''Òkú ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ ni mo bá nígbà tí mà á fi wọ ìlú lẹ́yìn táwọn agbébọn ṣọṣẹ́''

Àwòrán ibi tí ìkọlù náà ti wáyé

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

"Ní ìlú mi ní Umualaoma, èèyàn mẹ́sàn-án ni wọ́n pa tó fi mọ́ ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀."

Èyí ni ohun tí Ogbu Chidozie sọ fún BBC.

Chidozie sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò sí ní ìlú nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ìlú àwọn, ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Keje ni òun wọ ìlú láti rí òkú ẹ̀gbọ́n òun àti ọkọ rẹ̀.

Àwọn agbébọn ṣọṣẹ́ ní ìlú mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Arondizuogu, ìjọba ìbílẹ̀ Ideato ní ìpínlẹ̀ Imo tí wọ́n sì ṣekúpa èèyàn mẹ́tàdínlógún ní alẹ́ ọjọ́bọ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo sọ pé àwọn agbébọn mẹ́ta tí wọ́n ṣiṣẹ́ náà ni wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ IPOB/ESN tí wọ́n sì ṣe ìkọlù sí ìlú Ndi-Ejezie, Umualaoma, àti Ndiakuwata Uno.

Fídíò kan tó gba orí ayélujára kan ṣe àfihàn òkú mẹ́rin tí wọn tẹ́ sílẹ̀, táwọn agbébọn pa nígbà tí wọn ń ta ayò

Ó lé ní èèyàn méje tó bá ìkọlù náà lọ nígbà tí ọ̀pọ̀ míì náà sì tún farapa.

Chidozie sọ fún BBC pé àwọn agbébọn mẹ́ta náà yawọ ìlú pẹ̀lú ọ̀kadà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ti rí bí wọ́n ṣń ń gun ọ̀kadà náà lọ.

Nǹkan bíi aago mẹ́jọ àbọ̀ alẹ́ ọjọ́bọ̀ làwọn agbébọn, tí wọ́n wọ aṣọ ológun, ń ṣiná ìbọn fáwọn èèyàn bí wọ́n ṣe ń sá lọ.

Ó ṣàlàyé pé láti Ndi-Ejezie ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìbọn yínyìn náà títí tí wọ́n fi dé Ndiakuwata tí wọ́n sì tún yìnbọn bẹ́ẹ̀ padà láti Ndiakuwata títí tí wọ́n fi padà sí Ndi-Ejezie.

Ó fi kun pé àwọn agbébọn ọ̀hún kìí ṣe olè nítorí wọn kò jí ohunkóhun rárá. Nígbà náà ẹni tí wọ́n bá rí tó bá wà nínú ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ níṣe ni wọ́n ń yìbọn pa ẹni náà, tí wọ́n sì ń lé gbogbo àwọn tó bá ń sá.

Fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn àwọn òkú mẹ́rin tí wọ́n tẹ́ sílẹ̀ níbìkan ní ìlú Ndi-Ejezie.

Ọkùnrin kan nínú fídíò náà ń sọ̀rọ̀ bí òun àtàwọn òkú tó wà nílẹ̀ náà ṣe ń ta ayo lásìkò táwọn agbébọn náà dé tí wọ́n ṣiná ìbọn bolẹ̀ àmọ́ tí orí kó òun yọ bó ṣe fi eré gé e.

Àwòrán àsíá ọlọ́pàá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police

Ṣé IPOB/ESN lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà?

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo, Henry Okoye nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ṣàlàyé pé àwọn tí kó àwọn ọlọ́pàá sí ìgboro láti lọ ṣèwádìí àwọn tó wà nídìí ìkọlù náà, kí wọ́n sì fi póró òfin gbé wọn.

Àtẹ̀jáde náà sọ pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń ṣe ìwádìí ìwà ọ̀daràn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tanná wádìí gbogbo agbègbè náà, tí wọ́n sì sọ àrídájú rẹ̀ pé ohun gbogbo ti padà sípò àti pé àwọn ń ṣiṣẹ́ láti rip é irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ kò wáyé mọ́.

Láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ́yìn láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Imo ti ń kojú ìwà ọ̀daràn látọwọ́ àwọn agbébọn.

Lọ́pọ̀ ìgbà ni ìjọba máa ń pe àwọn tó ṣe ìkọlù náà bíi àwọn agbébọn èyí tí wọn k]o mọ ibi tí wọ́n ti wá.

Nígbà mìíràn ni wọ́n máa ń fẹ̀sùn kàn pé ikọ̀ ológun àwọn tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra, Ipob, Eastern Security Network (ESN) ló ń ṣiṣẹ́ ibi ọ̀hún.

Kò jọ pé wàhálà àìsí ààbò tó ń wáyé sáwọn aráàlú ní ìpínlẹ̀ Imo yóò dópin láìpẹ́.