Ta ni Ismail Haniyeh, olórí ẹgbẹ́ Hamas ní Palestine tí àdó olóró Israel ṣekúpa

Oríṣun àwòrán, EPA
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti sọ pe olori ẹgbẹ Hamas, Ismail Haniyeh ti ṣagbako iku ojiji niluu Tehran lorilẹede Iran.
Ẹgbẹ Hamas sọ pe ni ile rẹ niluu Tehran ni Haniyeh wa ti wọn ti ṣekupa a.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita ni o ti ṣalaye pe ayẹyẹ ifilọlẹ ati iburawọle aarẹ Iran tuntun, Masoud Pezeshkian, ni o lọ fun niluu Tehran ti o fi ṣagbako iku.
Ta ni Ismail Haniyeh nigba aye rẹ?
- Ibudo ogunlende kan to wa ni Gaza ni wọn bi Ismail Haniyeh si lọdun 1963, lati ibẹrẹ pẹpẹ lo si ti jẹ ọkan gboogi lara ọmọ ẹgbẹ Hamas.
- Lọpọ igba ni awọn alaṣẹ orilẹede Israel ti ju si ẹwọn, ti wọn tilẹ tun lee lọ si gusu orilẹede Lebanon fun oṣu mẹfa.
- Ni ọdun 2003, ori kooyọ ninu iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ ninu eyi ti orilẹede Israel ti gbiyanju ati gbẹmi oun ati oludasilẹ ẹgbẹ Hamas.
- Lẹyin ọdun mẹta, o jẹ olotu ijọba ilẹ Palestine fun igba diẹ lẹyin ti Hamas bori eto idibo to waye nibẹ, ki iṣẹlẹ rogbodiyan kan laarin Hamas ati Fatah to jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹgbẹ miran to wa ni Palestine to waye lẹyin ọdun kan.
- Ọpọ lo maa n wo Haniyeh gẹgẹbi ẹni to maa n farabalẹ woye ọrọ ko to gbe igbesẹ, koda wọn ni o ni ajọṣepọ to dan mọran pẹlu awọn ẹgbẹ miran ni ilẹ Palestine.
- Ni ọdun 2017 ni wọn yan an gẹgẹ̀ bi adari ẹka oṣelu ẹgbẹ Hamas. Atipo lo n ṣe lati nnka bii ọdun diẹ sẹyin laarin orilẹede Turkey ati Qatar.
- Ki o to jade laye, ipa gboogi lo n ko lori wiwojuutu alaafia si ogun to n ṣẹlẹ ni Gaza.
‘Iyanlẹnu gba a lọrọ naa ṣi jẹ’ fun awọn aṣiwaju ẹgbẹ Hamas
Rushdi Abualouf to jẹ akọroyin BBC ni Gaza, towa nilu London bayii sọ pe ọpọ lo rii Haniyeh gẹgẹ bi olori ẹgbẹ Hamas to maa n farabalẹ woye ọrọ ko to gbe igbesẹ.
O ni Haniyeh ti ṣe abẹwo si ilu Tehran laarin igba mẹwaa si marundinlogun lati igba to ti di olori patapata fun ẹgbẹ Hamas lati ọdun mẹfa sẹyin ‘o si ṣeeṣe ko jẹ pe ọkan rẹ maa n balẹ pe abo wa fun oun nibẹ.”
Akọroyin BBC naa ba awọn aṣiwaju ẹgbẹ Hamas kan sọrọ lowurọ ọjọru, ohun ti wọn si sọ fun ni pe, ọrọ naa ṣi n da bi ala loju awọn.
Awọn aworan asiko ikẹyin Haniyeh loke erupẹ
Ọjọ Iṣẹgun ni Haniyeh de ilu Tehran lati kopa nibi eto ibura fun aarẹ tuntun lorilẹede Iran, Masoud Pezeshkian, ti wọn dibo yan ni ibẹrẹ oṣu keje.
Eyi ni diẹ lara awọn aworan abẹwo naa – wakati diẹ ṣaaju iku rẹ

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, EPA
Ki ni ababọ eyi fun ẹgbẹ Hamas?
Bi ọrọ ṣe ri yii, a ṣi n reti ọrọ lati ẹnu ẹgbẹ Hamas lori iku adari wọn naa
Ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ kan n sọ ni pe, ṣiṣekupa adari ẹgbẹ naa kan ko le mu ki ẹgbẹ Hamas ju ọwọ silẹ tabi ye ogun un ja.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹgbẹ Hamas ti ṣapejuwe iṣekupani olori wọn bi iwa ọdaran to buru jai, eyi ti o si sọ pe oun naa maa gbẹsan.
Ẹgbẹ Hamas ti wa ranṣẹ ibanikẹdun si gbogbo eeyan Palestine, awọn Araabu ati gbogbo awọn musulumi kaakiri agbaye lori iku olori wọn.
Ọpọ awọn olori Hamas lawọn araalu kii saba mọ wọn, ọpọ wọn si ni wọn maa n saba moribọ lọwọ awọn agbenipa awọn orilẹede Israel.
Ọpọ wọn si ni wọn ki i jade sita lati kede ara wọn gẹgẹ bi olori Hamas, nigba tawọn to ba fi ara wọn maa n gbaiyanju lati fi ara pamọ fun orilẹede Israel.
Haniyeh ti wa ni ipo olori ẹgbẹ Hamas fun igba to ti pẹ, ati ọdun 1980 ni o si darapọ mọ ẹgbẹ naa.
Koda, o ti di ipo olootu ijọba Palestine mu ri lọdun 2006, amọ, wọn pada rọ ọ loye lẹyin ti Hamas gba ẹkun Gaza lati Fatah.
Lọdun 2017 ni wọn yan an gẹgẹ bi adari ẹka oṣelu ẹgbẹ naa.
Ni ọdun to tẹ le e ni 2018 ni orilẹede Amẹrika kede orukọ rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọdaran agbesunmọmi ti wọn n wa.
Haniyeh ti n gbe ni Qatar fun ọpọlọpọ ọdun.
Bo tilẹ jẹ pe orilẹede orilẹede Israel ko tii sọ ohun kan lori iku adari Hamas, minisita to n ri si ọrọ aṣa ni Israel sọ loju opo itakun ayelujara X rẹ pe ‘’ṣiṣeku pa Haniyeh yoo jẹ ki gbogbo agbaye di mimọ.’’














