Ilẹ̀ yíyọ̀ pa èèyàn 158, ọ̀pọ̀ di àwátì

India

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan 158 lo ti jade laye, ti awọn 157 mii si di awati lẹyin iṣẹlẹ ilẹ yiyọ to waye nipinlẹ Kerala, lorilẹede India.

Awọn adoola ẹmi ṣiṣẹ titi di oru alẹ ọjọ Iṣẹgun, wọn tun ti bẹrẹ bayii laarọ Ọjọru.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa ni eyii to buru julọ ti yoo kọlu agbegbe naa lati ọdun 2018 ti agbara omi gbe irinwo eeyan lọ.

Kaakiri India ni wọn ti gbe asia wọn si idaji bayii lati ṣọfọ awọn to ku fun ọjọ meji.

Ọkan lara awọn adari agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, Pinarayi Vijayan sọ pe iṣẹlẹ naa wọ ọpọ adugbo lọ ni Mundakkai and Chooralmala.

Ijọba ti ni ki awọn ilu to wa layika maa reti ojo arọrọda, bẹẹ lo tun gbe ile ẹkọ tipa ni agbegbe mejila ninu mẹrinla to wa nipinlẹ naa.

India

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ajọ National Disaster Response Force (NDRF), ọlọpaa, ologun ori omi ati ologun ofurufu lo pawọpọ lati doola awọn to ha sinu ilẹ naa.

Nnkan bii ẹgbẹrun mẹta eeyan ni wọn ti ri yọ bayii, ti wọn si ti ko lọ si agọ gbajawiri ti ijoba ṣeto fun wọn.

Adari ajọ NDRF, Akhilesh Kumar sọ fun ileeṣẹ iroyin ANI pe awọn ṣiṣẹ di nnkan bii aago mẹwaa alẹ ki ojo ati iji lile to ka ọwọ awọn ko.

O ni ojo wa lara ipenija awọn lati doola awọn to yẹ ki wọn doola.

Lagbegba Chooralmala, ọlọpaa ni okun lawọn fi n wọ inu omi lati doola awọn eeyan, eyii to mu ki iṣẹ naa ṣoro.

Nnkan bii ago meji oru ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ Aje.