Ǹjẹ́ àwọn èèyàn nílò láti mú àdínkù bá ìrẹsì tí wọ́n ń jẹ?

Àwọn obìnrin Hindu tí wọ́n ń jẹ ìrẹsì nínú ilé kan ní Dhaka

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìrẹsì ni oúnjẹ táwọn èèyàn bílíọ̀nù mẹ́rin ń jẹ káàkiri àgbáyé. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń jẹ ẹ́ nílé àti ibi ayẹyẹ
    • Author, By The Food Chain Programme
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìrẹsì kìí ṣe oúnjẹ lásán. Òhun ni oúnjẹ tó jẹ́ pé ó lé ní ìdajì àpapọ̀ gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní àgbáyé ló ń jẹ ẹ́. Ó jẹ́ oúnjẹ àṣà, ìṣe àti bíbọ́ lọ́wọ́ ebi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.

"Fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Philippines, ìrẹsì ni oúnjẹ wọn. Ó kọjá oúnjẹ fún wọn, ó ti dàbí àṣà wọn," èyí ni ọ̀rọ̀ tí Adriene Bianca Villanueva, tó máa gbọ́ ètò BBC Worls Service láti Manila tó jẹ́ olú ìlú Philippines ṣe sọ.

"Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Philippines ló máa ń jẹ ìrẹsì ní ẹ̀ẹmẹ̀ta lójúmọ́ – oúnjẹ àárọ̀, ọ̀sán tàbí alẹ́. Kódà àwọn míì máa ń fi ṣe ìpanu. Èyí tí mo fẹ́ràn jùlọ ni ìrẹsì tó máa ń dìpọ̀ nítorí ọ̀pọ̀ ìpanu Philippines ni wọ́n máa ń fi sí," ó sọ.

Àmọ́ bí àyípadà ojú ọjọ́ ṣe ń wáyé lójoojúmọ́ ìbéèrè tó gba ẹnu ni pé ṣe a gbọ́dọ̀ mú àdínkù bá bí a ṣe ń jẹ ìrẹsì?

Oúnjẹ àgbáyé

Abọ́ oúnjẹ Ikan Gurame Kota

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìrẹsì rọrùn láti sè, gbé pamọ́ àti gbígbe kiri

Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ àti àwọn ohun ọ̀gbìn ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta àwọn ohun ọ̀gbìn tó wà láyé àmọ́ mẹ́ẹ̀dógún nìkan ló kó ìdá àádọ́rùn-ún (90%) oúnjẹ táwọn èèyàn ń jẹ jùlọ. Ìrẹsì, wíìtì àti àgbàdo ló lékè nínú wọn.

Ìdá àádọ́ta sí mẹ́rìndínlọ́gọ́ta àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ló jẹ́ pé ìrẹsì ni wọ́n gbáralé gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ gẹ́gẹ́ bí Dókítà Ivan Pinto, adarí àjọ tó ń rí sí ìwádìí ìrẹsì káàkiri àgbáyé ìyẹn International Rice Research Institute, IRRI ṣe sọ. Èyí túmọ̀ sí pé bílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn ló ń jẹ ìrẹsì ní ojoojúmọ́.

Wọ́n máa ń gbin ìrẹsì lọ́pọ̀ yanturu káàkiri gúúsù àti ìlà oòrùn gúúsù ẹkùn Asia. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìbéèrè mímú àlékún bá iye ìrẹsì tí wọ́n ń gbì ní ẹkùn Africa, Europe àti Latin Amẹ́ríkà.

Àmọ́ bí ìrẹsì ṣe gba oúnjẹ táwọn èèyàn ń jẹ jùlọ ní ayé ni ipa rẹ̀.

Èso tó nílò omi

Àwọn àgbẹ̀ ní oko ìrẹsì ní paddy field ní Lambaro, Indonesia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

"Ìrẹsì jẹ́ ohun ọ̀gbìn tó máa ń gba omi gidi," Jean-Philippe Laborde adarí àkóso iléeṣẹ́ Tilda, iléeṣẹ́ tó ń pèsè ìrẹsì tó wà ní UK sàlàyé.

