Àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò tó ogún ọdún léwájú ìwọ́de tako ìjọba ọlọ́dún gbọọrọ ní Togo

Awọn ọdọ ṣewọde tako ijọba Faure Gnassingbe, olori ijọba ọlọdun pipẹ ni Lome, Togo.

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, By Isidore Kouwonou and Angela Henshall
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ijọba to ti wa lori aleefa fun ọdun gbọọrọ ni Togo ti mu ki awọn ọdọ orilẹede naa kora jọ bayii lati ṣewọde tako ijọba naa.

Awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ti i to ogun ọdun ati awọn to ti pe ni wọn kora jọ ti wọn si bẹrẹ iwọde to ṣi n tẹsiwaju naa ni Togo.

Eredi iwọde naa ni lati tako ijọba Aarẹ Faure Gnassingbé, ẹni to ti fẹrẹ pe ọgọta ọdun ti idile rẹ ti n ṣejọba Togo.

Tẹ o ba gbagbe, Eyadema Gnassingbé to jẹ baba fun Faure lo wa lori aleefa naa lati 1967 titi di 2005 to ku.

Ọdun 2005 naa ni ọmọ rẹ, Faure ti gba ipo naa, eyi to ti pe ogun ọdun bayii.

Ijọba aninilara to fi oṣi ta araalu ni wọn ni ẹbi Gnassingbé n ṣe, o le to bẹẹ ti awọn ọdọ ti pupọ ninu iya naa ko ṣoju wọn gan-an ti dide bayii lati tako ijọba yii.

Koda, awọn ọdọ Togo to wa loke okun, fifẹ han si ẹhonu naa lati ori ayelujara.

Awọn olorin, awọn to wa lẹka ẹkọ, awọn oniṣẹ ọna ti bẹẹ bẹẹ lọ naa faramọ ifẹhonuhan yii.

Ohun ti wọn ni awọn n fẹ ni ki Aarẹ Faure Gnassingbé fipo naa silẹ, wọn ni niṣe nijọba rẹ maa n mu awọn to ba tako o.

Wọn fi kun un pe igbesi aye awọn ko dẹrun latari ọrọ aje to dojuru, bẹẹ ni wọn ni awọn fẹ atunṣe si ofin orilẹede naa.

Orilẹ ede Togo paala pẹlu Ghana ati Benin.

Gẹgẹ bi akọsilẹ Banki Agbaye si ti wi, Togo jẹ ọkan lara awọn orilẹede to toṣi ju lagbaaye.

Wọn ni o fẹrẹ jẹ pe idaji awọn eeyan to wa nibẹ ni ìyà n jẹ.

Èèyàn mẹ́wàá kú níbi ìwọ́de

Aworan awọn oluwọde ni tako Aarẹ Gnassingbe, ni Lome

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọsẹ to kọja ti iwọde kọkọ waye, ko din ni eeyan mẹwaa to padanu ẹmi, bẹẹ ni ọpọ farapa. Gẹgẹ bi awọn ẹgbẹ awujọ ni Togo ṣe fidi ẹ mulẹ.

Iwọde naa bẹrẹ lẹyin ti wọn bura wọle fun Aarẹ Fuare bii Aarẹ igbimọ awọn minisita, iyẹn ipo kan ti ko ni opin igba ti yoo pari.

Ipo naa to sunmọ ti olootu ijọba, waye lẹyin ti Togo bẹrẹ ofin tuntun ni 2024.

Wọn kuro ni ijọba aarẹ bọ si ti igbimọ iṣejọba.

Ṣaaju ni wọn ti fi ofin de awọn to ba fẹẹ ṣe iwọde, ọdun 2022 ni wọn ti ṣe ofin naa ni Togo. Eyi naa lo fa a ti awọn ajafẹtọọ ọmọniyan fi n koro oju si ijọba to wa lode, wọn ni ijọba n lo awọn agbofinro lati dena awọn eeyan to fẹẹ wọde.

Ṣugbọn ijọba ti sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ, wọn ni awọn ko mọ nnkan kan nipa iku awọn to padanu ẹmi ninu iwọde ọjo mẹta to waye ni olu ilu Togo ti i ṣe Lome.

Ijọba Togo ti ni o ṣee ṣe koun pe awọn to ṣeto iwọde naa lẹjọ- Ijọba Faure sọ pe awọn to ṣeto naa n gbe ohun ti ko ri bẹẹ kiri, ati pe ikorira ni wọn fi gbe e kalẹ lati oke okun.

Nigba to n tako eyi, Dany Komla Ayida, awoye oṣelu ati ajafẹtọọ ọmọniyan loke okun, sọ pe awọn to n fi ẹhonu han n sọ itan aye wọn ni

"Wọn ṣafihan ìṣẹ́ ati òṣì ni bo ṣe n koju wọn lojoojumọ aye. Owo ina wọn gogo, omiyale n ṣọṣẹ kaakri ilu ti ojo ba rọ, ko tun si iṣẹ fun wọn lati ṣe."

