Wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lásìkò ìwọ́de tó ń bọ̀ kí o má baà fara káásá

Oríṣun àwòrán, X/@_EL_AMEEN/via REUTERS
Yoruba bọ, wọn ni o n bọ, o n bọ, awọn la a dẹ ẹ de e; eyi gan an ni BBC Yoruba fi fẹ ki o mọ bi o ti le daabo bo ara rẹ lasiko ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ ti yoo bẹrẹ kaakiri orilẹede Naijiria ni Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ kinni oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Bi ọjọ ṣe n sun mọ ọjọ kinni oṣu kẹjọ ti ifẹhonuhan yoo waye ni Aarẹ Bola Tinubu ti n ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan.
Aarẹ lo awọn ipade yii lati le jẹ kawọn alẹnulọrọ yii le b'awọn to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan sọrọ ki wọn le wọgile iwọde ọhun.
Amọ, nibi ti ọrọ naa de duro bayii, o dabi ẹni pe iwọde naa yoo gberasọ l’Ọjọbọ lai ṣe ani ani.
Ti o ba gbagbe, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti padanu ẹmi wọn ninu awọn iwọde kan to ti waye sẹyin ni Naijiria.
Wọnyii ni awọn nnkan ti o le ṣe lati daabo bo ara rẹ lasiko ifẹhonuhan.
Mọ ohun to n lọ ni ayika rẹ
Lara ohun ti o gbọdọ ṣe ni pe ki o mọ ohun to n lọ ni ayika rẹ lasiko ti ifẹhonuhan n lọ lọwọ.
Gbiyanju lati mọ awọn ọna ti awọn oluwọde yoo gba lasiko iwọde, ki o si tun mọ ibi ti wọn ti maa ko ara wọn jọ fun iwọde.
Bakan naa, mọ ọna ti o le gba kuro nibi iwọde naa ai baa mọ ti rogbodiyan ba bẹ silẹ; ti ọrọ si di ẹni ori yọ o dile.
Feti silẹ si iroyin tawọn ileeṣẹ iroyin n gbe jade lori iwọde to n lọ lọwọ, ki o si maa wo ori itakun ayelujara lati mọ ohun to n lọ lori iwọde naa kaakiri orilẹede Naijiria.
Mọ ẹtọ rẹ
Ohun kan ti o tun dabi rẹ ni pe o gbọdọ mọ ẹtọ rẹ.
Mọ ohun ti ofin sọ nipa ẹtọ rẹ lori ṣiṣe ifẹhonuhan.
Mọ ohun ti o le ṣe ati ohun ti o o le ṣe labẹ ofin lasiko iwọde.
Ri i daju pe o mọ nnkan ti o le ṣe to le jẹ ki o dero ahamọ ọlọpaa.
Daabo bo ara rẹ t’ọlọpaa ba yin taju taju
O le lo aṣọ ṣikaafu lati bo ẹnu ati imu rẹ tawọn ọlọpaa ba yin taju taju nibi iwọde.
Bakan naa, mu awo dani ti o le wọ ki taju taju ma baa ṣakoba fun oju rẹ.
Jinna si ibi tawọn eeayn ba ti n ba ara wọn ja lasiko iwọde.
Ma bẹru

Ti iwọde ba ti bẹrẹ, ri wi pe o duro gidigba lai bẹru.
Ti o ba ti ṣe akiyesi pe nnkan ti fẹ maa daru, o le ba ẹsẹ rẹ sọrọ ki o kuro nibẹ.
Tẹti si ohun tawọn adari ifẹhonuhan n sọ, ki o si tẹle ilana wọn pẹlu.
O ṣeeṣe ki wọn ti ba ijọba sọrọ lati pese eto aabo to peye fun wọn lasiko iwọde.
Ma jẹ kawọn eeyan mọ iru ẹni ti o jẹ
Ohun to tun da bii rẹ ni pe ma jẹ kawọn eeyan mọ iru eeyan ti o jẹ nibi ifẹhonuhan.
Ri i wi pe kii ṣe tabi ika rẹ ni o fi n ṣi foonu rẹ lasiko iwọde.
Ma ṣe sọ ohun kohun nipa rẹ fun ẹnikẹni nibi iwọde papaa julọ awọn eeyan ti o ko mọ.
Mura silẹ daadaa fun iwọde to n bọ

O ni lati wa ni imurasilẹ fun ifẹhonuhan nipa irufẹ aṣọ ti wa a wọ lọ sibẹ.
Wọ aṣọ to maa duro lara rẹ daadaa ti ko ni ṣe idiwọ fun ọ lati rin daadaa tabi sare.
Bakan naa, wọ bata gidi ti o le fi sare ti ọrọ ba bẹyin yọ nibi ifẹhonuhan.
Ma mu nnkan tawọn eeyan le jagba lọwọ rẹ lasiko iwọde dani.
Koda, o le mu aṣọ mii lọwọ ti o le wọ kawọn ma le da ọ mọ gan an.
Gbe omi dani, mu ipapanu ti o le sare jẹ ti ebi ba n pa ọ dani bakan naa.
Mo wo dani pẹlu, ki o si ri pe batiri foonu rẹ kun daadaa ki o ma ba ku.
Wa lojufo
Wo lojufo nibi iwọde tori ti nnkan ba dari.
Mọ ọna ti o le gba kuro nibi iwọde lati ibẹrẹ ifọhonuhan.
Ma da wa nibi kibi lasiko iwọde, ri wi pe o wa pẹlu awọn eeyan nigba gbogbo.
Ri i wi pe o wa pẹlu awọn ti ọrọ ara yin ba ye ara yin.
Mu ilera rẹ ni ọkun-kundun
Mu omi daadaa ki o ri pe oungbẹ ko gbẹ ọ lasiko iwọde.
Ri daju wi pe o mu ounjẹ to maa to ọ jẹ dani lo sibi ifẹhonuhan.
Ma ṣe ju ara rẹ lọ nibi iwọde.
Beere fun iranwọ ti o ba ti ri pe ara rẹ n ṣe bakan bakan.
Ti ilera rẹ ko ba gbe e mọ, tete ba ẹsẹ rẹ sọrọ ki o fi ibi iwọde silẹ.















