Wo àwọn ìfẹ̀hónúhàn tó mi ilẹ̀ tìtì tó ti wáyé sẹ́yìn ní Nàìjíríà àti ohun tó gbẹ̀yìn wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n sọ nipa ifọhonuhan ‘ebi n pa wa’ lori itakun ayelujara, eleyii ti awọn alakoṣo iwọde naa n gbero lati ṣe ni gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria ati niluu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.
Awọn araalu ti n pariwo lori bi ounjẹ atawọn nnkan mii ṣe gbowo lori ti ara si n ni ọpọ ọmọ Naijiria.
Iwọde ọhun ni wọn tun sọ pe awọn fẹ ṣe lati fopin si ṣiṣe ijọba ti ko jẹ ki ara rọ araalu:
Bi ọjọ ṣe n sun mọ diẹ diẹ si ọjọ kinni oṣu kẹjọ ti wọn n gbero láti ṣe ifẹhonuhan ọhun ni Aarẹ Bola Tinubu n ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan.
Aarẹ ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC, awọn ọba alaye, at'awọn olori ẹsin.
Tinubu lo awọn ipade yii lati sọ fawọn gomina, ọba alaye atawọn olori ẹsin wi pe ki wọn b'awọn to n gbero lati ṣe ifẹhonuhan sọrọ ki wọn le wọgile iwọde ọhun.
Aarẹ fun ra rẹ naa ti n rọ awọn to fẹ ṣe ifẹhonuhan naa wi pe ki wọn semẹdọ, ki wọn si fun ijọba oun laye diẹ si lati ṣe daadaa fun araalu.
Kii ṣe igba akọkọ niyi tawọn eeyan yoo gbero lati ṣe ifẹhonuhan ni Naijiria.
Koda, ọpọ amofin lo ti fidi rẹ mulẹ pe ṣiṣe iwọde tọna labẹ ofin orilẹede Naijiria.
Wọnyii ni awọn iwọde to milẹ titi to ti waye lorilẹede Naijiria ati abayọri wọn.
Iwọde EndSARS ọdun 2020

Iwọde Endsars bẹrẹ ni oṣu kẹwaa ọdun 2020 sugbọn ogunjọ oṣu kẹwaa naa ni rogbodiyan bẹ silẹ.
Ohun ti awọn ọdọ oluwọde naa n pariwo soke lasiko naa ni pe awọn ọlọpaa n huwa ipa, wọn si n fi iya jẹ awọn ọdọ eyi to tako ofin Naijiria, ti ọpọ ọdọ si ti padanu ẹmi wọn nitori iwa yii.
Ọpọ awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni iwọde ti waye, ti awọn ọdọ si korawọnjọ lati fẹhonuhan lori bi Ileeṣẹ ọlọpaa se n dunkoko mọ wọn.
Ohun to ṣokunfa iwọde yii gan an ni iṣẹlẹ kan to lamilaka to waye ni ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwaa.
Kii ṣe ni Eko lo ti waye ṣugbọn awọn to wa niluu Eko naa mọ riri rẹ lara ohun naa si ni ṣe pẹlu ọrọ EndSARS.
Ijọba ipinlẹ Edo kede konileogbele oniwakati mẹrinlelogun nitori ikọlu tawọn janduku ṣe si ọgba Ẹwọn Benin ati Oko.
Ninu ikọlu yi, ni ṣe ni awọn janduku to sa sabẹ iwọde ENDSARS N dunkoko mọ ara ilu ti wọn si n jale kaakiri ilu.
Pẹlu bi nkan ti ṣe ri yi, ọpọ lo ti n ro pe o ṣeeṣe ki iru rẹ naa waye ni Eko.Ọrọ pada ri bẹẹ.
Ogunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2020 jẹ ọjọ manigbagbe ninu itan orileede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọjọ yi ni ikọlu waye laarin awọn ọmọ ogun Naijiria ati awọn oluwọde ENDSARS ni agbegbe Lekki Toll Gate ni ilu Eko.
Lati ago mọkanla kọja ti ijọba fi ikede yi sita pe konile o gbele, awọn oluwọde to wa ni Lekki ni ko si giri pe ile lapoti awọn yoo joko de idi awn ti ijba ba ran wa.
