Ohun tá a mọ̀ nípa ìpànìyàn tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Imo rèé

Oríṣun àwòrán, IMO POLICE COMMAND
Níṣe ni àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Imo, ẹkùn gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà wà ní nínú inú fu àyà fu bí èèyàn mẹ́rin ṣe ti dágbére fáyé ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ṣe ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Káàkiri ìpínlẹ̀ Imo ni wọ́n ti ń yìbọn láti bíi ọjọ́ mẹ́ta báyìí.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé agbègbè Wetheral Road, Bank Road, Douglas Road àti Ikenegbu, Owerri, olú ìlú ìpínlẹ̀ Imo ni ìró ìbọn ti ń dún lákọlákọ lọ́jọ́rú bí àwọn agbébọn náà ṣe ya wọ ìgboro.
Àmọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Henry Okoye sọ fún BBC Pidgin pé àwọn agbébọn náà kò yìnbọn lónìí rárá pé àwọn èèyàn kàn ń gbé ìròyìn irọ́ láti fi gbin ìbẹ̀rù sáwọn èèyàn lọ́kàn.
Lẹ́yìn tí ikọ̀ tó ń pè fún ìdásílẹ̀ ọmọ bíbí Biafra, IPOB kéde pé àwọn èèyàn kò gbọdọ̀ jáde fún ọjọ́ mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n sí ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Keje ọdún 2024 ni ìpínlẹ̀ Imo kò ti ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbébọn láàárín ọjọ́ mẹ́ta náà.

Oríṣun àwòrán, IMO POLICE COMMAND
Ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ni ìbẹ̀rùbojo gbọkàn àwọn èèyàn nígbà tí ìró ìbọn bẹ̀rẹ̀ sí ní dún lákọlákọ káàkiri ìlú Owerri.
Ìròyìn sọ pé àwọn agbébọn náà ṣekúpa èèyàn mẹ́ta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun níbi ìkọlù tó w;ayé ní agbègbè Orji, Ekemele àti Nwaoriubi ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Bákan náà ni wọ́n tún jó ọkọ̀ ìjọba níná , tí wọ́n sì tún jí awakọ̀ kan gbé lẹ́ìn tí wọ́n sun ọkọ̀ rẹ̀ níná.
Ọlọ́pàá kan, òǹtàjà àti ọkọ olórí àwọn obìnrin tẹ́lẹ̀ rí fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP wà lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ìpànìyàn yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn agbébọn pa ọlọ́pàá mẹ́rin àti obìnrin kan tó ń ṣe POS ní Irete lọ́jọ́ Ajé.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé sọ pé bí àwọn agbébọn náà ṣe ń yìbọn ni wọ́n ń pariwo pé kí àwọn èèyàn jókòó sí ilé wọn, pé wọn ò gbọdọ̀ jáde síta láti sọ pé àwọn jáde lọ́jọ́ tí àwọn bá ti kéde pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ jáde tí wan bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Láti nǹkan bíi ọdún kan sẹ́yìn ni àwọn èèyàn ti máa ń jókòó sílé ní àwọn agbègbè kan ní àwọn ìpínlẹ̀ Igbo àmọ́ tí nǹkan yàtọ̀ díẹ̀ láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìbọn yínyìn náà wáyé ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Imo lọ sí àwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà fúnra rẹ̀.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣèlérí láti ṣàwárí àwọn jàgùdà tó wà nídìí ìpànìyàn náà pàápàá àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú àwọn akẹgbẹ́ wọn.















