Ẹ gbo ewúro sójú kọ̀lọ̀rànsí tó bá fẹ́ fa wàhálà tàbí dáná sunlé lásìkò ìwọ́de - ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà pàṣẹ fáwọn agbófinró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Kayọde Ẹgbẹtokun ti ke sawọn ọlọpaa jakejado orilẹede Naijiria lati rii pe wọn “gbo ewuro si oju ẹnikẹni” to ba fẹ da wahala silẹ tabi maa dana sun dukia lasiko iwọde ‘ebi n panu’ to fẹ waye ni Ọjọbọ.
Iwọde naa eyi ti awọn ọdọ kan gbe kalẹ lati fi ẹhonu han tako iṣoro ọrọ aje ati ebi pẹlu iṣẹ to gbilẹ bayii lorilẹede Naijiria.
Ninu atẹjade kan to fi sita eyi to funrarẹ buwọlu, ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ni awọn to wa nidi iwọde naa kọ lati fi awọn iroyin gbogbo to yẹ nipa orukọ awọn atawọn nnkan miran bii awọn ọna ti wọn fẹ gba, ibudo gbogbo ti akorijọ iwọde wọn yoo ti waye atawọn nnkan miran to ọlọpaa leti.
Ọga ọlọpaa Ẹgbẹtokun tọka si ẹgbẹ kan ti orukọ n jẹ ‘Take It Back Movement’ gẹgẹ eyi ti orukọ to n jẹ gan ni ọpọitumọ to tako iṣejọba tiwantiwa ati ibọwọ fun ofin.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti ṣalaye idi ti gbogbo awọn ti wọn n gbero lati ṣe ifẹhonuhan ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ fi gbọdọ fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ pẹlu awọn ọlọpaa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adejọbi sọ pe o ṣe pataki kawọn to fẹ ṣe ifọhonuhan forukọ silẹ pẹlu awọn ọlọpaa tori aabo wọn ati lati ri pe wọn ko tapa sọfin lasiko iwọde.
Lati ọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa ti n sọ fawọn to fẹ ṣe ifẹhonuhan naa wi pe ki wọn wa forukọ silẹ, amọ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti kọ eti ikun si ikede yii.
Ninu atẹjade kan ti o fi sita, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe o ṣe pataki lati jẹ kawọn eeyan mọ pe ọgagba ọlọpaa, IGP Kayode Egbetokun ko le fi ẹtọ araalu dun wọn nipa ṣiṣe ifẹhonuhan.
Amọ, Ọgbẹni Adejọbi sọ pe ohun ti IGP Egbetokun n sọ ni pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe ifẹhonuhan amọ lai da omi alaafia ilu ru.
''Ileeṣẹ ọlọpaa ni lati ri pe ifẹhonuhan ko ṣakoba feto aabo Naijiria''
Adejobi sọ pe ‘’ojuṣe ileeṣẹ ọlọpaa ni lati rii pe ohun kohun to fi mọ ifẹhonuhan ko ṣakoba fun eto aabo orilẹede Naijiria.
Fun idi eyi, ki kepe awọn to fẹ ṣe ifẹhonuhan lati forukọ ati idanimọ wọn silẹ to fi mọ ibi ti wọn fẹ lo, ọna ti fẹ gba ati aago ti wọn fẹ ṣe iwọde jẹ ojuṣe ọlọpaa lati ri pe aabo to daju fun wọn ati lati ri pe ẹnikẹni ko tapa sofin.
O ṣe pataki lati mọ awọn to n gbero lati ṣe ifẹhohuhan nipinlẹ kọọkan tori ti ọlọpaa ko ba mọ awọn to n ṣagbatẹru iwọde yii, o le ṣakoba fun alaafia orilẹede.’’
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa sọ pe aimọ awọn alakoṣo oluwọde le mu inira, ibanujẹ ati ẹkun wa bi o ti ṣẹlẹ lasiko ifẹhonuhan EndSARS lọdun 2020.
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n sọ nipa ifọhonuhan ‘ebi n pa wa’ lori itagun ayelujara, eleyii ti awọn alakoṣo iwọde naa n gbero lati ṣe ni gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria ati niluu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.
Awọn araalu ti n pariwo lori bi ounjẹ atawọn nnkan mii ṣe gbowo lori ti ara si n ni ọpọ ọmọ Naijiria.
Ẹyin ti ẹ fẹ ṣe iwọde, ẹ wa forukọ ati idanimọ yin silẹ – Ogagba ọlọpaa
Lọsẹ to kọja ni ọga agagba ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria, Kayode Egbetokun ke pe gbogbo awọn ti wọn n gbero lati ṣe iwọde ifẹhonuhan ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ tete wa fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ.
Egbetokun sọrọ yii lọjọ Ẹti, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, nibi to ti jẹ ko di mimọ pe awọn naa ti n gbaradi fun eto aabo to pe ye lori iwọde ọhun.
Ọga ọlọpaa sọ pe ki gbogbo ẹgbẹ, ajọ ati awọn to n gbero lati kopa ninu iwọde fi orukọ silẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ wọn, lati le mọ iru eeyan ti wọn jẹ.
Siwaju sii lo sọ pe ẹtọ araalu ni lati fi ẹhonu wọn han nipa kikorajọ soju kan, ati pe wọn gbọdọ ṣe ẹ pẹlu alaafia lai si iwa jagidijagan.
“Awa naa fidi ẹtọ araalu labẹ ofin mulẹ nipa iwọde ifẹhonuhan alalaafia.
“Ṣugbọn ṣa, lati le daabo bo dukia ati ẹmi araalu, a rọ gbogbo awọn ẹgbẹ ti wọn n gbero lati kopa ninu iwọde ifẹhonuhan naa lati lọ fi orukọ ati idanimọ wọn silẹ lọdọ ọga ọlọpaa to wa ni ipinlẹ wọn, nibi ti iwọde yoo ti waye.
“Lati le ṣagbatẹru iwọde ifẹhonuhan alalaafia ti ko nii mu ipalara dani, ki wọn lọ fi awọn nnkan wọnyi silẹ: ipinlẹ ti wọn ti fẹẹ ṣe e ati ibi ti wọn yoo korajọpọ si; igba ati asiko ti wọn yoo fi ṣe e; orukọ ati idanimọ awọn adari olufẹhonuhan ati awọn alagbatẹru.”
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn fẹẹ tete mọ awọn to n gbero lati da iwọde ọhun ru, lojuna lati le tete ko wọn pamọ.












