Kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá Super Falcons sọ lẹ́yìn tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ WAFCON fún ìgbà kẹwàá

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Aarẹ Bola Tinubu ti gboṣuba rabandẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons Naijiria lẹyin ti wọn la Morocco mọlẹ lati gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa lalẹ ana ọjọ Abamẹta niluu Rabat.
Ẹkọ ko kọkọ ṣoju mimu fun Naijiria nigba ti ere bọọlu naa bẹrẹ tori goolu meji ọtọọtọ ni Morocco kọkọ gba wọle Super Falcons ti wọn o si le ta putu ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Amọ, nigba ti abala keji ere bọọlu naa bẹrẹ ni Super Falcons bẹrẹ si ni ṣana ti Esther Okoronwo si da goolu kan pada lẹyin to gba pẹnariti ti Naijiria ri sawọn Morocco.
Kẹrẹ kẹrẹ ni wọn ba tun ri goolu keji gba wọle eyi to jẹ ki ami ayo di ọmi 2-2.
Jennifer Echegini to wọle ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lo kan Morocco ni eyin ọọkan nigba to gba goolu kẹta wọle fun Naijiria nigba ti o ku iṣẹju meji ki ere bọọlu naa pari.
Nigba ti o n bawọn sọrọ lori foonu, Aarẹ Tinubu ni ''Super Falcons mọ pe awọn ni iṣẹ la ti ṣe, iṣẹ naa si ye wọn yeke yeke.
Super Falcons ti wa jẹwọ ara wọn gẹgẹ bii ọmọ Naijiria tootọ ti kii kaarẹ.
Super Falcons lọ soju ogun, wọn si tun ti ṣẹgun.
Wọn ti gba ife ẹyẹ WAFCON gẹgẹ bii aṣaaju ninu bọọlu awọn obinrin nilẹ Afirika.
Ni bayii, ala #MissionX ti wa si imuṣẹ!''
Tinubu gboriyin fun Okoronkwo ati Ajibade
Aarẹ Tinubu sọ pe iwuri nla ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons jẹ fun orilẹede Naijiria ati gbogbo ọmọ Naijiria nibi kibi to wu ki wọn le wa.
Aarẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ti mu inu awọn ọmọ Naijiria dun, tori wọn jẹwọ ara wọn gẹgẹ bii ọmọ akin.
O ni aṣeyọri Super Falcons ninu idije WAFCON dara fun iṣọkan orilẹede Naijiria.
Tinubu ko ṣai ki Esther Okoronkwo to ṣe itaniji fun Super Falcons ninu ifẹsẹwọnsẹ naa fun iṣẹ takun takun ti o ṣe.
Bakan naa ni aarẹ tun gboriyin fun Rasheedat Ajibade to jẹ Balogun ìkọ agbabọọlu Naijiria fun ipa ribiribi ti o ko ninu idije naa.
Tinubu ni oun yoo maa reti wọn lati gbe ife ẹyẹ naa wa sile, amọ, o ni ki wọn ṣe pẹlẹ ki o to digba naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Super Falcons tun ti fi han pe awọn ni ọbabinrin ere bọọlu ni Afirika''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, aya aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnẹtọ Oluremi Tinubu, naa ti gboriyin fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons fun ife ẹyẹ WAFCON ti wọn gba fun igba kẹwaa.
Aya aarẹ ni eyi ṣee ṣe fawọn agbabọọlu obinrin Naijiria tori wọn o kaarẹ ninu igbiyanju wọn.
''Mo mọ riri ẹyin agbabọọlu obinrin wa fun bi ẹ ti gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa.
Ẹ gbiyanju bi ẹ ṣe lu Morocco ni 3-2 lẹyin ti Morocco ti kọkọ gba goolu meji sawọn Naijiria.
Eyi kii ṣe ife ẹyẹ mii lasan, amọ, o ni ṣe pẹlu iṣẹ aṣekara ati ẹmi ti kii kaarẹ tawọn ọmọ Naijiria ni.
A dupẹ lọwọ Eleduwa fun aṣeyọri nla yii, ẹ ti ṣe nnkan moriwu fun orilẹede wa lẹẹkan si.
Ẹ si tun ti jẹ ko ye gbogbo agbaye wi pe ẹyin ni ọbabinrin ere bọọlu nilẹ Afirika,'' Oluremi lo sọ bẹẹ.
Aya aarẹ wa ki Super Falcons ku oriire lorukọ gbogbo awọn obinrin ni Naijiria.
Sẹnẹtọ Oluremi ni Super Falcons ti fi goolu kọ orukọ wọn; ati pe wọn ti ṣe nnkan iwuri fun ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria.















