Iṣẹ́ tíátà ni kò jẹ́ kí n kàwé – Ibrahim Chatta
Gbajumọ oṣere sinima ti ilu mọọka jakejade agbaye ni Ibrahim Chatta. Gẹgẹ bi o ṣe sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo yii, Ọmọ Tapa ni baba rẹ, iya rẹ si wa lati ilu Mọdakẹkẹ ni ipinlẹ Ọṣun.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, o ni lati kekere loun ti mọ pe iṣẹ oṣere tiata loun yoo ṣe jẹun, lati igba naa wa loun si ti gbajumọ ọ ni ṣan an.
Ibrahim Chatta ni Iṣẹ tiata ti gba ọpọlọpọ nnkan sọnu lọwọ oun. Lara rẹ si ni lilọ si ile ẹkọ.
O ni lọpọ igba nigba ewe oun lawọn obi oun maa n ro wi pe ile ẹkọ loun wa, amọṣa to jẹ wi pe ode ere loun morile.
“Awọn obi mi maa n ro pe ile ẹkọ ni mo wa, ṣugbọn mo ti tẹle awọn onitiata lọ nitori mo maa n ṣe ere tiata alarinjo nigba naa.”

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis
Gẹgẹbi ọrọ rẹ, iṣẹ are to wa nigba naa ni Arinjo eyi tawọ oyinbo n pe ni, “Travel Theater” ki ere to yirapada si sinima to wa lode oni.
“Mi o pari ileẹkọ girama, mi o ni iwe ẹri iwe mẹwaa ṣugbọn mo n ṣe eto ẹkọ agbelegboye.”
Gbajumọ elere itage naa tun ṣalaye pe funra oun loun kọ ara oun ni ede oyinbo bẹẹni ko si iwe ti oun ko le ka.
- "Ojú mi rí nípò Adelé Ọba, n kò le lọ sọ́jà tàbí jẹun níta, n kò sì le súnmọ́ ọkùnrin"
- Ogunde ló sọ fún Kunle Afolayan láti fi mí ṣe Baṣọ̀run nínú sinimá Anikulapo - Owobo
- Taiwo Bamidele Ondo Dwarf Judge: Ọlọ́run kò ṣe àṣìṣe pé ó dá mi ní aràrá
- Èèyàn kìí dá orin níbi tí wọ́n kò bá ti fẹ́ ẹ ni mo ṣe dá dúró nínú ìjọ Cele - Wòlíì Genesis Global
Irinajo Chatta sinu ere itage

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis
Lọdun 1985, iyẹn ọdun mọkandinlogoji sẹyin, ni Ibrahim Chatta bẹrẹ iṣẹ ere tiata.
O ni nigba naa, nibikibi ti awọn ba gbe ere lọ, awọn a ti tete maa ba awọn ọmọ olounjẹ ati alata bẹẹbẹẹ dọrẹpọ nitori lasiko ti ebi ba n pa wọn, awọn wọnyi lawọn maa n gbara le lati ye niagba naa.
O ni gẹgẹbi elere, eeyan gbọdọ mọ gbogbo nnkan nitori pe elere nilo ọpọlọpọ nnkan yala lerefe tabi ni ijinlẹ.
Idi ti mi o fi ki n bikita fun ami ẹyẹ

Oríṣun àwòrán, ibrahimchatta_lordthespis
Ọpọ lo maa n wi pe, eekan onitiata yii ti yẹ ko ti gba ọpọ ami ẹyẹ ti awọn ti wọn wo pe wọn ko dangajia to lagbo oṣere ti gba.
Awọn ololufẹ Chatta a tilẹ maa sọ pe iye oriyin to n gba kere si ipa to ni lagbo oṣere lorilẹede Naijiria lọ.
O ni oun ko gbagbọ pe oun dara ju alare kan lọ nitori pe, gẹgẹbi ọrọ rẹ, “gbogbo alare ni maa n daa loju emi.”
O ni ọpọ awọn ami ẹyẹ ti wọn ti gbe kalẹ ti awọn ololufẹ oun maa n wo pe wọn o ti fun oun ni ami ẹyẹ ko dede ri bẹẹ, “emi ni mi o fi sinima mi silẹ fun ayẹwo ami ẹyẹ naa.”






