Bàbà mi, Ayinla Omowura, burú lóòtọ́, ṣùgbọ́n irọ́ lohun tí ọ̀pọ̀ ń sọ nipa ìgbé ayé rẹ̀ – Kabirat Ayinla Omowura

Àkọlé fídíò, Bàbà mi, Ayinla Omowura, burú lóòtọ́, ṣùgbọ́n irọ́ lohun tí ọ̀pọ̀ ń sọ nipa ìgbé ayé rẹ̀ – Kabirat Ayinla Omowura
Bàbà mi, Ayinla Omowura, burú lóòtọ́, ṣùgbọ́n irọ́ lohun tí ọ̀pọ̀ ń sọ nipa ìgbé ayé rẹ̀ – Kabirat Ayinla Omowura

Gbajumọ olorin ni Ayinla Ọmọwura nigba aye rẹ pẹlu ẹda orin rẹ ti wọn n pe ni Apala.

Iku rẹ lọpọ ọdun sẹyin jẹ eyi ti o mu ọpọlọpọ ibeere jade. Oniruuru alaye lawọn eeyan ti sọ pe o ṣokunfa iku rẹ.

BBC News Yoruba ba ọmọ oloogbe naa sọrọ nipa bi igbe aye olorin naa ati asiko igbẹyin rẹ ṣe ri.

O ni oniruuru ahesọ ọrọ lawọn eeyan ti sọ nipa iku baba oun eyi to ni o jina si otitọ.

O ni ọpọlọpọ eeyan to n sọ ọr tabi gbe sinima jade nipa baba oun ni wọn n fi afikun ọrọ si i ju bi ọrọ ọhun ṣe ri.