Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo fagilé ọjà títà lọjọ́ Àìkú lọ́ja Gbagi Ibadan laráàlú bá ń béèrè ìdí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ijọba ipinlẹ Oyo ti fagile karakata lọjọ Aiku ninu gbajugbaja ọja nla Gbagi to di Bola Ige International Business Complex.
Kọmiṣanna to n ri si ọrọ Okoowo,Ileeṣẹ ati Ajẹṣẹku, Ọgbẹni Adeniyi Adebisi, lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọbọ ninu atẹjade ti Kọmiṣanna eto iroyin ati ilanilọye, Dotun Oyelade, fi lede.
Atẹjade naa ṣalaye, pe o ti di eewọ lati naja ni Gbagi ni Sannde, bẹẹ ni ijọba yoo fi kele ofin gbe ẹni to ba tapa si ofin yii.
Ọjọ Aiku ọla yii ti i ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje ọdun 2025 ni 'ma patẹ ni Sannde' naa yoo bẹrẹ bi atẹjade ijọba ṣe sọ.
Ṣugbọn ero araalu ko jọra wọn lori igbesẹ ijọba lati dẹkun ọja tita lọjọ Sannde loja Gbagi yii.
Idi ni pe o ṣe ajeji lara awọn eeyan kan ti wọn ko le ma lọ sọja naa lati ta, tabi ra nnkan lọjọ Aiku.
Paapaa bo ṣe ọja nla ti gbogbo ohun ti eeyan ba fẹẹ ra wa nibẹ .
Àlàyé ìjọba
Nigba to n ṣalaye idi ti ijọba ipinẹ Oyo ṣe gbe igbeṣẹ yii, Kọmiṣanna ọrọ okoowo nipinlẹ Oyo sọ pe,
" Ofin 'ma patẹ ni Sannde yii yoo fi ẹsẹ eto aabo rinlẹ daadaa lọja yii, yoo si jẹ ki gbogbo nnkan wa letoleto.
" A ko deede gbe igbesẹ naa, lẹyin ọpọlọpọ apero ati ijiroro ti a ṣe pẹlu awọn olori ọja ati awọn ti ọrọ naa kan la pinnu. Fun anfaani awọn eeyan to n naja naa si ni pẹlu"
O fi kun un pe awọn ọmọ ganfe maa n lo anfaani ọjọ Sannde ti ọja Gbagi ki i kun pupọ, wọn yoo si maa fi huwa to lodi sofin nibẹ.
Eyi lo ni o fa a ti ifikunlukun fi waye laaarin awọn olori ọja ati ijọba Oyo, ti awọn si fẹnu ko pe ko gbọdọ si ọja tita lọja yii mọ ni gbogbo ọjọ Aiku.
"Koda, awọn olori ọja gan-an ni wọn ti kọkọ funra wọn sọ pe kijọba fofin de ọja tita ni Sannde, ki awọn baa le da aabo bo awọn ọlọja.
"Ṣugbọn awọn kan ṣi n tẹsiwaju lati maa ru ofin yii nigba naa, eyi to n fa a ti aabo ko fi to, ti ibẹrubojo si wa.''
Adebisi sọ pe ijọba ko le laju silẹ, ki awọn eeyan keeyan kan maa fi Sannde huwa laabi lọja Gbagi.
O ni aabo ẹmi ati dukia awọn to n ra ọja, ta ọja nibẹ, kun ijọba loju.
Adebisi fi kun un pe ikọ agbofinro yoo maa wa nikalẹ lọja naa, lati fi ofin gbe ẹnikẹni to ba gbiyanju ati naja ni Gbagi ni Sannde.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, ọja Bola Ige International Business Complex, tobi pupọ.
Ọkan ninu awọn ọja nla to wa nilẹẹ Yoruba ni.
Aṣọ gidi ọlọkan- o-jọkan kun Gbagi, bẹẹ si ni awọn ọja mi-in naa pọ nibẹ gidi pẹlu.