Ago mẹrin lu awọn oluwọde ko kuro ni Lekki bẹẹ si ni awọn agbofinro ko ti de.Ohun to waye lyin igba naa ree:
Nigba ti yoo fi di ago marun abọ irọlẹ awọn eeyan kan wa yọ kamẹra CCTV to wa lara patako ipolowo ọja to wa lẹgbẹ Toll Gate naa.
Ni nkan bi ago mẹfa ni wọn pa gbogbo ina to wa lagbegbe Toll Gate ti okunkun birimu si bo gbogbo ibẹ
Ni nkan bi ago mẹfa abọ irọle ku diẹ lawọn ikọ ọmọ ogun gbera kuro ni ibudo ologun to wa ni Bonny Camp lati lọ si Lekki Toll Gate.
6:43pm si 6:45pm akọroyin wa towa nikalẹ sọ pe wọn bẹrẹ si sunmọ ibi ti awọn oluwọde wa ti wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn.
Nkan bi wakati kan abọ si meji ni wọn fi n yinbọn yii.
Ibi ibọn yinyin yi ni ariyanjiyan ti waye.
Awọn ọmọogun sọ pe awọn ko yin ọta ibọn gidi ṣugbọn awọn oluwọde ni ọrọ ko ri bẹ.
Ninu iwadii kan ti BBC ṣe lyin iṣẹlẹ yi, awon oṣojumi koro ti ko f fojuhan ni awọn eeyan ba iṣẹlẹ naa lọ.
Lọjọ Keji iṣlẹ yi, Gomina Sanwoolu tọrọ aforijin lọwọ awọn araalu to si s pe eeyan kan ku ti awọn meji mii si farapa.
Igbesẹ yii lo jẹ ki Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijria wọgile ohun to n jẹ ọlọpaa SARS lorilẹede Naijiria lati le pẹtu si awọn ọdọ lọkan.
Iwọde 'Occupy Nigeria' ọdun 2012 lati tako ayọkuro 'subsidy' epo

Oríṣun àwòrán, AP
Lara iwọde to milẹ titi lorilẹede Naijiria ni ifẹhonuhan ‘Occupy Nigeria’ ti ọdun 2012 tawọn araalu ṣe tako ayọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiroolu(subsidy) labẹ ijọba aarẹ ana, Goodluk Jonthan wa.
Ni ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2012 ni ijọba Jonathan kede ayọkuro owo iranwọ ori epo ọhun, eyi to mi kawọn eeyan tutọ soke foju gba a ti wọn si bẹrẹ ifẹhonuhan kaakiri orilẹede Naijiria.
Ifẹhonuhan waye lawọn ilu bii Kano, Abuja, Minna ati ilu Eko to fi mọ ilu London loke okun gan an.
Ọpọ eeyan ni wọn lo oriṣiiriṣii oju opo ayelujara bii Facebook ati Twitter(to n jẹ X bayii) lati sọ ero wọn tako ayọkuro owo iranwọ ori epo bẹntiroolu.
Awọn oluwọde gbe ọpọ ile epo tipa, ti wọn si tun di ọpọ opopona gẹgẹ bi ọna lati fi ẹhonu wọn han.
Agbegbe Ojota niluu Eko jẹ ibi kan pataki tawọn oluwọde lo fun ifẹhonuhan wọn nibi ti wọn ti n pade lojoojumọ.
Ni ṣe lero yoo pejọ biba ni Ojota lojoojumọ titi ti iwọde ọhun naa kasẹ nilẹ.
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria naa kede wi pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi lati ọjọ Aje ọjọ kẹsan an oṣu Kinni ọdun 2012 ti ijọba ba kọ lati da owo iranwọ ori epo ti wọn yọ pada.
Iroyin sọ pe ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Muyideen Mustapha ba iwọde ọhun lọ, wi pe awọn ọlọpaa lo yinbọn fun niluu Ilorin lasiko ti ifẹhonuhan n lọ lọwọ lọjọ kẹta oṣu Kinni.
Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn oludwọde mii lo gun lọbẹ pa nibi ti wọn ti n ṣewọde.
