"Ojú mi rí nípò Adelé Ọba, n kò le lọ sọ́jà tàbí jẹun níta, n kò sì le súnmọ́ ọkùnrin"
Yoruba ni ko si ohun ti ọkunrin le se, ti awọn obinrin naa ko le se.
Tẹlẹ tẹlẹ, kikida ọkunrin nikan lo n jẹ ọba nilu Sabomi Apoi amọ ti wọn kii fi Adele Ọba jẹ lasiko ti ọba waja.
Nibayii, awọn obinrin naa ti n jẹ Adele Ọba, ti BBC Yoruba si ba Adele akọkọ nilu naa, ẹni to wa lori apere fun ọdun mẹsan sọrọ lati mọ awọn iriri to ni lori apere.
Ọmọbabinrin Adesola Oladiran Ebiseni, tii se Adele Ọba akọkọ nilu Sabomi Apoi, to wa nijọba ibilẹ Ese Odo nipinlẹ Ondo sọrọ, ilẹ kun.
O si salaye bi obinrin se bẹrẹ si jẹ oye Adele Ọba ni ilu wọn, etutu ti wọn se fun, iye owo osu rẹ, bo se n sakoso ilu, ipenija to koju rẹ ati awọn ofin to de ipo adele.

“Baba mi lo se akọsilẹ ofin ko to jade laye pe ki wọn bẹrẹ si yan adele sori apere nilu wa”
Nigba to n salaye fun BBC Yoruba lori bo se jẹ adele ọba akọkọ ni Apoi, Ọmọbabinrin Ebiseni ni baba oun lo ti se ofin kalẹ, ko to waja.
“Ni ọdọ wa, obinrin ko jẹ adele ri amọ laarin awọn afọbajẹ ni wọn ti maa n yan adele.
Onitọhun si le wa lati agbegbe miran, kii se dandan ki adele wa lati ilu wa nitori ilu mẹsan lo wa nijọba ibilẹ wa.
Amọ nigba ti baba wa wa laye, ti wọn si wa lori itẹ, akọsilẹ abọ ipade kan ti wọn se fihan pe wọn ti yi itan ilu Apoi pada, amọ wọn ko tii fi ofin naa sọwọ si ijọba ipinlẹ lati buwọlu, ko si di ofin.
Ohun to wa ninu akọsilẹ naa ni pe ọmọbinrin ni wọn yoo maa lo bii adele, igba ti wọn wa jiroro pẹlu awa ọmọ ọba, awọn ọmọ baba mi fa mi silẹ.
Mo wa ba ọkọ mi tori emi ko gbe ninu ilu, mo si gba aaye lọwọ rẹ pe mo le se adele.
Nitori ifẹ ilu ni mo se gba lati jẹ oye naa.”

“Kii se nnkan to rọrun rara lati j Adele ba lọjọ mẹsan ta fi se etutu, se lo dabi pe a n gba aawẹ, ti a si n gba adura”
Nigba to n salaye awọn igbesẹ to rọ mọ jijẹ Adele Ọba, Ebiseni ni ọpọlọpọ nnkan lo rọ mọ jijẹ Adele Ọba.
“Ọjọ mẹsan ni wọn fi wa sori apere lati se idanilẹkọ fun wa lori bi wọn ti n se Adele Ọba, gẹgẹ bi wọn ti n se etutu fun ọba.
Ẹ maa tete ji ni aarọ, ẹ ti joko sori itẹ, awọn oloye naa yoo ti ji da lati wa maa kọ wa lori bi wọn ti n se lori apere.
Kii se nnkan to rọrun rara nitori ni ọjọ mẹsan naa, se lo dabi pe a n gba aawẹ, ti a si n gba adura.
Amọ gẹgẹ bii Adele Ọba, a ko gbọdọ wọ inu ọja, a ko si gbọdọ wọ asọ obinrin, awọn asọ ọkunrin ni a maa n wọ.
Bakan naa ni a ko gbọdọ jẹun ni ita, tabi kunlẹ ki eeyan. Bakan naa ni a ko gbọdọ kunlẹ ki ọkunrin fun gbogbo akoko ti a ba fi wa lori itẹ.
Ko mọ emi lara ti mo ba jade, amọ mo si maa n kunlẹ ki awọn ọba to jẹ ọrẹ baba mi."
Nigba ti wọn ni a ko gbọdọ sun mọ ọkunrin, emi wa bi wọn pe se wọn mọ pe emi ti ni ọkọ o, wọn ko si le ro pe maa sa fun ọkọ mi.
Amọ wọn ni ọkọ mi gan gan ko gbudọ sun mọ mi.
Wqọn n fi awọn ofin naa lọlẹ lati tọ adele sọna ni, ka maa baa ba ori itẹ naa jẹ.
Nigba ti mo kuro ni ipo Adele, mo n gbe igbe aye mi pada.

"Ida marundinlọgọrin owo ti baba mi to jẹ ọba onipo kinni n gba, ni wọn n fun emi ti mo jẹ Adele"
“Ida marundinlọgọrin owo ti baba mi to jẹ ọba onipo kinni n gba, ni wọn n fun emi ti mo jẹ Adele.
Awọn miran n kun pe owo yii ti pọ ju nitori pe owo naa pọ ju owo awọn to jẹ ọba gangan, ti wọn ko si nipo kinni.
Wọn wa n fi apa janu pe bawo ni Adele se maa gba owo ju wọn lọ.
Iru awọn nnkan bayi maa n fa rogbodiyan fun awọn to ba jẹ Adele ati awọn ọba miran.
Mo maa n bẹ ijọba ipinlẹ pe ki wọn wo se fun awa ti a jẹ adele, ki wọn se eto to dara fun wa bii owo ifẹyinti lẹyin ti a ba kuro nipo Adele.
“Eeyan to ba kuro nipo adele ko le pada si igbe aye to n gbe tẹlẹ mọ. Abi ẹni ti gbogbo aye ti n kunlẹ tabi dọbalẹ ki, yoo se tun pada wa maa lọ sisẹ ti a n se tẹlẹ.
Amọ ti a ba ni owo tuulu ni ipamọ, yoo rọrun lati da ibudo itaja tiwa silẹ eyi ti ko ni tabuku wa.’”






