‘Mo fẹ́ dákú nígbà tí mo gbọ́ pé mo ní àìsàn jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ ‘Hepatitis’'
Arun jẹdọjẹdọ, Hepatitis jẹ aisan kan ti ọpọ ko fi iye si pupọ ṣugbọn to n ṣe ọpọ ọṣẹ laarin awujọ eniyan.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ ilera agbaye, WHO fi sita, inu ẹdọ ni kokoro aisan yii maa n dojukọ eyi to si le ti ipasẹ bẹẹ fa awọn ipenija ilera loniranran, omiran si maa n ja si iku.
Ọtalelọọdunrun o din mẹfa miliọnu eeyan lagbaye laisan yi n ba finra.
Ni Afirika, o le ni aadọrin miliọnu eeyan ti aisan yii n ba finra.
Ọpọlọpọ awọn to ba ni isan yii ni kii fẹ jade lati sọrọ sita lati kede pe oun ni aisan naa.
Sugbọn fun Joshua Adeola ko si idi lati fi pamọ nitori gẹgẹ bi o ṣe sọ, igba ti oun fẹ lọ fun eto agunbanirọ loun rii pe aisan naa wa lagọ ara oun.

"Asiko ti mo fẹ lọ se agunbanirọ, ni mo ṣe ayẹwo, ti wọn si ni mo ni aisan Hepatitis, mo fara ya gidi gan an ni, koda, mo fẹ ẹ daku"
Ọgbẹni Adeọla ni sisọrọ sita ṣe pataki fun awọn to ba ni aisan yii ati riri awọn iranwọ to ba yẹ latọdọ awọn to ni imọ nipa rẹ.
Gẹgẹ bi Adeọla, Orimọloye Oluwaseun pẹlu ni asiko ti oun fẹ lọ fun agunbanirọ, ti oun si lọ ṣe ayẹwo loun ri i pe oun ni aisan naa.
“Bi mo ṣe gbọ bayii, mo fara ya gidi gan an ni.
Koda. mo fẹ ẹ daku lọjọ naa.”
Oluwaṣeun Orimọloye ni lara ohun ti oun n beere lọwọ ara oun ni ibi ti oun fẹ ti bẹrẹ.
O ni aisan naa da ajọṣepọ oun ati ololufẹ oun ru nitori pe, ko ri ara gba iroyin aisan naa.
Koda, o ni ololufẹ oun kọ pe oun ni ika nitori pe ni iwoye rẹ, oun mọọmọ ṣe e ni.

Bawo ni ayẹwo yii ṣe maa n waye?
Yussuf Hassana Taiwo to jẹ igbakeji adari ẹka ayẹwo ni ile iwosan apapọ FMC nilu Akurẹ ṣalaye pe ayẹwo itọ ni o maa n ṣe atọna lati mọ boya eeyan ni aisan yii.
Irufẹ aisan jẹdọjẹdọ marun un lo wa gẹgẹ bi ọrọ ti oniṣegun oyinbo, Aragbaye Abimbọla ṣe lalaye fun BBC.
Dokita Aragbaye ni Hepatitis A, B, C. D. E lo wa ati pe, Hepatitis B nikan lo ṣe e dena pẹlu abẹrẹ ajẹsara.
Bakan naa lo ṣalaye pe ko si eyikeyi ninu awọn aisan jẹdọjẹdọ yii to jẹ ajogunba, bi o tilẹ jẹ wi pe ọmọ inu oyun le ko o latara iya rẹ lasiko to ba wa ninu oyun rẹ.

Ki lọna abayọ si aisan Hepatitis?
Dokita Aragbaye Abimbọla ni ohun to ṣe pataki ni pe ki ẹnikẹni to ba ni aisan yii ko sare tete gba ile iwosan lọ.
O ni o le pẹ ju ti onitọun ko ba tete gba itọju loju ẹsẹ nitori o le mu ẹmi lọ.






