Tinubu kò dẹ́yẹ sí ẹkùn àríwá, onírúurú àkànṣe iṣẹ́ ló ń ṣe níbẹ̀, iléeṣẹ́ ààrẹ dáa padà fún Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, Rabiu Musa Kwankwaso/X
Ileeṣẹ Aarẹ ti fesi sọrọ ti gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Musa Kwankwaso sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ko dasi ọrọ ẹkun ariwa ninu isejoba rẹ.
Kwankwaso sọ pe apa guusu ni Tinubu n ṣe oniruuru iṣẹ idagbasoke si nigba to gbe ọrọ ẹkun ariwa pati.
Kwankwaso fidi ọrọ yii mulẹ níbi ipade awọn alẹnulọrọ to waye nílùú Kano l'Ọjọbọ ọjọ kẹrinlelogun oṣu keje yii.
Kwankwaso fidi ọrọ yii mulẹ níbi ipade awọn alẹnulọrọ to waye nílùú Kano l'Ọjọbọ ọjọ kẹrinlelogun oṣu keje yii.
Kwankwaso ni ọpọ ọna lapa ariwa lo ti bajẹ tan, o ni o wa jẹ pe lasiko ti ijọba Tinubu n nawo rọgun rọgun sori oriṣiiriṣii akanṣe iṣẹ lẹkun guusu Naijiria ni eyi n ṣẹlẹ.
Amọ, oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Sunday Dare, sọ loju opo X rẹ pe irọ to jina sootọ ni gbogbo nnkan ti Kwankwaso sọ.
Dare ni lara awọn ẹri to fidi rẹ mulẹ pe Tinubu ko dẹyẹ si apa ariwa ni iṣẹ lori ọna mọrosẹ lati Abuja si Kaduna to fi de Kano to n lọ lọwọ.
Iṣẹ lori ọna mọrosẹ Sokoto si Badagry ati iṣẹ lori ọpa to n gbe gaasi lati Ajaokuta si Kaduna to fi de Kano tun jẹ akanṣe iṣẹ mii ti ijọba Tinubu n ṣe lapa ariwa.
Ọgbeni Dare ni ijọba n ṣe oriṣiiriṣii iṣẹ idagbasoke kaakiri ẹkun ariwa Naijiria.
Oriṣiiriṣii iṣẹ idagbasoke lo n lọ lọwọ lẹkun ariwa bayii - Ileeṣẹ aarẹ
Ọgbẹni Dare ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ìjọba àpapọ̀ tun ti na $158.15m lori eto ọgbin ni ipinlẹ mẹsan an lapa ariwa.
Bakan naa ni oludamọran aarẹ tun sọ nípa àwọn iṣẹ ti ijọba apapọ ti ṣe lẹka eto iiera.
Dare ni diẹ lara awọn iṣẹ naa ni imugbooro ile ẹkọ ẹkọṣé ìṣẹgun fasiti ABU, Zaria, ti fasiti UNIJOS naa ati ile iwosan FMC to wa ni Nguru.
Oludamọran aarẹ tun ni ko din ni ẹgbẹrun kan ile iwosan alabọde ti ijọba apapọ ti taji l'ẹkun Ariwa.
Ọgbẹni Dare tun sọ nípa iṣẹ ti ijọba n ṣe lori opopona Kaduna sí Jos, Kano sí Maiduguri at'awọn àtúnṣe àwọn ọna n'ipinlẹ Adamawa ati Borno.
Oludamọran aarẹ ni ọna reluwee lati Kaduna sí Kano to fi de Maradi naa ko gbẹyin.
Tinubu kò ṣiṣẹ́ ìdàgbàsókè s'Ókè Oya, ẹkùn gúsù ló ń náwó Nàìjíríà sí - Kwankwaso
Oludije fun ipo aarẹ f'ẹgbẹ oṣelu NNPP lọdun 2023, Rabiu Musa Kwankwaso ti sọ pe ìjọba Aarẹ Bola Tinubu ti pa ẹkùn Ariwa Naijiria ti fún iṣẹ idagbasoke.
Kwankwaso to tun jẹ gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ ri sọ pe apa guusu Naijiria ni Tinubu ti n ṣe oniruuru iṣẹ idagbasoke.
Kwankwaso fidi ọrọ yii mulẹ níbi ipade awọn alẹnulọrọ to waye nílùú Kano l'Ọjọbọ ọjọ kẹrinlelogun oṣu keje yii.
Ohun ti a gbọ ni pe bi idaji eto ìṣúná Naijiria lo n lọ si ẹkun kan ṣoṣo ni Naijiria.
Ẹ jẹ kí n ran awọn ti wọn n wa gbogbo ọna lati ja ìjọba lole pe aito owo jẹ ọkan lara ìṣòro tí Naijiria n dojú kọ, nigba t'awọn mii si tun n ṣe ọwọ owo to wa kumọ kumọ.
Ara nnkan bayii lo n ṣokunfa eto abo to mẹhẹ, ebi to n pa araalu at'awọn ìṣòro mii," Kwankwaso lo sọ bẹẹ.
Kwankwaso ni ọpọ ọna lapa ariwa lo ti bajẹ tan, o ni o wa jẹ pe lasiko ti ijọba Tinubu n nawo rọgun rọgun sori oriṣiiriṣii akanṣe iṣẹ lẹkun guusu Naijiria ni eyi n ṣẹlẹ.
Kwankwaso wa kepe Tinubu lati ri pe o n lo ọrọ orilẹede Naijiria fun idagbasoke gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria.
Ohun ti ọrọ ti Kwankwaso sọ tumọ si
Kwankwaso sọrọ yii lasiko t'awọn eeyan kan n sọ pe APC n fa oju rẹ mọra ki í lè darapọ mọ ẹgbẹ naa.
Eyi lo si ti jẹ kí ọpọ maa sọ pe ti Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC ko ba ni ibasepọ to dan moran pẹlu rẹ, o ṣee ṣe ki Kwankwaso sí duro sinu ẹgbẹ NNPP.
Amọ, ọpọ lo ti n sọ pe ọrọ naa lọwọ oselu ninu torí Kwankwaso lo ti n sọ fun ìjọba awọn nnkan to yẹ kí wọn ṣe lapa Oke Oya ni Naijiria.
Láìpẹ́ yìí ni awọn fọto kan lu ori ayelujara pa eyi to ṣafihan bi Kwankwaso ṣe n gba awọn oloṣelu kan ti wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ APC tẹlẹ sinu NNPP.
Kwankwaso tun sọ laipẹ yii pe ko sí ìdí foun lati darapọ mọ ẹgbẹ ti ko bikita nipa awọn ti oṣi ati iṣẹ n ba finra.
Amọ, lati igba ti Abdullahi Ganduje ti kọwe fipò silẹ gẹgẹ bii alaga apapọ APC lawọn ọmọlẹyìn Kwankwaso ti n sọ pe ibi to ba lọ lawọn naa yoo tẹle lọ.
Ọpọ onimọ nipa eto oselu woye pe ọrọ naa wi pe ọ ni ṣe pẹlu didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mii.















