Emir ìlú Gusau, Ibrahim Bello jade láyé lẹ́ni ọdún 71

Emir ilu Gusau to doloogbe, Ọmọwe Ibrahim Bello

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọmọwe Ibrahim Bello ti i ṣe Emir ilu Gusau, nipinlẹ Zamfara, ti dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71).

Owurọ oni, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025 ni iroyin ṣo pe Emir Ibrahim Bello dagbere faye niluu Abuja, lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.

Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, Sulaiman Idris, Agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal, kede ninu atẹjade to fi sita, pe gomina ba awọn eeyan Zamfara kẹdun iku ọba naa.

Gomina Lawal sọ pe adanu nla ni iku Emir Ibrahim jẹ fun oun bii ẹnikan.

O fi kun un pe alatilẹyin ọba to fi ọdun mẹwaa to fi wa nipo Emir jin ipinlẹ Zamfara ni.

"Mo ba awọn igbimọ oloye Zamfara, awọn mọlẹbi Emir, igbimọ afọbajẹ Zamfara ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Zamfara kẹdun iku Emir Bello.

"Adanu nla ni ipapoda rẹ jẹ fun emi bii ẹnikan, awọn eeyan Zamfara, Ariwa ati gbogbo Naijiria lapapọ.

"O fi gbogbo ara jin, o si ni igbagbọ tootọ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade Emir naa wi.

Ta a ni Emir Ibrahim Bello

Ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹta, ọdun 2015 ni Emir Ibrahim Bello de ipo Emir ilu Gusau.

Oloogbe yii ni Emir kẹẹẹdogun to jẹ ni Gusau.

Ṣaaju ko too depo ọba, oṣiṣẹ ijọba ni Oloogbe Bello.

O ṣiṣẹ naa de ipo ọga agba ti a mọ si Permanent Secretary.

Ipinlẹ Sokoto atijọ ati ipinlẹ Zamfara ni Oloogbe ti ṣiṣẹ ijọba titi.

Ọdun mẹwaa ati oṣu diẹ lo fi wa nipo Emir Zamfara ki ọlọjọ too de.