Díẹ̀ ló kù kí APC di ẹgbẹ́ tí kò ní àtakò kankan nílé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, National Assembly
Awọn sẹnetọ mẹrin, ati ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin lo tun ti kede pe awọn ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọ si APC.
Awọn aṣofin naa sọ pe omi alaafia ẹgbẹ naa ti ko tooro, aini igbẹkẹle ninu awọn adari, ati aisi airdaju ọjọ ọla to dara fun ẹgbẹ naa, lo mu ki awọn kuro.
Igbesẹ yii ni awọn onimọ nipa oṣelu ti n woye pe yoo fun ẹgbẹ to n ṣe iṣakoso ni Naijiria, APC, ni anfaani lati ni ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ ni ile aṣofin mejeeji, ti yoo si tun mu ko ṣe e ṣe fun wọn lati maa tẹwọ gba awọn nnkan ti awọn alaṣẹ ijọba ba n fẹ lai si atako kankan.
Awọn sẹnetọ to fi PDP silẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn sẹnetọ to fi PDP silẹ lọ si APC ni Francis Fadahunsi lati ipinlẹ Osun (Osun East), Oluwale Olubiyi lati ipinlẹ Osun bakan naa (Osun Central), Aniekan Bassey lati Akwa Ibom North-East ati Samson Ekong lati Akwa Ibom South.
Nigba to n tẹwọgba wọn, Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Godswill Akpabio, sọ pe aisi eto to yẹ ati amojuto to peye lo mu ki awọn aṣofin ọhun fi PDP silẹ.
Wọnyii ni iye sẹnetọ ti ẹgbẹ oṣelu kọọkan ni:
APC - 70
PDP - 28
Labour Party - 5
NNPP - 1
SDP - 2
APGA - 1
Nnkan ti eyi tumọ si ni pe ninu sẹnetọ 109 to wa ni Naijiria, ẹgbẹ oṣelu APC lo ni eyi to pọ ju lọ. Sẹnetọ mẹta pere lo nilo si i lati le gbe igbesẹ kankan nile aṣofin lai si jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ alatako da si i.
Iye awọn sẹnetọ to ti fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ darapọ mọ APC:
Ibrahim Abdullahi Danbaba lati ipinlẹ Sokoto - PDP si APC
Ifeanyi Ubah YPP si APC, ṣaaju iku rẹ.
Ned Munir Nwoko lati ipinlẹ Delta kuro ni PDP lọ si APC.
Ezenwa Onyewuchi lati ipinlẹ Imo fi LP silẹ lọ si APC.
Kawu Sumaila lati ipinlẹ Kano kuro ni NNPP lọ si APC.
Adamu Aliero (Kebbi Central)
Yahaya Abdullahi (Kebbi North)
Garba Maidoki (Kebbi South)
Ayipada to waye nile igbimọ aṣoju-ṣofin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni ọmọ ṣe ori nile igbimọ aṣoju-ṣofin - aṣofin mẹta lo kuro ni PDP bọ si APC.
Awọn aṣofin naa to kuro ni Ọjọru ni:
Ọnarebu Ajilesoro Taofeek Abimbola lati ipinlẹ Osun
Ọnarebu Omirin Olusanya lati ipinlẹ Osun
Ọnarebu Marcus Onobu lati ipinlẹ Edo
Gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ wọn, Olori ile aṣofin naa, Tajudeen Abass, nigba to n ka lẹta wọn, sọ pe rogbodiyan to wa ninu ẹgbẹ PDP ati aisi ireti to ba ẹgbẹ naa lo mu ki wọn o kuro.
Orukọ awọn aṣofin to ti darapọ mọ APC bayii:
- Idris Sulaiman Abubakar lati ipinlẹ Kogi - ADC si APC.
- Chris Nkwonta lati ipinlẹ Abia -PDP si APC.
- Sulaiman Abubakar lati ipinlẹ Zamfara - PDP si APC
- Chinedu Okere lati ipinlẹ Imo
- Mathew Donatus lati Kaduna
- Bassey Akiba lati Rivers State
- Esosa Iyawe lati Edo state.
- Alfred Ajang lati Plateau
- Amos Magaji lati Kaduna
- Garba Koko lati Kebbi
- Awọn aṣofin mẹfẹẹfa lati ipinlẹ Delta
- Kabiru Usman lati Kano - NNPP si APC
- Abdullahi Sani - NNPP si APC
Lọwọlọwọ, ẹgbẹ APC ni ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin 210, lẹyin ti wọn ri ọmọ ẹgbẹ 48 gba si i nitori awọn to fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ, paapaa Peoples Democratic Party.
Nnkan ti eyi tumọ si ni pe o ṣe e ṣe ki APC ni ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ paapaa bo sẹ ni 240 ninu 360. Eyi yoo si fun wọn ni anfaani lati ma a fi ontẹ lu nnkan ti awọn alaṣẹ ijọba ba n fẹ lai si atako kankan.
'Awọn to fi ẹgbẹ wọn silẹ tun fun Tinubu l'agbara si'

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook
Ọmọwe Kabiru Sa'id Sufi, olukọ ni Fasiti ipinlẹ Kano, sọ pe bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Aarẹ Bola Tinubu ṣe pọ si laarin awọn aṣofin, tumọ si atilẹyin ti ko ni atako fun un.
"Gbogbo abaa to ba n wa lati ọdọ rẹ ni yoo ma a gba ontẹ lai si atako kankan.
"Gbogbo abaa ti awọn aṣofin naa ba n da yoo jẹ eyi ti yoo ṣe aarẹ ati ẹgbẹ APC l'anfaani."
Ọmọwe Sufi tun sọ pe eyi yoo din agbara ẹgbẹ alatako ijọba rẹ ku nile aṣofin.
O ni kii ṣe nnkan to dara ti ko ba si ẹgbẹ alatako laarin awọn aṣofin "nitori pe nibẹ ni wọn ti n jiroro lori awọn igbesẹ to le tun orilẹede ṣe tabi ṣakoba fun.
"Bi igba ti wọn pa ohun mọ awọn araalu lẹnu ni ti ko ba ti si agbara lọwọ alatako mọ ọ."
Akoba wo ni awọn to fi ẹgbẹ wọn silẹ le ṣe fun ilu?
Ọmọwe Sufi ṣalaye pe, adari ilu ma n nilo ohun alatako nigba mii lati pe akiyesi rẹ si aṣiṣe, paapaa to ba jẹ nnkan to le pa araalu lara.
Lara akoba ti eyi le ṣe fun ijọba awaarawa ni pe, yoo sọ ile aṣofin di gbẹwu dani lọwọ ijọba, ti yoo ma a dari wọn si ibi to ba fẹ.
Bakan naa ni ẹgbẹ to n ṣe ijọba yoo ma a ṣe nnkan to wu u.












