Mo ya fọ́tò náà láti fi han àgbáyé ọṣẹ́ tí ebi ń ṣe fáwọn ọmọdé ní Gaza

Àkọlé fídíò, Ebi Gaza
Mo ya fọ́tò náà láti fi han àgbáyé ọṣẹ́ tí ebi ń ṣe fáwọn ọmọdé ní Gaza

Ayafọto kan ni Gaza ti ṣalaye itan to rọ mọ bi o ṣe ya fọto ọkan-o-jọkan fọto to n gba omi loju, eleyi to se afihan ọmọde jojolo kan tie bi ti sọ di nnkan mii.

Ahmed al-Arini ṣalaye fun BBC Newshour pe oun fẹ "fi han gbogbo agbaye ọwọja ebi ati airi ounjẹ gidi jẹ" ti o n ba awọn ọmọ ọwọ atawọn ọmọde finra ni Gaza ni.

Awọn onimọ nipa ipese ounjẹ lagbaye ko tii ka ohun to n ṣẹlẹ ni Gaza si iyan, ṣugbọn awọn ajọ gbogbo labẹ ajọ iṣọkan agbaye UN ti ṣekilọ pe awọn iyan atọwọda ti n gbilẹ nibẹ.