Israel kéde dídáwọ́ ogun dúró láti fààyè gba gbígbé oúnjẹ wọ Gaza

Àwọn èèyàn tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gba oúnjẹ ní Gaza

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iléeṣẹ́ ológun Israel ti kéde ìgbésẹ̀ láti fi ààyè gba àwọn ohun èlò ìbojú àánú woniláti máa wọ Gaza lẹ́yìn táwọn àjọ àgbáyé lóríṣiríṣi ti ń ṣèkìlọ̀ nípa ebi tó ń bá àwọn èèyàn fínra lẹ́kùn náà.

Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ológun Isreal Defense Forces, IDF fi síta lọ́jọ́ Àìkú ni wọ́n ti kéde àwọn ìlànà láti ṣe ìdádúró ìkọlù láwọn agbègbè mẹ́ta láti fi ààyè gba fífi oúnjẹ ránṣẹ́ sí Gaza.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Israel kéde pé àwọn fi àwọn oúnjẹ bíi fúláwà, ṣúgà àtàwọn oúnjẹ inú agolo míì ránṣẹ́ sí Gaza gba ti ojú òfurufú.

Láti bíi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìpè ti ń wáyé pé kí Israel fi ààyè gba gbígbe oúnjẹ wọ Gaza lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù táwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ti ń kojú ebi tó lágbára.

Ṣùgbọ́n Israel jiyàn pé àwọn ń mọ̀ọ́mọ̀ ń fi ààyè gba ebi ní Gaza.

Ní ọjọ́ Àìkú ni iléeṣẹ́ ètò ìlera tí Hamas ń darí sọ pé èèyàn mẹ́fà ló dágbére látàrí àìrí oúnjẹ jẹ tó bó ṣe yẹ èyí tó mú kí iye èèyàn tí ebi ti pa kú di 133 láti ìgbà tí ogun náà ti bẹ̀rẹ̀, tó sì jẹ́ pé ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ikú ọ̀pọ̀ wọn wáyé.

IDF sọ pé àwọn máa ṣí àwọn ọ̀nà sílẹ̀ ní Gaza láti fi ààyè gba àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN àti àwọn àjọ míì láti gbé oúnjẹ àti oògùn wọ Palestine gba àwọn ọ̀nà náà láàárín aago mẹ́fà òwúrọ̀ sí aago mọ́kànlá alẹ́.

Àwọn agbègbè mẹ́ta tí wọ́n ti máa dáwọ́ ogun dúró ni Al Mawasi, Deir al-Balah àti ìlú Gaza láàárín aago mẹ́wàá àárọ̀ sí aago mẹ́jọ alẹ́ lójoojúmọ́ títí di ìgbà kan náà gẹ́gẹ́ bí IDF ṣe sọ.

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé UN àti àwọn àjọ ẹlẹ́yinjú àánú míì tó fi mọ́ àwọn tó jẹ́ abẹ́ṣinkáwọ́ Israel ni wọ́n ti di ẹ̀bi àìsí oúnjẹ tó ń wáyé ní Gaza ru Israel, tí wọ́n sì ń pè fún fífi ààyè gba gbígbe oúnjẹ wọ ẹkùn Gaza.

Tom Fletcher, ọ̀gá àgbà àjọ ẹlẹ́yinjú àánú UN sọ pé ohun tó dára gidi ni ìgbésẹ̀ tí Israel gbé yìí.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé àwọn kàn sí ọ̀pọ̀ àwọn tí ebi ń dà láàmú ní Gaza láàárín àkókò náà.

Israel fi ààyè gba gbígbe oúnjẹ wọ Gaza

Àwọn ọkọ̀ tó fẹ́ kó oúnjẹ wọ Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn orílẹ̀ èdè bíi UAE, Jordan àti Egypt ti ń fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí Gaza báyìí láti orí ilẹ̀ àti ojú òfurufú bí Egypt ṣe ti ń rí ọ̀nà gba lẹ́nu ibodè.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní UN ṣèkìlọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sùn lébi fún ọjọ́ pípẹ́ ní Gaza.

"Àìrí oúnjẹ jẹ ń lékún bó ṣe jẹ́ pé èèyàn tó lé ní 90,000 tó fi mọ́ àwọn ọmọdé àti obìnrin ló nílò ìtọ́jú kíákí," àjọ World Food Programme sọ nínú àtẹ̀jáde kan.

Adarí àjọ Unrwa, Philippe Lazzarini sọ pé èèyàn tó lé ní ọgarùn-ún tó fi mọ́ àwọn ọmọdé ni wọ́n fi pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ebi.

Àwọn àwòrán ọmọdé tí ebi ń dà láàmú ń jéde láti ẹkùn náà.

IDF sọ pé àwọn ọkọ̀ òfurufú àwọn ló ti ń gbé àwọn oúnjẹ sílẹ̀ ní Gaza.

'Fífi òpin sí ogun ni à ń fẹ́'

Àwọn èèyàn tí ebi ń dà láàmú ní Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn olùgbé Gaza ti ń dunnú lórí ìgbésẹ̀ Israel láti fi ààyè gba gbígbe oúnjẹ àtàwọn ohun ìdẹ̀kùn wọ ẹkùn náà.

Àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn ló ń pè fún wíwá ojútùú sí làásìgbò tó ń wáyé ní agbègbè náà.

Iléeṣẹ́ ológun Israel sọ pé àwọn máa fàyè gba gbígbe oúnjẹ àti oògùn wọ Gaza lẹ́yìn gbogbo ìkìlọ̀ táwọn àjọ àgbáyé ṣe fun.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì ló ti ń kojú àìsí oúnjẹ, omi àtàwọn ohun èlò míì bíi oògùn bó ṣe jẹ́ pé wọ́n ti ti àwọn ẹnubodè pa.

"Lóòótọ́ ni mo tún ti ní ìrètí pé nǹkan máa da ṣùgbọ́n mo ǹ kọminú pé àìrí oúnjẹ jẹ yóò tún túnbọ̀ tẹ̀síwájú nígbà tí ìgbésẹ̀ yìí bá dúró," Rasha Al-Sheikh Khali, ìyá ọlọ́mọ mẹ́rin sọ.

"Kìí ṣe bí oúnjẹ ṣe pọ̀ sí ni à ń sọ bíkòṣe irú àwọn oúnjẹ tó yẹ kó jẹ́," Neveen Saleh, ìyá ọlọ́mọ kan sọ.

"A ò tíì jẹ èso kankan tàbí ẹ̀fọ́ láàárín oṣù mẹ́rin. Kò sí ẹran adìẹ, kò sí ẹran, kò sí ẹyin. Gbogbo àwọn nǹkan tí à ń rí ni oúnjẹ inú agolo tí ọjọ́ ti máa ń lọ lórí wọn àti fúláwà."

Lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas ṣèkọlù sí ẹkùn gúúsù Israel ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá, ọdún 2023 níbi tí èèyàn 1,200 ti pàdánù ẹ̀mí wọn tí wọ́n sì fi èèyàn 251 sí àhámọ́ ni Israel ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìkọlù sí Gaza.

Èèyàn tó lé ní 59,000 ni wọ́n ti pa ní Gaza láti ìgbà náà gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera tí Hamas ń darí rẹ̀ ṣe sọ.