"O máa ń gbà tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta sí márùn-ún lítà omi fún kílógíráàmù ìrẹsì kan tí wọ́n bá gbìn, èyí tó jẹ́ ohun tó pọ̀."

Ilẹ̀ omi ni wọ́n sábà máa ń gbi ìrẹsì sí pàápàá ní gúúsù àti ìlà oòrùn gúúsù Asia. Èyí máa ń ṣe ìrànwọ́ fún gbíngbin ìrẹsì àmọ́ ń máa ń pèsè àyíká tí kò ní èémí tó pọ̀ tó táwọn olóyìnbó ń pè ní "anaerobic condition".

"Nígbà tí ẹ̀kún omi bá wà… àwọn kòkòrò àìfojúrí tó máa ń pèsè methane máa ń pọ̀ si," Dókítà Ivan Pinto sọ.

Methane jẹ́ gáàsì tó kó ipa ìdá ọgbọ̀n (30%) lára àwọn ohun tó ń fa àyípadà ojú ọjọ́ gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí àwọn ohun àmúṣagbára ṣe sọ.

IRRI sọ pé ìpèsè ìrẹsì ló ń kó ìdá mẹ́wàá (10%) àwọn gáàsì tó ń wá láti ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn káàkiri àgbáyé.

Ètò ìgbàlódé

Ilẹ̀ tí ọ̀dá omi ṣe àkóbá fún ní ìlú Hudianxiang ní Xinyang ní China

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn àgbẹ̀ tó wà ní ilẹ̀ ọ̀dá ń wá ìrẹsì tó máa ṣe gbìn pẹ̀lú omi tí kò pọ̀

Tilda ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò ìlànà láti mú àdínkù bá iye omi tí wọ́n ń lò láti fi gbin ìrẹsì bíi lílo Alternate Wetting and Drying (AWD). Ìlànà náà gba fífi ọ̀pá sínú ilẹ̀ ní ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀dógún (15cm) sábẹ́ ilẹ̀. Dípò gbíngbin ìrẹsì sí ibi tí ẹ̀kún omi wà, àwọn àgbẹ̀ á kàn máa bu omi sínú ọ̀pá náà ni.

Ní 2024, Tilda mú àlékún bá iye àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ń lò láti fi ṣàyẹ̀wò láti 50 sí 1,268. Àwọn àbájáde rẹ̀ dára gidi.

"A lè mú àdínkù bá omi lílò pẹ̀lú ìdá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27%) iná mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú ìdá méjìdínlọ́gbọ̀n (28%) àti ajílẹ̀ lílò pẹ̀lú ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25%). Ó wòye pé àlékún bá ìrẹsì tí wọ́n pèsè pẹ̀lú ìdá méje (7%).

"Kìí ṣe mímú àlékún bá ìpèsè ìrẹsì nìkan pẹ̀lú owó púpọ̀, ó wáyé nípasẹ̀ owó kékeré," ó sọ.

Laborde sọ pé àdínkù bá methane tó ń jáde pẹ̀lú ìdá márùndínláàdọ́ta (45%) tó sì ní ìgbàgbọ́ wà pé èyí ṣì tún lè lékún si di ìdá àádọ́rin (70%) tí wọ́n bá ń tẹ̀síwájú láti mú àdínkù bá ẹ̀kún omi tí wọ́n ń lò.

