Aráàlú ké gbàjarè bí ilé ẹ̀kọ́ kan l‘Ondo ṣe di ẹ̀bìtì àlàpà, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì ń kàwé lábẹ́ igi torí ògiri yàrá ìkàwé tó dà wó lulẹ̀

Àkọlé fídíò, Ile ẹkọ ni Ado Ugbo
Aráàlú ké gbàjarè bí ilé ẹ̀kọ́ kan l‘Ondo ṣe di ẹ̀bìtì àlàpà, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ sì ń kàwé lábẹ́ igi torí ògiri yàrá ìkàwé tó dà wó lulẹ̀

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ girama Ado Ugbo, to wa niluu Afin Akoko, nipinlẹ Ondo, ti ke gbajare si ijọba atawọn araalu fun iranlọwọ nitori bi ile ẹkọ naa ṣe di ẹgẹrẹmiti.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, alaṣẹ ile ẹkọ naa, Azeez Surajudeen Bamidele ati Oluawa ilẹ Irawa Ilale nilu Akungba -Akoko, Omorinkanoba Benson, sọ pe pupọ ninu awọn ile to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa lo ti dawo.

Ọgbẹni Bamidele sọ pe lati kekere ni oun ti mọ ile ẹkọ naa, ko to di pe oun funra oun di alaṣẹ ile ẹkọ naa.

O ni ile ẹkọ ọhun gbajumọ lọpọ ọdun sẹyin amọ o ti sọ ogo rẹ nu bayii latari bo ṣe ri lonii.

Apa kan ile ẹkọ to da wo

Gẹgẹ bi Bamidele ṣe sọ, ijọba gbiyanju gidi fun idagbasoke ile ẹkọ naa amọ awọn araalu ko ran ijọba lọwọ to bo ṣe yẹ.

O ni to ba jẹ pe awọn araalu n kin ijọba lẹyin ninu akitiyan rẹ, gbogbo igbiyanju ijọba yoo yọ.

Apa kan ile ẹkọ to da wo

"Abẹ igi lawọn akẹkọọ ti n kawe, koda, gbọngan ti wọn ti n se idanwo WAEC ati NECO gan ti da wo lulẹ"

Akọroyin BBC News Yoruba to lọ sile ẹkọ naa jabọ pe, abẹ igi nla kan ni pupọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti n kawe latari bi ogiri ọpọ awọn kilaasi to wa nibẹ ṣe dawo.

Koda, gbọngan nla ti wọn ti n ṣe idanwo bii WAEC ati NECO tẹlẹ ti dawo.

Oluawa ilẹ Irawa Ilale ni Akungba -Akoko, Omorinkanoba Benson naa ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ nipa ipo to buru jai ti ile ẹkọ naa wa.

"Laye atijọ, nigba ti a wa nibi, ile iwe naa dara, amọ awọn yara ile ẹkọ to wa nibi laye atijọ yẹn, o ti wo.

Atẹgun ti gbe ọpọlọpọ orule lọ, ti ko si si ireti pe a le tun ṣe mọ. Ki lo dẹ fa a ni pe bi orilẹede yii ṣe ri."

Benson sọ pe ijọba n gbinyanju, bẹẹ ni awọn alẹnulọrọ kan laarin ilu gbiyanju lati ran ile ẹkọ naa lọwọ amọ inu awọn ko dun si bi ile ẹkọ ọhun ṣe ri lọwọ yii.

Awọn mejeji pari ọrọ wọn pẹlu arọwa si ijọba pe ko ran awọn lọwọ lati tun ile ẹkọ ọhun ṣe, ti igbesẹ bawọn akẹkọọ ṣe n kawe labẹ yoo si di ohun itan.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti awọn mejeji sọ pẹlu BBC News Yoruba.

Orukọ ile ẹkọ to da wo