Ọba ìlú Oyotunji, Ọba Adefunmi II jáde láyé

Ọba Adefunmi II

Oríṣun àwòrán, OYOTUNJIAFRICANVILLAGE/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọba ìlú Oyotunji, Ọba Adejuyigbe Adefunmi kejì, ìlú Yorùbá kan tó wà ní ẹkùn gúúsù Carolina ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti jáde láyé.

Ìròyìn ní ẹ̀gbọ́n ọba náà, Akiba Kasale Meredith ló gún ọba náà ní ọ̀bẹ pa tí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Beaufort County ṣàlàyé pé nǹkan bíi aago mẹ́ta ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ọ̀sán ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje ni àwọn gba ìpè pé àwọn kan ti gún ara wọn ní ìlú náà tó wà ní Bryant Lane.

Wọ́n ní àwọn gbé ọba náà, ẹni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́ta lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ tó dágbére fáyé látàrí ìpalára tí ojú ọgbẹ́ ọ̀bẹ ti kó bá a.

Ìròyìn ní Meredith, lẹ́yìn tó gún ọba náà pa, sá kúrò ní ilé àmọ́ tí wọ́n ti ri báyìí tó sì ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ní Beaufort County.

Ẹ̀sùn ìpànìyàn ni wọ́n kà si Meredith lọ́rùn.

Ìlú wo ni Oyotunji?

Oyotunji jẹ́ ìlú àwọn Adúláwọ́ tó wà ní ẹ̀bá Sheldon, Beaufort County, South Carolina, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.

Ọba Efuntola Oseijeman Adelabu Adefunmi kìíní ló dá ìlú náà sílẹ̀ lọ́dún 1970.

Oyotunji jẹ́ ìlú tí wọ́n dá sílẹ̀ láti máa ṣe ìrántí ìlú Ọ̀yọ́ tó wà ní ìpínlẹ̀ Oyo, ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.

Gbogbo àwọn àṣà àtiu ìṣe ilẹ̀ Yorùbá ni wọ́n máa ń ṣe ní ìlú náà tó fi mọ́ àwọn ọdún àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Yorùbá.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n sí ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Keje ni ayẹyẹ ọdún Sango wáyé ní ìlú náà níbi tí wọ́n ti ṣàfihàn àti ìṣe ilẹ̀ Yorùbá.

Eékà ilẹ̀ mẹ́tàdínllọ́gbọ̀n ni ìlú Oyotunji wà lórí rẹ̀ ní Beaufort County.

Àwọn èèyàn tó lé ní igba ni ùgbàgbọ́ wà pé wọ́n ń gbé ní ìlú náà.

Láti ọdún 2005 ni Ọba Adejuyigbe Adefunmi Kejì ti ń darí ìlú náà lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀ tó tẹ ìlú náà dó.