Ìdí tí mo fi yarí pé Arsenal FC nìkan lẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí mo fẹ́ darapọ̀ mọ́ rèé - Gyokeres

Aworan Viktor Gyokeres

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lẹyin o rẹyin, ẹlẹsẹ ayo orilẹede Sweden, Viktor Gyokeres, pada darapọ mọ ẹgbẹ agbabọolu Arsenal lẹyin ọpọlọpọ ipenija to koju lati kuro lẹgbẹ agbabọọlu Sporting.

Gyokeres buwọlu iwe adehun latu darapọ mọ Arsenal fun owo to to £64m lẹyin ti wọn ṣe ayẹwo ara rẹ tan ti wọn si ri pe ṣaka lara rẹ da.

Amọ, opọ eeyan lo ti n beere wi pe ki gan an ni Gyokeres ri lara Arsenal to fi taku wi pe Oriogbade nikan loun fẹẹ darapọ mọ lati Sporting..

Gyokeres ti sọrọ soke wi pe bi Arsenal ṣe lu ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tẹlẹ Sporting pẹlu ami ayo 5-1 lo mu oun pinnu lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Gyokeres ni iyalẹnu lo jẹ foun pe oun ko ri goolu kankan gba sawọn Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

O ni lẹyin naa loun wa roo pe ẹgbẹ agbabọọlu to gbọrẹgẹjigẹ ni Arsenal i ṣe eyi to maa n nira fawọn ẹgbẹ agbabọọlu alatako lati lu.

''Mo kan ro wi pe Arsenal lẹgbẹ agbabọọlu to dara fun mi lati darapọ mọ.

Nnkan ti mo tun gbọ lẹnu Mikel Arteta to jẹ akọnimọọgba Arsenal ati Andrea Berta to jẹ adari ẹka to n ri si rira awọn agbabọọlu ni Arsenal naa wa lara idi to mo fi pinnu lati darapọ mọ Arsenal.

Mi o le duro mọ lati bẹrẹ si ni gba goolu sawọn fun Arsenal - Gyokeres

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgọọrọ awọn ololufẹ Arsenal kaakiri agbaye lo ti wa lọrun awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa papaa julọ akọnimọọgba Arteta wi pe wọn gbọdọ ra Gyokeres.

Ni bayii, Gyokeres gan an ti foju sọna lati fakọyọ nipa gbigba ọpọlọpọ goolu sawọn fun Arsenal.

''Idunnu lo jẹ fun mi bi ọpọ ololufẹ Arsenal ṣe fẹ ki n darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Gunners .

Inu mi maa dun lati ri awọn ololufẹ Arsenal ni papa iṣere ti mo ba ti bẹrẹ si gbabọọlu fun wọn.

Emi gan an ko le duro mọ lati bẹrẹ si ni gba goolu sawọn fun Arsenal,'' Gyokeres lo sọ bẹẹ.

England ni Gyokeres ti bẹrẹ irinajo bọọlu gbigba rẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Coventry lo kọkọ ṣoju ki o to darapọ Swansea.

Ọdun 2023 lo darapọ Sporting ni Portugal nibi ti o ti wa si Arsenal bayii.

Gyokeres sọ pe ''England nibi ni mo ti bẹrẹ irinajo bọọlu mi, o ti to ọjọ mẹta naa.

O dami loju pe mo ti dara sii gẹgẹ bi ẹlẹsẹ ayo ju ti tẹlẹ lọ.

Ni bayii, mo ṣetan lati jẹwọ ara mi ki n si ṣe iranwọ fun awọn akẹgbẹ mi lori papa.''

Ọpọ lo ti n wo Gyokeres wi pe yoo ran Arsenal lọwọ lati gba ife ẹyẹ Premier League ati Champions League ti wọn ko tii gba ri ninu itan ẹgbẹ agbabọọlu naa.