Idán inú eré sinimá ti gbàràdá ní Nàìjíríà - Hakeem Effect

Aworan idan Kola Ajeyemi

Oríṣun àwòrán, Hakeem Effect/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Hakeem Onilogbo to jẹ gbajugbaja apidan ati aṣaraloge ninu sinima ti sọ fun BBC Yoruba òun ti wa lẹnu iṣe yii lọjọ tó ti pẹ.

Opọlọpọ oṣiṣẹ lo maa n fọwọsowọpọ ki eré sinima to di odindin.

Yatọ si oṣere, a ni oludari, aṣaraloge, abaniwale, agbohunsilẹ, oni ina mọnamọna, ato itage, ọlọ́wọ́ idan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ to sẹ pataki ninu sinima ṣugbọn ti kii ṣe oṣere ni Hakeem Effect to n fi awọn oṣere pa idan to ba wuu, nipa pipa irisi tabi awọ wọn da, debi pe o ma n ṣoro nigba miran lati da oṣere mọ̀.

Opọ arugbo ni Hakeem ti sọ di ọmọge bẹẹ lo ti sọ ẹya ara awọn eeyan di nkan mii laarin ọdun mẹrinla ti oun ti n ṣe e.

Aworan Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Hakeem Effect/Instagram

Hakeem ṣalaye fun BBC Yoruba ninu ifọrwanilẹnuwo yii ldun 2019 pé idán lásán ni ṣugbọn ọpọ rẹ n bani lẹru.

O sọrọ lori afojusun rẹ lati di alafo to wa laarin awọn oṣiṣẹ ọlọwọ idan ninu sinima ilu oyinbo ati ti ilẹ Adulawọ.

Ori ko Hekeem Effect yọ lọwọ awọn ajinigbe

Ẹwẹ, ori ko Hakeem Effect yọ lọwọ awọn ajinigbe lọdun 2023.

Ninu fọnran to gbe sori ayelujara lọdun naa, o ni awọn ajinigbe yii ṣekọlu si oun ati awọn osisẹ lasiko ti wọn n rin irinajo kuro Ikenne nipinlẹ Ogun.

Hakeem Effect ni dẹrẹba oun lo doola ẹmi gbogbo awọn to wa ninu ọkọ akẹro ti wọn gbe lọ irinajo naa.

O ṣalaye ninu fọnran ọhun wi pe iro ibọn n lọ lọtun losi lasiko ikọlu naa, ti ibọn si ba dẹrẹba wọn to pe orukọ rẹ ni Legba.

O wa dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi oun ati akẹgbẹ rẹ si lasiko ikọlu awọn ajinigbe naa.

"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bi o ṣe gba ẹmi emi ati awọn osisẹ mi la lẹyin ti awọn ajinigbe ṣekọlu wa ni bi ogun isẹju ti a kuro niluu Ikeene.

"Wọn fi ibọn fọ gilaasi ọkọ, ti wọn si ji awọn kan gbe sugbọn mo dupẹ pe mo mo wa laye.

"Mo dupẹ fun dẹrẹba ọkọ wa Legba ti wọn yin ibhọn lu, iro ibọn n dun lọtun losi sugbọn Ọlọrun ba wa wa ọkọ naa.

"Emi, Iyawo mi ati awọn osisẹ mi wa laaye,'' Hakeem Effect ṣalaye.