Ọ̀rẹ́kùnrin pa olólùfẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Fásítì l'Ondo, ariwo sọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Olorunsaanu Godspowers

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Rogbodiyan nla sẹlẹ n'ilu Akungba Akoko nipinlẹ Ondo bi ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin to wa ni Akungba Akoko ṣe yabo gbogbo opopona ilu naa lati bere fun idajọ ododo lori iku Akẹkọọ fasiti ti ololufẹ rẹ gun pa.

Joy Adeyemi to jẹ Akẹkọọ ipele asekagba ni eka imọ Human Kinetics ni o di awati ni ọjọ Isegun ti o kọja ki wọn to ri oku rẹ ni yara ololufẹ rẹ to jẹ ọmọ bibi ilu Akungba Akoko.

Ololufẹ oloogbe naa ti ki n se Akẹkọọ fasiti naa ti na papa bora ti awọn esọ alaabo si ti n wa bayi.

Iṣẹlẹ yi waye lẹyin ọsẹ meji ti baba onile kan n'ilu naa sagbateru bi wọn ṣe pa Akẹkọọ meji ni fasiti naa.

Eyi lo mu ki awọn Akẹkọọ fasiti Adekunle Ajasin Akungba Akoko pe fun idajọ ododo lori iṣẹlẹ yi.

Kì ni ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni fásitì Adekunle Ajasin sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?

Aarẹ ẹgbẹ awọn Akẹkọọ fasiti náà, Salami Akeem, lasiko to n ba BBC News Yoruba salaye pe iku Joy Adeyemi jẹ iyalẹnu nla nitori pe wọn si n wa ọna lati fopin si iṣẹlẹ isekupani latọwọ awọn ọmọ onilu lẹyin iṣẹlẹ to waye nibi ọsẹ meji sẹyin, ni wọn gbọ nipa iṣẹlẹ yii.

Lasiko to n salaye bi iṣẹlẹ naa se waye Salami Akeem sọ di mimọ pe ololufẹ Joy Adeyemi to jẹ ọmọ bibi Akungba Akoko lo gun akẹkọọ naa pa sinu yara rẹ, to si fi oku rẹ silẹ si yara naa fun ọjọ mẹta gbako.

O salaye pe awọn olugbe agbegbe naa lo kesi wọn latari oorun to n jade lati yara naa, ti wọn si ri oku akẹẹkọ naa ninu yara rẹ, ti ara Akẹkọọ naa si ti n kẹ.

Aarẹ awọn akẹkọọ naa sọ pe ni kete ti wọn ri oku akẹkọọ naa wọn ni igbiyanju lati sawari ẹni to sọsẹ naa bẹrẹ sugbọn o ti fẹsẹ fẹ, ti wọn si fa iya rẹ le awọn agbofinro lọwọ.

Awọn Akẹkọọ naa wa fun ijọba Ipinlẹ Ondo ati awon agbofinro ni wakati merinlelogun lati sawari ẹni to sekupa Akẹkọọ naa.

Bẹẹni wọn rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati wa ojutu si bi awọn ọmọ bibi ilu Akungba ṣe n seku pa awọn Akẹkọọ fasiti ilu naa.

Aworan iwode tako iṣekupani

Oríṣun àwòrán, Premiumtimesng

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ipaniyan naa

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Alayande Olushola salaye pe wọn ti fi panpe ọba mu awọn mẹta ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Alayande Olushola lasiko to n ba BBC YORUBA sọrọ salaye pe awọn mẹta yi seranwọ fun afunrasi naa lati se isẹ ibi naa, ti wọn si tun ran lọwọ lati na papa bora.

Alukoro naa sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa pẹlu ileri pe ọwọ awọn ikọ ajọ naa yoo tẹ afunrasi naa laipẹ.

O wa rọ awọn Akẹkọọ naa lati se ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ofin, to si tun seleri pe ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo yoo ri daju iṣẹlẹ Ipaniyan yoo dohun igbagbe ni ilu Akungba ati fasiti.