Mọ nípa àwọn oúnjẹ aṣara lóore tó lè dènà ìgbẹ́ gbuuru fún ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/ HUMAIRA'S VARIETIES
Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo kaakiri agbaye, (MSF) fi atẹjade abọ iwadii wọn oṣu mẹfa akọkọ ninu ọdun 2024 síta.
Iwadii naa fihan pe afikun ti de ba iye awọn ọmọde ti o ni igbẹ gbuuru - eyi ti ai ni anfani si oúnjẹ to ṣe ara loore ṣe okunfa rẹ.
Iwadii naa sọ pe awọn ipinlẹ Borno, Bauchi, Zamfara, Kano, Kebbi ati Sokoto wa lara awọn ipinlẹ ti afikun ti de ba iye awọn ọmọde to n laiṣan igbẹ gbuuru lorilẹede Naijiria.
Ajọ MSF sọ pe oun nilo lati pe akiyesi gbogbo eniyan lati parapọ gbe ogun ti isoro yii.
Iru ounjẹ wo ni o le dena igbẹ gbuuru fawọn ọmọde?
Dokita Auwal Musa Umar to je ogbontarigi ninu Cimaka ati to ṣi tun olori awon dokita to n ri si ọrọ ounje jijẹ ti eka ipinle Kano salaye awọn ounje to ye ki a maa fun awon omode lati dena arun na.
O sọ pe ara awọn ọmọde nilo gbogbo iru awọn ounjẹ wọnyii, bii oúnjẹ alagbara ati awọn ounjẹ asearaloore, eyi ti o ṣe pataki pupọ lati ní idagbasoke ninu ara.
Lẹyin naa a ni iru ounjẹ to ni fitami to n gbe ogun ti aarun.
"O yẹ ki awọn ọmọ maa jẹ iru awọn oúnjẹ wọnyi lati ma le kan agbako ikọlu igbẹ gbuuru," Dokita naa lo sọ bẹẹ.
Omi ọyan iya

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ohun akọkọ to n peṣe aabo fun awọn ọmọde lati ni agbara ni omi ọyan iya ti wọn n mu loorekoore.
Awọn dokita gba awọn eeyan ni imọran pe o kere tan oṣu mẹfa ni wọn gbọdọ fi fun ọmọ ni ọmu kí wọn to fun ni ounjẹ miiran.
Idi abajọ ni pe wara ti iya n pese fun ọmọ ni ọpọlọpọ eronja to le daabo bo ọmọ lọwọ aarun igbẹ gbuuru, ebi ati awọn aarun to jọ mọ kí ebi maa pa eeyan.
Dokita naa tẹsiwaju pe awọn obi ni lati se itọju awọn ọmọ wọn pẹlu fi fun wọn ní omi ọmu, kí awọn naa si ma jẹ oúnjẹ to ṣe ara loore, bi jíjẹ ẹyin kan lojumọ, ẹja ati awọn nnkan to le se awọn ọmọde loore.
Ajọ WHO eleto ilera agbaye gba a ni imọran pe kí awọn iya maa fun awọn ọmọde ní ọmu fun ọdun meji tàbí ju bẹẹ lọ.
Ounjẹ asara loore

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni kete ti ọmọ ba ti bẹrẹ si jẹun, ohun ti o yẹ ki o fun ni ounjẹ to ṣe asaraloore, eyi ti yoo se anfaani nla fun idagbasoke rẹ.
Awọn Dokita ni iya ọmọ ni lati gbajumọ awọn ohun ti yoo se anfani fun awọn ọmọ rẹ.
Wọn ní ki iya pin oúnjẹ naa si meji ko si yan eyi to tọ fun awọn ọmọ rẹ
Awọn iru ounjẹ ti o wa ninu oúnjẹ to dara fun ọmọ ni ẹja, ewa, soya, ẹyin, wara, ati awọn ẹran rirọ ti ọmọde le jẹ laisi iṣoro.
Ẹfọ ati Eso

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ eleto ilera agbaye sọ pe ida aadọta oúnjẹ to yẹ kí awọn ọmọde maa jẹ ní ẹfọ ati eso.
Awọn ẹfọ ni awọn fitami, awọn ohun alumọni to ṣe ara loore.
Wọn wulo pupọ fun iranti ọmọde nigbati o dagba, bi dokita ṣe ṣalaye.
"Aisi ounje ti o ni awọn eroja ati fitamin maa jẹ ki ọmọ ni isoro iranti, ti ko si le ronu daradara."
O fi kun pe fifun ọmọde ni ounjẹ ti o ni awọn eroja wọnyi yoo ṣe iranlọwọ fun un lati kọ ẹkọ kika tabi ṣiṣẹ pẹlu agbara.
"Folic acid'' ṣe pataki fun igbesi aye ọmọde, nibi ti ko ba ti si eroja yii, o le fa awọn iṣoro miiran fun ọmọ naa."
Ounjẹ mii to n ṣe ara loore
Dokita Auwal sọ pe iwulo ounjẹ to n fun ni agbara pọ gan an.
Awọn iru ounjẹ ti o wa ninu ẹgbẹ yii ni agbado, iresi, pasita, alikama, akara, iṣu, ẹgẹ, jero, agbado, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iru ounjẹ yii n pese awọn eroja ti o ṣe iranlọwọ fun ọmọde lati dagba.
Dokita Auwal gba awọn obi ni imọran lati ri pe wọn n fun awọn ọmọ wọn ni apapọ oúnjẹ to ni eroja to ṣe ara loore
Dokita sọ ohun to ṣe pataki ju ni fifun awọn ọmọde ni oúnjẹ to ṣe ara wọn loore, to si se pataki pe awọn ọmọde yii jẹ apapọ oúnjẹ to ṣe ara wọn loore pupọ ninu abọ oúnjẹ wọn.
"Ti o ba irẹsi, fi ẹwa jẹ ẹ, fi awọn ewe ẹfọ kun oúnjẹ náà
"Eyi yoo se ọpọlọpọ anfani fun ago ara awọn ọmọde."















