Ilé ẹjọ̀ pàṣẹ pé kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá san mílíọ̀nù mẹ́wàá Naira fún àwọn olùwọ́de END SARS.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ọga agba ọlọpaa pata ni Naijiria, ati kọmiṣanna ọlọpaa Eko, san miliọnu mẹwaa naira fun awọn oluwọde to ṣeranti awọn ẹgbẹ wọn to fẹhonu han lasiko iwọde END SARS.
Miliọnu mẹwaa naira naa duro fun titẹ ẹtọ awọn olufẹhonu han to n ṣeranti ọdun kẹrin ti iwọde END SARS waye, mọlẹ labẹ ofin.
Adajọ Musa Kakaki to gbe idajọ naa kalẹ l'Ọjọbọ, sọ pe awọn ọlọpaa tẹ ẹtọ awọn oluwọde to kora jọ logunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2024, lati ṣeranti ọdun kẹrin ayajọ END SARS ni Lekki Toll Gate, mọlẹ labẹ ofin.
"Loootọ, awọn agbofinro lẹtọọ lati ri i pe alaafia wa laaarin ilu, ki awọn eeyan si pa ofin mọ, ṣugbọn wọn ko gbọdọ ko ipa to lodi si ijọba awaarawa ati ohun ti ofin sọ."
Adajọ Musa Kakaki lo ṣalaye bẹẹ.
Kí ló ṣelẹ̀ ṣíwájú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tẹ o ba gbagbe, o kere tan, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko mu ogun eeyan lara awọn oluwọde to n ṣeranti ọdun kẹrin ti ayajọ END SARS waye niluu Eko lọdun to kọja.
Ogunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2020 ni iwọde END SARS gan-an waye, nibi ti ọpọ ọdọ ti kora jọ ti wọn n pe fun fifi opin si ẹka ọlọpaa SARS lorilẹede yii.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọ lo bọ soju titi ni Lekki TollGate lati ṣe iwọde tako iwa ipa awọn ọlọpaa SARS yii si araalu.
Awọn ọdọ naa pe ipe yii lati fi opin si ipaniyan lai nidii ati iwa to lodi si ẹtọ ọmọniyan ti wọn fi ẹsun ẹ kan awọn ọlọpaa naa.
Bo tilẹ jẹ pe iwọde wọọrọ ni wọn ṣeto, o pada di rogbodiyan ti ẹmi bọ si. Awọn mi-in si ba ara wọn latimọlẹ fun igba pipẹ ninu awọn oluwọde naa.
Awọn ṣọja ṣina ibọn bole, o si kere tan, iroyin sọ pe oku to sun loju ija naa to mejila.
Iranti ọdun kẹrin naa lo pe logunjọ, oṣu Kẹwaa ọdun 2024, ti awọn oluwọde si tun kora jọ lati ranti rẹ ati awọn akọni ẹgbẹ wọn to ba ogun lọ.
Eyi ni wọn n ṣe lọwọ ni Lekki Toll gate l'Ekoo lọdun to kọja ti awọn ọlọpaa fi de ti wọn si ko wọn da sinu ọkọ awọn agbofinro lai sọ ohun pato ti wọn ṣe tako ofin Naijiria.
Ọpọlọpọ wakati ni iroyin sọ pe wọn fi da wọn duro sinu ọkọ naa, ki wọn too pada fi wọn silẹ lai fi ẹsun kankan kan wọn fun mimu ti wọn mu wọn.
Eyi lo mu awọn oluwọde naa gbe igbesẹ ofin, wọn ṣapejuwe iwa awọn ọlọpaa bii titẹ ẹtọ awọn lati ṣewọde wọọrọ mọlẹ.
Bakan naa ni wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria tako anfaani ti ofin fun awọn lati sọ ero ọkan awọn sita.
Àwọn olùpẹ̀jọ́
Eeyan mejilelogun ati awọn ajọ mẹta ti i ṣe Education Rights Campaign, the Take It Back Movement (TIBM) ati Campaign for the Defense of Human Rights lo pe ọlọpaa Naijiria lẹjọ.
Awọn oluwọde to pe ẹjọ naa ni: Hassan Taiwo Soweto, Uadiale Kingsley, Ilesanmi Kehinde, Osopale Adeseye, Olamilekan Sanusi, Osugba Blessing, Kayode Agbaje, Michael Adedeji, Jennifer Rita Obiora, Orunsola Oluremi ati Seyi Akinde.
Awọn mi-in ni: Akin Okunowon, Ugochukwu Prince, Aisha Omolara, Thomas Abiodun Olamide, Ogbu Obinna Ferdinald, Aghedo Kehinde Stephen, Duroonike Olawale, Isaac Obasi, Funmilayo Jolade Ajayi, ati Afeez Suleiman.
Àwọn olùjẹ́jọ́
Awọn ti wọn fẹsun titẹ ẹtọ ẹni loju mọlẹ kan ninu ẹjọ naa ti wọn si jẹ olujẹjọ ni:
Ọga agba pata fun awọn ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Kọmiṣanna ọlọpaa Naijiria, Alaga ajọ Task Force Eko, Gomina ipinlẹ Eko ati olootu idajọ ijọba ipinlẹ Eko.














