Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Nentawe Yilwatda, alága tuntun fún ẹgbẹ́ APC

Oríṣun àwòrán, Nentawe Yilwatda/X
Ẹgbẹ oṣelu APC ti kede Ọjọgbọn Nentawe Goshwe Yilwatda gẹgẹ bii alaga gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu naa.
Ọjọgbọn Yilwatda ni yoo rọpo Abdullahi Ganduje to kọwọ fipo silẹ loṣu Kẹfa to kọja gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ APC.
Nibi ipade igbimọ alaṣẹ APC ẹlẹẹkẹrinla iru ẹ to waye l'Ọjọbọ niluu Abuja ni wọn ti kede Ọjọgbọn Yilwatda gẹgẹ bi alaga tuntun.
Ali Bukar Dalori to jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ APC tẹlẹ lo ti n ṣe adele alaga fun ẹgbẹ naa lati igba ti Ganduje ti kọwe fipo silẹ loṣu Kẹfa.
Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ni Yilwatda i ṣe, o si jẹ ọmọbibi ipinlẹ Plateau.
Awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ APC to fi mọ Aarẹ Bola Tinuba ṣatilẹyin fun Ọjọgbọn Yilwatda lati dipo alaga apapọ APC mu.
Ohun to yẹ ki o mọ nipa alaga ẹgbẹ oṣelu APC tuntun
Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda jẹ Minisita fun ọrọ ọmọniyan ati siṣe aanu ninu ijọba Aarẹ Bola Tinubu.
Ọjọgbọn Yilwatda wa lara awọn ti afojusun wa pe wọn le di Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye l'Ọjọbọ lonii niluu Abuja.
Ọjọgbọn Yilwatda to jẹ ọmọbibi ipinlẹ Plateau figba kan ri jẹ olukọ ni ile ẹkọ giga yunifasiti imọ ọgbin to wa niluu Makurdi nipinlẹ Benue ko too darapọ mọ oṣelu.
Bakan naa ni Ọjọgbọn Yilwatda tun figba kan di ipo kọmiṣanna eleto idibo mu laaarin ọdun 2017 si 2021 ni ipinlẹ Benue, Anambra, Osun, Rivers ati Cross River.
Awọn ti oju wa lara wọn pe o ṣe e ṣe ko rọpo Ganduje

Oríṣun àwòrán, FB/MULTIPLE
Ipade ti APC ti yan Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda di dandan lẹyin ti alaga tẹlẹ, Abdullahi Ganduje, fipo silẹ lojiji loṣu Kẹfa.
Alaye Ganduje nigba naa ni pe oun fipo silẹ nitori ati boju to ilera oun.
Ko pẹ sigba naa ti wọn si fi yan Ali Bukar Dalori, ọmọ ipinlẹ Borno,gẹgẹ bii Adele alaga.
Ikọwefiposilẹ Ganduje waye lẹyin ọpọ ọdun ti awọn eeyan Aarin Gbungbun ilẹ yii ti n kede pe ki wọn da ipo naa pada sọdọ awọn.
Ọrọ naa ti n fa ariyanjiyan ṣaaju ki gomina Kano tẹlẹ naa too gba ipo yii.
Eyi ri bẹẹ nitori ọmọ Aarin Gbungbun lo wa nibẹ tẹlẹ, iyẹn gomina Nasarawa tẹlẹ, Abdullahi Adamu.
O si tun ṣee ṣe ki APC pinnu pe ki Bukar Dalori to n dele maa ba ipo naa lọ, titi digba ti ẹgbẹ yoo ṣepade apapọ loṣu Kejila, gẹgẹ bi agbẹnusọ wọn, Bala Ibrahim, ṣe ṣalaye fun BBC.
Eyi ni awọn oloṣelu mẹta to ṣee ṣe ki ipo naa ja mọ ẹnikan ninu wọn lọwọ.
Tanko Almakura

Oríṣun àwòrán, Tanko Almakura/ FB
Gomina ipinlẹ Nasarawa tẹlẹ ni Tanko Almakura, oun naa wa lara awọn to ṣee ṣe ko di Alaga apapọ APC tuntun.
Ọdun ti pẹ ti Almakura ti jẹ ọmọ ẹgbẹ APC tootọ, o si ni oye oṣelu pupọ.
Bakan naa lo jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu CPC, eyi ti wọn pada fi da APC silẹ.
Ẹni ọwọ ni gomina Nasarawa tẹlẹ yii ni ẹkun Aarin Gbungbun Naijiria.
Laipẹ yii lo kede ni gbangba pe ẹyin Aarẹ Bola Tinubu loun wa digbi, lati tako ahesọ to ni inu awọn ọmọ APC ko dun si Aarẹ.
Tanko Almakura ni gomina Nasarawa lati 2011 titi di 2019, ẹgbẹ CPC lo fi wọle lakọkọ, APC lo si fi bọ sipo naa lẹẹkeji.
Simon Bako Lalong

Oríṣun àwòrán, Simon Bako Lalong/X
Gomina Plateau nigba kan ni Simon Lalong, oun naa wa lara awọn to ṣee ṣe ko di Alaga APC tuntun.
Tinubu ti figba kan yan an sipo minisita to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, ko too fipo naa silẹ, to gba ile igbimọ aṣofin lọ.
Agbẹjọro ni Lalong ko too wọnu oṣelu, oun lo si n ṣoju Guusu Plateau bayii nile igbimọ aṣofin.
Lalong ti figba kan ri di ipo Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Plateau mu, ko too di gomina lẹẹmeji, iyẹn lati 2015 titi de 2023.
Olulaja to ti gbiyanju pupọ lati ṣẹgun ikọlu to n ṣẹlẹ ni Plateau ni awọn eeyan mọ Lalong si, bẹẹ lo n gbiyanju lati pana ọtẹ ẹsin ati ti ẹlẹyamẹya.












