Àwọn jàndùkú agbébọn pa tọkọ taya àti èèyàn mẹ́ẹ̀dógún míì, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan awọn abule tawọn agbebọn ti ṣọṣẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn janduku agbebọn ṣọṣẹ ni abule mẹta ni ijọba ibilẹ Ideato ni ipinlẹ Imo lẹyin ti wọn yinbọn pa eeyan mẹtadinlogun.

Ogbu Chidozie to ba BBC Igbo sọrọ ṣalaye pe eeyan mẹsan an to fi mọ ẹgbọn oun ati ọkọ rẹ ni wọn yinbọn pa ni Umualaoma ti i ṣe abule awọn.

Chidozie to sọ pe oun ko si abule nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ lalẹ Ọjọbọ, ṣalaye pe oku ẹgbọn oun ati ọkọ rẹ loun ba nilẹ nigba toun pada de.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo sọ pe awọn abule mẹta tawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ IPOB/ESN ti ṣọṣẹ naa ni Ndi-Ejezie, Umualaoma, ati Ndiakuwata Uno.

Chidozie ni ọkada lawọn agbebọn mẹta ọhun gun wọ awọn abule naa lalẹ ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn fawọn araalu.

O ni aṣọ awọn sọja lawọn janduku to ṣọṣẹ naa wọ ṣiṣẹ laabi wọn ni nnkan bii ago mẹjọ abọ alẹ Ọjọbọ ti wọn si n yinbọn bi wọn ṣe n lọ.

Chidozie fikun ọrọ rẹ pe awọn agbebọn ọhun kii ṣe ole tori wọn o ji nnkan, o ni ohun kan ti wọn n ṣe naa ni pe wọn sa tẹle awọn eeyan kaakiri, wọn si n yinbọn fun wọn.

Fidio kan lori ayelujara tiẹ ṣafihan oku eeyan mẹrin to wa nilẹ labule Ndi-Ejezie to jẹ ọkan lara awọn abule tawọn agbẹbọn naa ti ṣọṣẹ.

Ọkunrin kan sọ ninu fidio naa bi oun ati eeyan mẹrin mii ṣe n ta ayo ''draft'' lọwọ kawọn janduku agbebọn naa to de ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.

Ọkunrin naa sọ pe ori lo ko oun yọ ninu iṣẹlẹ ọhun bi bẹẹ kọ oun naa ko ba ba a lọ.

Ọwọ Ipob/ESN wa ninu ikọlu yii

Ẹwẹ, agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Imo, DSP Henry Okoye, ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to ṣiṣẹ laabi yii gan.

DSP Okoye ni gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin ti ọwọ ọlọpaa ba ti tẹ wọn.

Ninu atẹjade kan to fi sita, DSP Okoye ni awọn ọlọpaa ti wa lagbegbe ti isẹlẹ ọhun ti waye lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ to tun le fẹẹ ṣẹlẹ.

Iṣẹlẹ awọn janduku agbebọn yii ti n waye fun ọpọ ọdun sẹyin bayii kaakiri awọn ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Imo.

Ohun ti ijọba saba maa n sọ naa ni pe awọn ko le sọ pato awọn ti awọn janduku ọhun jẹ.