Wo bí wọ́n ṣe máa ń sin òkú àwọn arìnrìnàjò Hajj tó bá kú sí Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Irin-ajo Hajj si ilu Mecca lorilẹede Saudi Arabia jẹ ọkan lara awọn nnkan to ṣe pataki ninu ẹsin musulumi.
Lilọ si Hajj jẹ ọkan lara opo marun un to di ẹsin Islam mu eleyii to yẹ ki ẹni to ba lagbara rẹ lọ, o kere lẹẹkan niwọn igba to wa laye.
Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ẹlẹsin Islam kaakiri agbaye lo maa n lọ si ilu Mecca fun eto Hajj lakoko yii.
Amọ, gbogbo awọn to ba lọ si irin-ajo yii kọ ni wọn maa n pada de.
Awọn mii a ti ku nibẹ yala nipasẹ aisan, ijamba tabi ki wọn tẹ elomiran mọlẹ pa.
Ẹwẹ, nibi eto Hajj ti ọdun 2024 yii to n lọ lọwọ, arinrin-ajo Hajj meji lati orilẹede Naijiria - Tawakalitu Busare Alako ati Muhammad Suleman tawọn mejeeji wa lati ipinlẹ Kebbi ni wọn ti ku ni ilu Mecca bayii gege bi ajọ NAHCON to n ri si ọrọ irin-ajo si ilẹ mimọ ni Mecca ṣe fidi rẹ múlẹ.
Ki lo maa ṣẹlẹ si oku arinrin-ajo Hajj to ba ku ni Mecca?
Kinni itumọ arinrin-ajo Hajj to ku si Mecca ninu ẹsin musulumi?
"Ore ọfẹ lo jẹ fun ẹni to ba ku si Mecca lasiko Hajj"
Lọpọ igba, awọn eeyan ilẹ Afirika maa n fẹ lati sin oku ẹbi wọn sile ki wọn le sun ni ibikan naa pẹlu awọn baba nla wọn to ti ku.
Amọ, onimọ nipa ẹsin musulumi, Umar Haruna, sọ pe oun ko tii ri ẹni to ku si Hajj ti wọn si gbe pada wale ri.
"Ore ọfẹ lo jẹ fun arinrinajo Hajj to ba ku si Mecca.
Otitọ ni pe awọn ẹbi iru ẹni bẹẹ le kọkọ banujẹ pe wọn o ni ri eeyan naa mọ, ṣugbọn inu wọn yoo tun dun lapa kan pẹlu igbagbọ pe ibukun lati ọdọ Allah ni ki eeyan ku lasiko Hajj ni Mecca," Haruna lo sọ bẹẹ.
Ilana ẹsin musulumi ni pe ki wọn sin oku eeyan to ba ku laarin wakati mẹrinlelogun ti ẹni naa ba papopa.
Onimọ nipa ẹsin musulumi naa sọ pe ko le ṣeeṣe lati gbe oku eeyan wale lati Saudi Arabia laarin wakati mẹrinlelogun tii ṣe ọjọ kan.
Idi niyi ti wọn maa n fi sin wọn si orilẹ-ede Saudi Arabia.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibo ni wọn maa n sin awọn arinrin-ajo Hajj to ba ku si Mecca si?
Onimọ nipa ẹsin Islam mii, Imam Nurudeen to ti lọ si Hajj ni ọpọ igba sọ pe oniruuru ibi isinku lo wa ni Saudi ti wọn maa n sin iru awọn eeyan bayii si.
Lasiko eto Hajj ọdun 2015, eeyan to le ni ẹgbẹrun meji lo ku ninu awọn arinrin-ajo Hajj lẹyin t'awọn oniṣẹ Hajj tẹ wọn pa.
Awọn alaṣẹ ni Saud lawọn ti pese aye silẹ ni ibi isinku mẹfa ọtọtọ lati sin wọn si.
Awọn ọmọ Naijiria naa wa lara awọn to ku yii lọdun 2015 to fi mọ Maurufudeen Adefolabi, ọmọ ile ìgbimọ aṣofin ipinlẹ Eko tẹlẹ ri.
Onimọ nipa ẹsin musulumi, Nurudeen ṣalaye pe eto isinku awọn to ba ku si Hajj ko yatọ si ilana isinku l'ọna ẹsin musulumi kaakiri gbogbo agbaye.
Ọgbẹni Nurudeen sọ pe "wọn a kọkọ wẹ oku naa, lẹyin naa ni wọn maa we e laṣọ funfun.
Leyin eleyii ni imaamu kan yoo ṣiwaju irun isinku ti a n pe ni Salat al-Janaza ni ibi isinku ki wọn to sin oku naa."