Iroyin tun fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan lawọn ọlọpaa ṣekupa lasiko ifẹhonuhan naa.
Lẹyin o rẹyin, Aarẹ Jonathan pada da owo iranwọ ori epo bẹntiroolu ti o yọ pada lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ nibi ifẹhonuhan araalu tako ayọkuro ‘subsidy’ ori epo.
Iwọde June 12

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu awọn ifẹhonuhan to lamilaaka to ti waye ni Naijiria, ọkan ni iwọde ‘June 12’ jẹ.
Ifẹhonuhan June 12 waye lẹyin latari bi olori ologun orilẹede Naijiria nigba naa, Ọgagun Ibrahim Babangida wọgile le esi idibo aarẹ to waye lọjọ kejila oṣu Kẹfa ọdun 1993.
Igbagbọ ọpọ ọmọ Naijiria ati ọpọ eeyan lagbaaye ni pe oludije ẹgbẹ oṣelu SDP, M.K.O. Abiola lo la oludije ẹgbẹ oṣelu NRC, Bashir Tofa mọlẹ ti o si jawe olubori ninu eto idibo naa.
Ajọ NEC to n ṣakoso eto idibo ni Naijiria nigba naa ko kede Abiola gẹgẹ bi ẹni to bori ninu ibo aarẹ Naijiria ọdun 1993.
Bi Babangida ṣe wọgile esi ibo yii ti ọpọ sọ pe ohun li ti lọ wọọrọwọ julọ ninu itan edibo Naijiria, lo jẹ ki ifẹhonuhan bẹrẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Babangida ni awọn kudiẹ kudiẹ wa ninu eto idibo naa lo jẹ ki oun wọgile esi rẹ.
Rogbodiyan to bẹ silẹ lo jẹ ki Babangida fi ipo rẹ silẹ ti o si yan Ernest Shonekan gẹgẹ bi aarẹ fidihẹẹ.
Lẹyin o rẹyin ni Ọgagun agba Sani Abacha doju ijọba fidihẹ Shokan bolẹ ti o di olori ologun ijọba orilẹede Naijiria.
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe o le ni ọgọrun eeyan tawọn ẹṣọ eleto abo ṣekupa ninu rogbodiyan to bẹ silẹ lasiko iwọde June 12 kaakiri orilẹede Naijiria.
Ọpọ awọn eeyan to ku yii ni a gbọ wi pe ilu Eko ni wọn ti padanu ẹmi wọn lasiko iwọde naa.
Ọpọ awọn ẹya Igbo to n ṣiṣẹ nipinlẹ Eko lo pada si ipinlẹ wọn nilẹ Igbo nitori rogbodiyan June 12.
Oniruuru orilẹede ilẹ okeere bi UK, Emẹrika, ajọ EU to fi mọ ajọ Commonwealth lo bu ẹnu atẹ lu bi Babangida ṣe wọgile esi idibo naa.
Ijọba ologun Babangida nigba gbe awọn ileeṣẹ iroyin kan tipa, ti wọn si tun ju awọn akọroyin kan si ahamọ.
Koda, ijọba ologun to ṣofin pe ile ẹjọ kankan ko gbọdọ gbọ ẹjọ lori igbesẹ Ọgagun Babangida lati wọgile esi ibo June 12.
Lẹyin o rẹyin, ijọba ologun mu Abiola, wọn si ju si ahamọ lori ẹsun pe o fẹ ditẹ gba ijọba.
Abacha pada ku lojiji lọjọ kẹjọ oṣu Kẹfa ọdun 1998, nigba ti Abiola ku lọjọ keje oṣu Keje ọdun 1998 kan naa.
Ọgagun Abdulsalami Abubakar lo gori oye gẹgẹ bi olori ologun ijọba orilẹede Naijiria lẹyin iku Abacha.
Abdulsalami lo ṣi ṣe eto igbejọba fun alagbada ti Oloye Olusegun Obasanjo to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fi la oludije ẹgbẹ oṣelu AD ati APP, Oloye Olu Falae mọlẹ ti o ṣi wọle ibo aarẹ naa.















