Amotekun fẹ̀sùn kan ológun kan pé ó wọ́ ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ sílẹ̀ lórí ọ̀kadà, gba ẹ̀mí rẹ̀ l‘Osun, ọlọ́pàá fèsì

Oríṣun àwòrán, AMOTEKUN/FACEBOOK
Àjọ ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun ti fẹ̀sùn kàn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà kan pé ó ṣekúpa òṣìṣẹ́ àwọn kan lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2025.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ẹ̀ṣọ́ Amotekun ìpínlẹ̀ Osun, Yusuf Idowu Abass fi léde lórúkọ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà Dókítà Isaac Omoyele sọ pé ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni òṣìṣẹ́ ológun náà ṣe ìkọlù sí ẹ̀ṣọ́ àwọn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peter Samuel Tope.
Ní agbègbè Ijeda ní ìlú Ijesa, ìpínlẹ̀ Osun ni wọ́n sọ pé ìkọlù náà ti wáyé.
Omoyele nínú àtẹ̀jáde náà fẹ̀sùn kan pé òṣìṣẹ́ ológun kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Opejobi Fiyinfoluwa, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ ológun ló ṣe ìkọlù sí Peter Samuel Tope ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ó ṣàlàyé pé Fiyinfoluwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ, wọ aṣọ ológun tó sì ṣe ìkọlù sí iléeṣẹ́ Amotekun tó wà ní Ijebu-Jesa.
"Wọ́n la nǹkan mọ́ Tope lórí, ó ṣubú lulẹ̀ lórí ọ̀kadà, ogún ìṣẹ́jú ni ìkọlù náà fi wáyé láì sí ìrànlọ́wọ́ kankan, Tope sì wà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀"
Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé Fiyinfoluwa sọ pé lára ìdí tí òun fi lọ darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ológun ni láti máa fi ìyà jẹ àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ Amotekun.
Omoyele nínú àtẹ̀jáde náà sọ pé kò pẹ́ sígbà náà ni Fiyinfoluwa àtàwọn kan pàdé ẹ̀ṣọ́ Amotekun Tope lójú ọ̀nà tó ń gun ọ̀kadà lọ tí wọ́n sì da dúró.
"Wọ́n ṣe ìkọlù si.
Ohun tí a gbọ́ ni pé wọ́n la nǹkan mọ́ Tope lórí èyí tó jẹ́ kó ṣubú lulẹ̀ láti orí ọ̀kadà tó gùn.
Nǹkan bíi ogún ìṣẹ́jú ni ìkọlù náà fi wáyé láì sí ìrànlọ́wọ́ kankan, èyí tó mú kí Tope wà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀."
Bákan náà ló fi kun pé, ní kété tí òṣìṣẹ́ ológun wu ìwà láabi náà tán ni wọ́n na pápá bora pẹ̀lú ọ̀kadà.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé lẹ́yìn táwọn òṣìṣẹ́ Amotekun gbọ́ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n sáré gbé Tope lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Bákan náà ló tún ní wọ́n lọ fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó wà ní Ijebu-Jesa létí àti pé àwọn sọ fún ọ̀gágun Yunusa Isyaku tó wà ní ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun tó wà ní ìlú Ede nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Omoyele ní gbogbo ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí Peter Tope ló já sí pàbó bí ó ṣe dágbére fáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Ileesẹ Ọlọpaa fi idi isẹlẹ naa mulẹ
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ti ń fa awuyewuye ní agbègbè náà pàápàá láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò síra wọn.
Amotekun ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ìkọlù ọ̀hún àti pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà ló máa fojú winá òfin.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Abiodun Ojelabi Zechariah fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá tó sì sọ pé ìwádìí ti ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.















