Orílẹ̀èdè UK náà ti kéde àdínkù owó ìrànwọ́ sílẹ̀ òkèèrè, báwo ni yóò ṣe kàn Afirika?

Aworan alawọdudu kan

Oríṣun àwòrán, PA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ijọba Uk ti kede pe oun yoo mu adinku ba iranwọ toun n ṣe silẹ okeere to fi mọ iranwọ fun eto ẹkọ awọn ọmọde ati iranwọ fun eto ilera awọn obinrin papaa julọ nilẹ Afirika.

Ohun ti ijọba UK sọ tẹlẹ loṣu Keji to kọja ni pe awọn yoo mu adinku ba iranwọ silẹ okeere pẹlu ida 40%.

Wọn ni awọn yoo lo owo tawọn ba ge fun eto abo araalu ni Uk.

Eyi waye lẹyin ti Aarẹ Donald Trump ti kọkọ mu adinku nla ba ọpọ iranwọ silẹ okeere ti orilẹede Amẹrika n ṣe to fi mọ owo iranwọ ti Amẹrika maa n ṣe nipasẹ ajọ USAID.

Ṣaaju ni BBC ti mu iroyin wa lori ipa ti idaduro owo iranwọ silẹ okeere yoo ni lori eto ati gbogun ti arun HIV/Aids, ikọ fere ati ilera awọn ọmọde.

Iroyin kan lati UK sọ pe ilẹ Afirika ni igbesẹ UK ọhun yoo ṣe ipalara fun julọ.

Iroyin naa sọ pe ẹka eto ilera awọn obinrin, riri omi to mọ gaara mu ati gbigbogun ti ajakalẹ arun yoo fara kaaṣa gan an.

Koda, iroyin naa tun sọ pe iye awọn eeyan ti ajakalẹ arun yoo maa pa yoo lọ soke si ni Afirika.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ Bond to n ri si ọrọ iranwọ silẹ okeere ni UK sọ pe awọn obinrin atawọn ọmọde to n gbe lawọn awujọ tawọn ti ko rọwọ họri pọ si ni yoo fara kaaṣa adinku eto iranwọ UK silẹ okeere naa julọ.

''Nnkan to n kọmi lominu ni pe adinku yoo ba owo iranwọ si Afirika lori ọrọ eto ẹkọ, ati eto ilera.

Awọn eeyan to n gbe nibi ti wọn ti n ja, atawọn obinrin ni igbesẹ ijọba UK yii yoo ṣe ipalara fun julọ.

O yẹ ki UK fikun iranwọ ti wọn n ṣe silẹ okeere ni lasiko yii ti Amẹrika ti da iranwọ silẹ okeere duro.''

Ọfiisi UK to n ri si ọrọ ilẹ okeere sọ pe adinku yoo ba iranwọ ti UK n ṣe sawọn orilẹede kan, ṣugbọn ọfiisi naa ko tii darukọ awọn orilẹede ti yoo fara gba.

Owo to yẹ ko wa ninu eto iṣuna UK fun ọdun 2027 yẹ ko jẹ £15.4bn, amọ, ko ni ju £6.1bn lọ bayii pẹlu adinku ti yoo ba a.

Ọpọ oloṣelu lati inu ẹgbẹ alatako to fi mọ Kemi Badenoch ni wọn faramọ igbesẹ ijọba UK naa nigba ti wọn kọkọ kede rẹ loṣu Keji to lọ.

Awọn adari mii bii eekan ẹgbẹ Liberal Democrats, Ed Davey, naa ṣatilẹyin fun igbesẹ ọhun, o ni oun faramọ ki wọn nawo naa sori eto abo UK.

Idi ti UK ṣe fẹ ṣe adinku owo iranwọ silẹ okeere

Aworan Kei Starmer

Oríṣun àwòrán, PA Media

Olootu ijọba UK, Keir Starmer, sọ pe ijọba fẹ lo owo ti wọn ba fi pamọ ninu owo iranwọ naa lati jẹ ki owo ti ijọba n na lori eto abo gberu sii pẹlu ida 2.5% titi ọdun 2027 si 2020.

Eyi tumọ si pe ijọba yoo na afikun £13.4bn lori eto abo lọdun 2027.

Idi miran gẹgẹ bii minisita eto okowo ni UK, Douglas Alexander, ṣe ṣalaye owo ko pọ nilẹ mọ fun ijọba lati na, ati pe awọn araalu ko maa ṣe iranwọ to bẹẹ mọ lori ọrọ ilẹ okeere.

Minisita okowo sọ pe ''ijọba fẹ ṣeto to mọyan lori fawọn iran to n bọ lọjọ iwaju ni UK.''

Ki ni eyi tumọ si fun ilẹ Afirika?

UK maa n pese iranwọ fawọn ilẹ okeere lẹka eto ilera, eto ẹkọ, iṣejọba, iṣe aanu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ajọ Malaria No More Uk to n gbogun ti itankalẹ arun iba kaakiri Afirika sọ pe adinku ti yoo ba owo iranwọ si Afirika yoo fa ọwọ ago sẹyin lori igbiyanju lati doola ẹmi awọn ọmọde lọwọ aisan iba.

Astrid Bonfield, ọga agba nileeṣẹ 'Malaria No More', ni UK, 'salaye ninu atẹjade kan pe : "A gbọdọ maa ranti pe bo tiẹ jẹ pe ilẹ okeere lati n nawo rẹ, ile nibi lati n anfaani ẹ, nitori o n mu aabo nipọn si i ni UK, alaafia, ilera pipe ati ọrọ̀ si n pọ si pẹlu. "

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ko darukọ awọn orilẹede ti adinku naa yoo kan julọ, o ṣee ṣe ki awọn to n koju ikọlu ati iṣoro ayipada oju ọjọ fara gba a gidi.

Awọn bii Sudan, South Sudan, Chad, Niger, Ethiopia ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣaaju ni ijọba Naijiria ti buwọ lu iwe adehun mẹjọ pẹlu ijọba UK lọdun yii, eyi ti iye owo rẹ to N589 billion.

Ni bayii, ko ti i han gedegbe boya adehun naa yoo kan adinku iranwọ ti wọn fẹẹ gunle naa.

Àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé tó ti dín ọwọ́ ìrànwọ́ wọn ku

Yatọ fun Aarẹ Trump to fagile ida ọgọrin (80%) awọn eto iranlọwọ ti ajọ USAID maa n ṣe tẹlẹ, France, Germany ati Sweden naa ti din iranlọwọ wọn ku jọjọ laaarin ọdun 2024 ati 2025.

Gẹgẹ bi alaye Donor Tracker, ẹka ayelujara kan to maa n ṣagbeyẹwo iranlọwọ awọn orilẹede agbaye, France ti din iranwọ 'Official Development Assistance ' (ODA), ti wọn maa n ṣe ku pẹlu $1.5 billion, ninu eto iṣuna ọdun 2025.

Eyi tumọ si pe ida mẹtalelogun (23%) ni wọn ti dinku lọdun yii, ti a ba fi we bo ṣe wa ninu ilana iṣuna ọdun 2024 to kọja.

Ni ti Germany, awọn naa din ODA wọn ku pẹlu owo to to19.8 billion Euros, ninu eto iṣuna wọn fun 2025.

Bakan naa, loṣu Kẹsan-an ọdun to kọja, Minisita ilẹ Sweden to n ri si idagbasoke ati ajẹṣẹku, Benjamin Dousa, ṣalaye pe iranwọ ODA ti awọn naa yoo dinku pẹlu owo to to $291 million laaarin 2026 si 2028.