Àyípadà ojú ọjọ́

Àgbẹ̀ tó kó èrè oko sínú ọkọ̀ ojú omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn àgbẹ̀ ní Bangladesh ń wá irú ìrẹsì tí ó máa le gba ẹ̀kún omi dúró

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrẹsì ti ń ṣe ìrànwọ́ láti pèsè oúnjẹ fún bílíọ̀nù èèyàn - pàápàá látara àwọn èyí bíi IR8 – àyípadà ojú ọjọ́ ń dúnkokò mọ́ ìpèsè rẹ̀ báwọn agbègbè tó ń pèsè ìrẹs]I ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kojú ọ̀dá òjò, àgbàrá òjò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní India ooru tó mú níbẹ̀ wọ 53C lásìkò tí wọ́n máa ń gbin ìrẹsì lọ́dún 2024. Ní Bangladesh, ẹ̀kún omi àti àgbàrá òjò ń ba ọ̀pọ̀ nǹkan oko jẹ́.

IRRI ń wá ojútùú sí ìṣòro yìí látara àwọn irúfẹ́ ìrẹsì 132,000 tí wọ́n ní nílẹ̀. Lára èyí tí wọ́n ṣàwárí ni èyí tó fàyè gba ìrẹsì láti dàgbà láì sí omi fún ọjọ́ mọ́kànlélógún.

Àwọn oúnjẹ míì

Ẹbí tí wọ́n ń jẹ ìrẹsì papọ̀ ní Kenya

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ní Africa ìrẹsì jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ ìdílé máa ń wá láti jẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nínú ìṣẹ́

Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba ló ti ń gbìyànjú láti rip é àwọn èèyàn wọn kò máa jẹ ìrẹsì tó bẹ́ẹ̀ mọ́.

Ní Bangladesh, wọ́n ṣe ìpolongo kan ní ọdún mẹ́ẹ̀dógún sẹ́yìn láti gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa jẹ òdùnkún bí owó ìrẹsì ṣe ti gbẹ́nu sókè.

"A nífẹ̀ẹ́ òdùnkún… ṣùgbọ́n ó ṣóro láti yí ọkàn wa padà láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tí wọ́n fi òdùnkún ṣe ," olùgbé Dhaka kan Shareef Shabir ṣèrántí.

China náà gbé irú ìpolongo bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ lọ́dún 2015, níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti ṣàfihàn pé oúnjẹ tó dára ní òdùnkún.

Orílẹ̀ èdè náà ti di olùpèsè òdùnkún lọ́pọ̀ yanturu lọ́dún 1990 tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń rí òdùnkún gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ síbẹ̀ ìpolongo náà kò kẹ́sẹ járí.

Àwọn èèyàn ní ẹkùn ìwọ̀-oòrùn gúúsù China ló máa ń rí ara wọn bí ẹni tó wà nínú ìṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń jẹ òdùnkún gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ Jakob Klein ṣe sọ.

Ṣíṣe ìpinnu tó le

Ìrẹsì Biryani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wọ́n le se ìrẹsì pẹ̀lú ẹ̀fọ́ láti fi ṣe biryani

Káàkiri àgbáyé, ìrẹsì jẹ́ oúnjẹ tó ti dàpọ̀ mọ́ ìgbé ayé rẹ̀. Ó jẹ́ oúnjẹ tó dùn, ó rọrùn láti sè, gbé pamọ́ àti gbé láti ibìkan sí òmíràn.

Ìrẹsì tọ́ọ̀nù mílíọ̀nù 520 láwọn èèyàn ń jẹ káàkiri àgbáyé láàárín ọdún kan.

Ní Philippines, Adrian Bianca Villanueva gbà pé òun le mú àdínkù bá ìrẹsì jíjẹ àmọ́ òun kò le yọ ọ́ pátápátá.

"Kòdá bí mi ò bá fẹ́ jẹ ìrẹsì, tí mob á lọ sí ibi ayẹyẹ tàbí ilé ẹlòmíràn, wọ́n máa fún mi ní ìrẹsì," ó sọ.

"Mo rò ó pé mà á mú àdínkù bá ìrẹsì jíjẹ àmọ́ mi ò ní yọ kúrò lára oúnjẹ mi pátápátá nítorí ó wà lára ìgbé ayé wa."