Agbébọn tún ṣọṣẹ́ ni Plateau, dènà pa èèyàn mẹ́rìnlá àti ọlọ́pàá kan

Aworan ologun to gbe ibọn dani ati awọn obinrin araalu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni mẹrinla ninu awọn eeyan abule meji ti wọn di oloogbe ninu ikọlu tuntun to waye l'Ọjọbọ, nijọba ibilẹ Bokkos, ipinlẹ Plaetau, pẹlu ọlọpaa kan.

Ṣaaju ni ikọlu akọkọ to pa ọlọpaa ti waye lọjọ naa, ki ikeji ti araalu mẹrinla ti dero ọrun too waye ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi ẹ mulẹ.

Lasiko ti awọn eeyan ti pupọ ninu wọn jẹ ara abule Chirang n daribọ lati ọja Bokkos, ti wọn n pada si Abule Mangor ni awọn agbebọn to ti dena de wọn ṣina ibọn bolẹ fun wọn.

Alaga igbimọ to n ri si ki alaafia jọba ni Bokkos, Ọgbẹni Kefas Mallai, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun iwe iroyin Punch lalẹ Ọjọbọ.

"Ootọ ni, ọmọ ilu mẹrinla ni awọn afurasi agbebọn pa, awọn mẹta mi-in si farapa nigba ti wọn n bọ lati Ọja Bokko, ti wọn n lọ si Abule Mangor, nijọba ibilẹ Bokkos ."

Mallai fi kun un pe awọn agbofinro ti wa ni agbegbe naa, lati dena ikọlu yowu to ba tun fẹẹ waye.

'Wọ́n ti kọ́kọ́ yìnbọn pa ọlọ́pàá tọ n ṣọ́ ọ̀nà Richa'

Ninu alaye Alaga igbimọ alaafia Bokkos, o ni ṣaaju ni awọn apaayan naa ti pa ọlọpaa kan to n ṣọ oju ọna Richa, nijọba ibilẹ Bokkos kan naa.

Mallai sọ pe ibi ti ijọba fi ọlọpaa naa ṣọ lo n ṣọ lọwọ ti wọn fi kọlu u, ti wọn si pa a sibẹ.

O ṣapejuwe ipaniyan naa bi eyi to buru gan-an.

"Ọkan wa gbọgbẹ gan-an, nitori laaarọ oni, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Keje ọdun 2025, wọn pa ọlọpaa MOPOL kan sibi ti ijọba fi ṣọ, loju ọna Richa, ijọba ibilẹ Bokkos.

"Ohun to ṣẹlẹ ni Bokkos lonii niyẹn."

Mallai lo ṣalaye bẹẹ.

Ninu ọrọ tirẹ to fi fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alaga ijọba ibilẹ Bokkos Amalau Amalau, juwe ohun to ṣẹlẹ naa bii eyi to nilo akiyesi kiakia.

Ẹ o ranti pe ikọlu awọn agbebọn n di lemọlemọ ni awọn ipinlẹ kan, paapaa Pleateu ati Benue.

Bi awọn eeyan agbegbe naa ṣe n koro oju si ipaniyan ọhun ni wọn n rọ ijọba apapọ lati dide si i.

Bẹẹ ni awọn mi-in n pe fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lati pari ikọlu gbogbo igba yii.