọn awọn agbofinro wa nigboro daadaa.
Ìwọ́de di méjì l’Abuja, àwọn tó ń tako ìwọde pàdé àwọn afẹ̀hónúhàn

Iwọde ti gbera sọ niluu Abuja ti i ṣe olu ilu Naijiria.
Yatọ si awọn ipinlẹ yooku ti awọn oluwọde ko ti jade, awọn olufẹhonuhan lori ebi ati ìyàn ti bẹrẹ l’Abuja ni tiẹ.
Ṣugbọn bi awọn afehonuhan naa ṣe jade ni awọn kan naa jade tako wọn, wọn lawọn ko faramọ ifehonuhan naa.
Oriṣiiriṣii akọle ni awọn to tako iwọde gbe dani, ninu eyi ti wọn ti ni ki awọn olufehonuhan ṣe suuru fun Aarẹ Bola Tinubu.
Awọn to tako iwọde naa sọ pe iwọde kọ ni yoo tan iṣoro Naijiria, wọn ni awọn ti wọn n ṣewode ko si gbọdọ ba dukia ijọba abi ti araalu jẹ.
Bakan naa ni awọn olufehonuhan naa gbe akọle to n kede inira ọlọkan-o-jọkan dani.
Won ni kijọba da owo epo pada si iye to wa ki Tinubu too gbajọba.
Ninu ọrọ rẹ, AIG Joshua Ogundele, ọkan lara ọga ọlopaa Zone 7 l’Abuja to ba BBC sọrọ, kilọ fun awọn afehonuhan naa lati ṣe jẹjẹ.
Ogundele sọ pe loootọ ni ofin faaye gba wọn lati fi ẹhohu han, ṣugbọn wọn gbọdọ ṣọra, ki awọn janduku ma baa gba a mọ wọn lọwọ ti yoo si di rogbodiyan.
Ọga ọlọpaa Ogun, CP Abiodun Alamutu naa fi ọkan awọn araalu balẹ lori iwọde yii, o ni ki wọn maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya rara.
Ìwọ́de gbéra sọ l’Ọṣun, ‘a kò fẹ́ ìjọba Tinubu mọ’ ni wọ́n ń wí

Ẹ̀wẹ̀, awọn olufẹhonuhan nipinlẹ Ọsun ti bere iwọde tiwọn.
Akọle ti ko jọra wọn ni wọn gbe dani, lara re ni eyi to n kede pe awọn ko fe ijọba Bola Tinubu mọ.
Awọn oluwọde naa kọ akọle to n kede ebi, ìyà, inira ati bẹẹ bẹẹ lọ, wọn si n wọde lohun kan naa.
Kedere ni akọle nla kan han lọwọ wọn, eyi to n kede pe, ẹ jẹ ka dide, ka fopin si ijọba buruku.
Ọdọ ni pupọ ninu awon olufẹhonu han naa, wọn tọ lọwọọwọ lojuu popo.
Kò sí ìwọ́de l’Ekiti
Bi a ṣe n kọ iroyin yii, ipinlẹ Ekiti naa ko gburo awọn olufẹhonuhan bi irọkẹkẹ rẹ ṣe gbilẹ to.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, paroparo ni gbogbo agbegbe da l’Ado-Ekiti ti i ṣe olu ipinlẹ naa.
Ṣugbọn nibi ti awon eeyan to je abarapa ko ti i wọde ni awọn ipinle mi-in, awọn akanda eda jade lawon ibi kan lati fi ehonu tiwon naa han.
To ba tun ṣe n lọ si, BBC Yoruba yoo maa fi to yin leti.