Dany Komla lo ṣalaye bẹẹ.

Ṣé ó lè di nńkan ńlá?

Aworan apa kan Togo ati awọn ilu to sunmọ ọn.

Iwoye awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ohun to n ṣẹle yii ni pe, tẹlẹ, awọn oloṣelu alatako lo maa n wa nidii iwọde, ṣugbọn ti ọtẹ yii yatọ, nitoriawọn ọdọ ti a mọ si Gen Z lo wa nidii eyi.

Gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ ni Kenya, awọn ọdọ Togo korajọ lọpọ yanturu nipasẹ awọn ẹka ayelujara bii Facebook, Signal ati TikTok, wọn si tu jade sojuu popo.

Wọn n kuro loju opo kan bọ si omiran, kijọba ma le gba ibi kan mu wọn.

Susanna Eusebi, awoye lati 'Control Risks', ni oun gbagbọ pe iwọde eleyii yatọ, pẹlu ọna ti awọn ọdọ gba fi airiṣẹṣe, ebi, ofin onikumọ ati bẹẹ bẹẹ lọ to aye leti.

Togo to paala pẹlu Ghana, Benin ati Burkina Faso, ti eeyan miliọnu mẹjọ aabọ ( 8.5 million) si wa nibẹ, ko lowo lọwọ bii awọn alamuleti rẹ yii, bẹẹ si ni ko ni nnkan alumọni tabi ti agbara.

Eto ọgbin ni Togo fi n ṣe ọrọ aje, ati bi wọn ṣe n fi agbami okun wọn gbe nnkan wọlu nipasẹ ọkọ oju omi. Eyi lo fa a ti iṣẹ ko fi pọ nibẹ.

Minisita fun ileeṣẹ ọmọ ogun Togo nigba kan, Essozimna Marguerite Gnakadè, kọwe laipẹ yii, nibi to ti ni ki awọn ẹṣọ ji giri, o ni igba ọtun de tan.

" Ijọba alatako naa lagbara tiẹ ni Lomé - ṣugbọn ko kọja ibẹ.

"Mo lero pe ohun to n ṣẹlẹ yii yoo lẹyin."

Alex Vines, awoye kan ni Chatham House lo sọ bẹẹ.

Bi ọ̀rọ̀ olórin tí wọ́n mú nítorí ìwọ́de ṣe di wàhálà

Ibẹrẹ ọdun yii ni wahala naa ti bẹrẹ si i rugbo bọ ni Togo, nigba ti awọn olorin ati awọn oniroyin ori ayelujara bẹrẹ si i fi ẹhonu han, ti pupọ wọn ko si gbe ni Togo, oke okun ni wọn n gbe.

Ni oru ọjọ kẹrindinlọgbọn , oṣu Karun-un, ijọba mu olorin taka-sufee ọmọ Togo kan, Tchala Essowè Narcisse (alias Aamron).Ile rẹ ni wọn ti lọọ fi ofin gbe e.

Awọn alaṣẹ sọ pe wọn gbe e nitori o n bu ẹnu atẹ lu ijọba ogun ọdun ti Faure Gnassingbé n ṣe.

Bayii ni wọn gbe Aamron lọ sileewosan awọn alarun ọpọlo to wa ni Aného, ilu to to kilomita 45 si Lomé.

Bi wọn ṣe fiya jẹ ẹ lọhun-un mu ki araalu binu, awọn olorin ati awọn akọroyin ayelujara si ni ki awọn ọmọ Togo kora jọ lato fẹhonu han lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa.

Ọjó naa ni wọn tun ko ọpọ eeyan ju si atimọle.

"A o ni i yee fẹhonu han, afi ti Faure Gnassingbé ba fipo silẹ. Zaga Bambo, olorin Togo kan lo gbe e jade bẹẹ lori ayelujara kiri.

Wọn fi Aamron silẹ lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa.

Lọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa kan naa, awọn oluwọde gbegidina ọpọ agbegbe ni olu ilu Togo.

Ikọlu bẹrẹ pẹlu awọn ẹṣọ ijọba, ọpọ lo si koju tajutaju ti wọn yin. Wọn sọ okuta lu awọn oluwọde mi-in pẹlu.

Akojọpọ ẹgbẹ ajafẹtọọ kan ti wọn jẹ mẹtalelogun (coalition of 23 Togolese civil rights groups) ti ni ki iwadii waye lori iwọde yii ati ohun to ṣẹlẹ nibẹ.

"Awọn eeyan to ku ti pọju. Awọn to ṣeṣe naa pọ."

Ọjọgbọn David Dosseh, agbénusọ fun ẹgbẹ Front Citoyen Togo-Débout, lo sọ bẹẹ .