Kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àṣekágbá WAFCON láàrin Super Falcons àti Morocco lónìí

Aworan Sakina Ouzraoui Morocco ati Rasheedat Ajibade Naijiria

Oríṣun àwòrán, Back page pix

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Pẹpẹyẹ yoo pọmọ lalẹ oni nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ba koju Morocco ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije WAFCON to n lọ lọwọ lorilẹede Morocco.

Super Falcons ti wọn ti gba ife ẹyẹ naa fun igba mẹsan an ọtọọtọ fẹ lu Morocco lati gba ife naa fun igba kẹwaa.

Atlas Lionesses Morocco ko tii gba ife ẹyẹ WAFCON ri ni ti wọn, ti wọn ba le bori Naijiria lalẹ oni, igba akọkọ ni yoo jẹ ti wọn yoo gba ife ẹyẹ WAFCON.

Ko si ẹni to fidirẹmi ninu ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ marun un ti wọn ti gba ṣaaju ipele aṣekagba yii.

Koda, goolu kan ṣoṣo lo ti wọ inu awọn ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ninu idije WAFCON yii.

Morocco to n gbalejo idije WAFCON yii lo gba ipo keji lọdun 2022 nigba ti South Africa fagba han wọn gba ife ẹyẹ naa.

Niluu Rabat ti wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ aṣakagba tọdun 2022 naa ni ere bọọlu ti alẹ oni yoo ti waye.

O nira lati sọ ni pato ẹni ti yoo bori ninu ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji tori awọn mejeeji naa lo tiraka wọ ipele aṣekagba.

Pẹnariti ni Morocco gba ti wọn fi lu Ghana wọ ipele aṣekagba, nigba ti Naijiria ṣiṣẹ takun takun ki wọn to ri South Africa lu ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun si aṣekagba.

Amọ, agbabọọlu adilemu fun Super Falcons, Michelle Alozie, sọ pe Falcons ti ṣetan lati gba ife ẹyẹ naa fun igba kẹwaa eyi ti wọn n pe adape rẹ ni ''mission X.''

Alozie ni nnkan ẹyọkan to wa lọkan awọn ni pe kawọn gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa.

$1m owo to to bii biliọnu kan abọ naira ni ẹni to ba gba ife ẹyẹ naa yoo gba lọọle.

Ẹgbẹ agbabọọlu Morocco kii kaarẹ rara ninu ere bọọlu – Oparanozie

Aworan ẹgbẹ agbabọọlu Morocco

Oríṣun àwòrán, CAF

Agbabọọlu Super Falcons tẹlẹ ri, Desire Oparanozie, ti sọ fun BBC wi pe awọn ẹgbẹ agbabọọlu Morocco kii kaarẹ titi ti ere bọọlu yoo fi pari.

''Wọn ti fakọyọ gan an ninu idije WAFCON yii.

Ni gbogbo igba ni wọn maa n gbeja ko awọn alatako wọn, eyi to jẹ nnkan to dara lati ṣe,'' Oparanozie lo sọ bẹẹ.

Jorge Vilda to gba ife ẹyẹ agbaye pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Spain ni akọnimọọgba Morocco.

Awuyewuye wa lori iyansipo Vilda tori bi o ṣe kuro ni ẹgbẹ agbabọọlu Spain lẹyin iṣẹlẹ to ṣẹlẹ nigba ti aarẹ ajọ ere bọọlu lorilẹede Spain, Luis Rubiales, fẹnu ko agbabọọlu Jenni Hermoso lẹnu lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ agbaye tan lọdun 2023.

Ẹsun ihuwa ipa fun ibalopọ ni wọn fi kan Rubiales, o si sanwo itanran.

Amọ, Vilda jare ẹsun iwa ipa ti wọn fi kan oun.

Ọrọ yii si wa lọkan awọn ololufẹ Atlas Lionesses kan bo tilẹ jẹ pe Vilda le gba ife ẹyẹ WAFCON akọkọ iruẹ fun Morocco.

Njẹ Super Falcons le gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa?

Aworan awọn agbabọọlu Super Falcons

Oríṣun àwòrán, Backpage px

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons ko sọ nnkan mii ju pe awọn fẹ gba ife ẹyẹ WAFCON fun igba kẹwaa lọ.

Ajọ NFF to n ri si ere bọọlu ni Naijiria ti sọ ṣaaju ki idije WAFCON to bẹrẹ wi pe ''Mission X'' eyi to tumọ si gbigba ife ẹyẹ naa fun igba kẹwaa ni afojusun Super Falcons ninu idije WAFCON tọdun yii.

Akọnimọọgba Naijiria, Justin Madugu, ti ṣe atunṣe lori Super Falcons debi wi pe wọn duro daadaa lẹyin ati laarin gbungbun.

Bakan naa si ni awọn agbabọọlu iwaju ti Esther Okoronkwo n dari wọn naa ti mọwọ ara wọn.

Lara nnkan to le jẹ anfaani fun Super Falcons ni pe agbabọọlu mẹsan an ọtọọtọ lo ti gba goolu sawọn fun Naijiria ninu idije WAFCON yii.

''Abuda wa ni lati ja fita fita ki a si bori ninu gbogbo ifẹsẹwọnsẹ ti a ba n gba,'' Okoronkwo lo sọ bẹẹ fun BBC.

Aṣọle Super Falcons, Chiamaka Nnadozie, ko tii ri iṣẹ ṣe dabi alara ninu idije WAFCON yii.

Goolu kan ṣoṣo to tọwọ rẹ wọle naa ni pẹnariti ti South Africa gba ni ipele to kangun si aṣekagba.

Oparanozie ni Super Falcons yoo gbẹsan bi Morocco ṣe lu wọn ninu idije WAFCON ọdun 2022 nibi ti rẹfiri ti le agbabọọlu Naijiria meji jade ki Atlas Lionesses to fi pẹnariti bori wọ ipele aṣekagba.